Akẹkọ fasiti purọ mọ ọlọpa lẹyin to fowo ileewe ta MMM

Ọlaniyan Ọlayẹmi Joshua duro si iwaju ileesẹ ọlọpa ni Osogbo

Oríṣun àwòrán, Mama Akin

Àkọlé àwòrán, Ọlayẹmi fi owo ileewe ta kalokalo, o wa n sare kiri

Ọlaniyan Ọlayẹmi Joshua to jẹ akẹkọ ọlọdun kẹin ni fasiti ipinlẹ Ọsun, UNIOSUN ti wa lahamọ awọn ọlọpaa bayii lẹyin ti awọn mọlẹbi atawọn ọrẹ rẹ ti pariwo sita lori ẹrọ ayelujara wi pe agọ ọlọpa to wa l'Ojodu nilu Eko lo sọnu sii.

Ẹyin o rẹ yin ti ọwọ ọlọpa tẹ Ọlayẹmi lo to jẹwọ pe oun daa gẹgẹbii ọgbọn pe oun sun si ọgba agọ ọlọpa naa lẹyin ti ilẹ su oun silu Eko sugbọn to jẹ wi pe ilu Ilọrin ni oun gba lọ.

O ni Eko loun gba de Ilorin lojo keji koun too gbọ pe won ti n wa oun.

Ọlayẹmi ni bi oun se padanu owo ileewe oun si inu eto sogundogoji igbalode MMM lo faa ti oun fi n sa kaakiri lai ri ọna abayọ.

Awọn ọlọpa mẹfa n se ayẹwo ọkọ kan lalẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ igba lawọn eeyan ti di ẹru ti kii se ti ọlọpa le wọn lori

Nkan bii ọsẹ meji sẹyin ni ariwo gbode lori itakun ayelujara kaakiri wi pe ọdọkunrin kan ti di awati lẹyin ti o sọ wi pe oun fẹ sun si agọ ọlọpa to wa lagbegbe Ojodu nilu Eko.

Nigba ti awọn mọlẹbii rẹ yoo fi waa de ibẹ ni wọn fi to wọn leti pe eegun to n jẹ Ọlayẹmi ko fi igba kọọkan sẹyọ ni agọ naa gẹgẹbi o se sọ fun wọn.

Kọmisọna ọlọpa nipinlẹ Ọsun, Fimihan Adeoye ni irọ patapata ni gbogbo ohun ti Ọlayẹmi sọ fun awọn mọlẹbii rẹ atipe oun gan-an lo mọọmọ gbe ara rẹ pamọ.

Kọmisna ọlọpa Adeoye wa sekilọ fun awọn ti o nlo ẹrọ ayelujara lati tan iroyin irọ kaakiri ki wọn jawọ.