FUOYE: Fayemi ní ìṣẹ̀lẹ̀ bí àwọn ìrètí ọ̀la náà ṣe kú ba òun nínú jẹ́

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
Gomina Kayọde Fayẹmi ti ipinlẹ Ekiti ti ranṣẹ ibanikẹdun lọ ki awọn ẹbi akẹkọọ meji ti ọlọpaa yinbọn pa.
Awọn akẹkọọ naa jẹ alaisi lasiko rogbodiyan to waye laarin awọn ọlọpaa ati akẹkọ fasiti FUOYE, pẹlu awọn olugbe ilu Ọyẹ Ekiti.
Awọn akẹkọọ meji ọhun, Joseph Okunofua ati Kehinde Dada jade laye lẹyin ti iroyin sọ pe, ọta ibọn ba wọn lasiko iwọde awọn akẹkọọ ati awọn olugbe ilu naa ni ọjọ Iṣẹgun ati Ọjọru.
- Àwọn ọmọ Ilara-mọkin yarí,wọn gbé'jà lọ bá Ọba láàfin
- Aya Fayemi lẹ́jọ́ jẹ́ lórí ikú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fuoye - Segalink
- Ẹ ṣèwádìí ikú Ọ̀jọ̀gbọ́n Gideon Okedayọ - ASUU
- Àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀dé South Africa yóò gba ìrànwọ́ owóyàá àti káádì ìpè - Dabiri
- Ká má parọ́, ojora mú mi lórí àbọ̀ ìgbìmọ̀ olùgbẹ́jọ́ ìbò ààrẹ - Buhari jẹ́wọ́
- Ọọ̀ni obìnrin, Lúwòó Gbàgídà rèé, akọni tó ń gun ọkùnrin ní ẹṣin rìn
Họnọrebu Biọdun Oyebanji, to jẹ akọwe ijọba ipinlẹ Ekiti pẹlu Họnọrebu Biọdun Ọmọlẹyẹ, to jẹ olori awọn oṣiṣẹ to n ba gomina ipinlẹ Ekiti ṣiṣẹ, lo ṣiwaju ikọ olubanikẹdun naa.
Ikọ olubanikẹdun ọhun lọ si ilu Ido-Ekiti nibiti wọn ti ṣabẹwo si arabinrin Esther Okunofua, to jẹ iya Joseph akẹkọọ ipele kẹta ẹka imọ Biology ni fasiti FUOYE, ki o to jade laye.

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
Bakan naa ni wọn tun de ilu Uṣi Ekiti, nibi ti wọn ti ki alagba Adedayọ Dada to jẹ baba fun Kẹhinde.
Họnọrebu Oyebanji ṣalaye pe, iṣẹlẹ naa jẹ eyi ti o ba gomina Fayẹmi ninu jẹ pupọ ati pe, kii ṣe idunu rẹ ki awọn obi mejeeji yii padanu ọkan lara awọn ireti ọla wọn.








