Sex Offenders: NAPTIP ní àwọn aráàlú tó jẹ́ ẹ̀jẹ̀ kannáà kìí fẹ́ kí ẹbí wọn ṣẹ̀wọ̀n ìfipábánilòpọ̀

Ọkunrin to n fi ipa ba obinrin lo pọ

Oríṣun àwòrán, Others

Ọjọ Aje ni igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo sefilọlẹ iwe akọsilẹ ti yoo maa gbe orukọ awọn eeyan to ba jẹbi ẹsun ibalopọ lọna aitọ sita.

Iwe akọsilẹ naa si ni wọn fi n sami ayajọ ọjọ gbigbogun ti iwa sawọn obinrin eyi to maa n waye lọjọ kẹẹdọgbọn osu kọkanla ọdọọdun, to ko lọjọ aje lọdun 2019.

Iwe akọsilẹ orukọ awọn eeyan to jẹbi ẹsun ibalopọ lọna aitọ yii nii se akọkọ iru rẹ ti ajọ to n gbogun ti iwa ifinisowoẹrun NAPTIP, se agbekalẹ rẹ nifọwọkọwọ pẹlu awọn ileesẹ alaabo ati awọn ajafẹtọẹni lorilẹede Naijiria.

Nigba to n salaye ohun ti iwe akọsilẹ naa wa fun awọn awọn igbesẹ to rọ mọ lilo rẹ, oludari fun ẹka eto itaniji fun araalu labẹ ajọ Naptip, Arinze Orogwe salaye fun BBC Yoruba pe eto yii lo jẹ eyi to kan tọmọde tagba lorilẹede Naijiria.

Iwe akọsilẹ ti yoo maa gbe orukọ awọn eeyan to ba jẹbi ẹsun ibalopọ lọna aitọ sita

Oríṣun àwòrán, Yemi Osinbajo

Awọn koko ohun to si mẹnuba ree pe o jẹ igbesẹ lati gbe ta ba fẹ lo iwe akọsilẹ naa, ti a si kọ̀ orukọ awọn afipabanilopọ sibẹ. yoo si wa nibẹ titi laelae.

Àkọlé fídíò, 'Buns ni ọmọ mi jẹ tán ní ṣọ́ọ̀ṣì, ló bá di àwátì'

Bi a se lee lo iwe akọsilẹ orukọ awọn abanilopọ lọna aitọ:

  • Ko si aaye fun ẹnikẹni lati sadede fi orukọ eeyan kan sinu iwe akọsilẹ naa pe o huwa ibalopọ lọna aitọ
  • Iru ẹni ti orukọ rẹ yoo ba wọ iwe akọsilẹ ọhun gbọdọ ti kọkọ foju ba ileẹjọ, koju igbẹjọ, ti adajọ yoo si ti kede pe o jẹ ẹsun ibanilopọ lọna to lodi sofin, ki wọn to kọ orukọ rẹ silẹ, ti yoo si a faraye ri
  • A lee fi orukọ awọn eeyan to n ba ọmọde lopọ tabi ti wọn fẹsun kan, eyi ti adajọ ti gba pe o jẹbi ẹsun naa sinu iwe akọsilẹ ọhun.

Ninu alaye rẹ, Arinze Orogwe ni lootọ ni ijọba sefilọlẹ iwe iforukọsilẹ orukọ awọn eeyan to jẹbi ẹsun ifibanilopọ, amọ o wa n beere pe se yoo rọrun lati ri ọpọ orukọ awọn eeyan to jẹbi ẹsun naa tile ẹjọ ti se idajọ wọn.

Arinze ni awọn isoro kan wa to nii se pẹlu igbẹjọ awọn eeyan ti wọn fi ẹsun ibalopọ kan, ti awujọ ko ba si fọwọsowọpọ pẹlu ijọba, o lee soro pupọ lati sedajọ wọn, pẹlu afikun pe ti iwa ifipabanilopọ ba si n tẹsiwaju lawujọ, awọn araalu lo n faa.

Isoro to lee pagidina amulo iwe iforukọsilẹ orukọ awọn afipabanilopọ:

  • O seese ki amulo iwe iforukọsilẹ naa koju isoro pupọ nitori pe awọn ọmọ Naijiria kii fẹ jade sita lati wa fi ẹjọ awọn eeyan to ba bawọn lopọ sun tabi ọmọ wọn.
  • Eto igbẹjọ ati idajọ ileẹjọ nipa awọn eeyan ti wọn fẹsun kan pe o huwa ibalopọ lọna aitọ lee fori sọgi nigba ti awọn eeyan to yẹ ko jade bii ẹlẹri ba n fa sẹyin lati jade sita wa jẹri tako awọn eeyan naa.
  • "Awujọ wa kii se iwuri fun awọn eeyan ti wọn ba fi tipa lopọ lati jade sita wa fi ẹjọ sun, bakan naa ni ko si ilana atẹle lori iyara kankan lati gbe igbesẹ lori awọn ẹsun ifipabanilopọ ti wọn ba mu wa. Iwa ọdaran si ni iwa ọdaran n jẹ, ko yẹ ka maa dọwọ boo."
  • O lee ma rọrun lati gbọ irufẹ ẹjọ yii, paapa to ba jẹ pe awọn ẹjẹ kan naa ni wọn sẹ ara wọn, bii ki baba ba ọmọbinrin rẹ lo pọ lọna aitọ abi ki ẹgbọn fi tipa ba aburo rẹ obinrin sun tipatipa.
  • Awọn ẹjẹ kan naa kii fẹ jade wa jẹri tako ara wọn nitori pe inu mọlẹbi kansoso ni wọn ti wa, wọn kii si fẹ ki mọlẹbi wọn lọ sẹwọn, nitori naa ni yoo se nira lati se iru ẹjọ bẹẹ ni aseyanju.

Amọ oludari ẹka itaniji fun araalu labẹ ajọ Naptip wa rọ awọn araalu lati mase maa sa si abẹ ojiji wọn, ki ẹlẹsẹ ma baa lọ laijiya amọ ki wọn kan si ajọ naa, ki wọn si setan lati ba ẹjọ naa de opin, ki idajọ tootọ lee wa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: