FUTA: Òfin ti wà nílẹ̀ tó ní ká lé akẹ́kọ̀ọ́ tó bá na akẹẹgbẹ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Google
Ile ẹkọ fasiti imọ ẹrọ ijọba apapọ to kalẹ silu Akure, ti fi ọwọ osi juwe ile fawọn akẹkọọ mẹfa ti wọn fẹsun kan pe wọn lu akẹgbẹ wọn.
Igbesẹ yii ko ṣẹyin abajade igbimọ iwaadi ti ile ẹkọ naa gbe kalẹ, lati ṣe iwaadi bi awọn akẹkọọ naa ṣe lu akẹgbẹ wọn kan nilegbe awọn akẹkọọ.
Iṣẹlẹ naa waye lọjọ kẹrindinlogun oṣu Kọkanla ọdun 2019.
Igbakeji oludari eto ibanisọrọ fasiti Futa, Adegbenro Adebanjo lo fi ikede yii sita ninu atẹjade kan ti ile ẹkọ naa fi sita.
Gẹgẹ bi o ti ṣe sọ, wọn ni orukọ awọn akẹkọọ naa ni:
- Popoola Olaniyi Agboola IDD/ (300L)
- Oluwadare Faith Tobiloba FST ( 200L)
- Nandi Yohanna Jessica IPE/ ( 200L)
- Ajuwon Tolani Emmanuella FAT/ (100L)
- Emmanuel Funmilayo Taiwo FAT/ (100L)
- Alao Olabimpe Cecilia CSP/ (100 L)
Bakanna ni wọn ni lile tawọn le awọn akẹkọọ naa wa ni ibamu pẹlu ofin ileewe to la ijiya ''lile akẹkọọ kuro ti o ba lu akẹkọọ akẹgbẹ rẹ nibikibi ti kii ṣe ọgba ile ẹkọ''
Wọn ni lnitori eleyi, awọn akẹkọ to huwa aidaa naa ko le e jẹ anfaani kankan to tọ si awọn akẹkọọ fasiti naa mọ bayi.
Ẹwẹ, fasiti FUTA tun sọ pe kii ṣe nitori pe awọn eeyan ke gbajare lori iwa awọn akẹkọọ to lu akẹgbẹ wọn naa, bi kii ṣe pe awọn tẹle ofin ti ile ẹkọ la kalẹ lori fifi iya jẹ ẹni ba tasẹ agẹrẹ sofin wọn.












