Hate Speech: Àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà kẹ̀yìn sí ìjọba lórí ofin sísọ̀rọ̀ àlùfànsá
Káákiri ìpínlẹ̀ tó lé ní ogún ni ìwọ́de náà ti ń wáyé lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Àkọlé àwòrán, Àwọn ọdọ Naijiria ni titasẹ agẹrẹ sinu ẹtọ ẹni lati sọ ohun tọkan ẹni fẹ gẹgẹ bo ṣe wa ninu ofin Naijiria ni igbesẹ ijọba yii.
Àkọlé àwòrán, "A o ni gba kẹẹ tun mu wa lẹru lẹẹkan sii".
Àkọlé àwòrán, Lara idi ti wọn tun fi n fẹhonuhan ni pe ki ijọba tu ajafẹtọ ati oludasilẹ ileeṣẹ iroyin Sahara reporters silẹ lahamọ ti wọn ti i mọ fun oṣu melo kan bayii.
Àkọlé àwòrán, Awọn afẹhonuhan naa taku si inu ọgba ile asofin agba l'Abuja.
Àkọlé àwòrán, Ẹ̀tọ́ wa ni! A ò ní gbà kẹ́ẹ buwọ́lu ofin tí yòó dí wa lẹ́nu lórí ayélujára
Àkọlé àwòrán, "Fun apẹrẹ, koo kan sọ fun eeyan pe "mo nifẹẹ rẹ, ki ijọba dẹ gbe ọbe le ọ lọrun, eyi pakasọ. Awọn afẹhonuhan ni ko si idi kankan to fi yẹ kaa ni awọn ofin wọnyii.
Àkọlé àwòrán, Ni ipinlẹ Eko, wọn ni abadofin eyi to lodi si iroyin ayelujara da bi ifipa ba ijọba awa ara wa lo pọ ni wọn si n fẹ ki gbogbo awọn aṣofin ipinlẹ ati aṣofin agba fọwọ wẹwọ lati yọ aba naa kuro ninu aato wọn patapata.
Àkọlé àwòrán, Awọn ọdọ Eko ni igbesẹ yii jẹ fifi ọwọ rẹ ijọba awa ara wa nimu ati pe lati igba ti ile igbimọ aṣofin yii ti bẹrẹ iṣẹ, ko si ofin kankan ti wọn ṣe to ba ifẹ awọn ọmọ Naijiria mu.
Àkọlé àwòrán, Awọn afẹhonuhan taku sẹnu ọna ile aṣofin ipinlẹ Eko lati ma jẹ́= ki ẹnikẹni wọle tabi jade sita ayafi bi wọn ba gbọ tiwọn.
Àkọlé àwòrán, Lara ija wọn ni kikoro oju si aba ofin to lodi si iroyin ori ayelujara labẹ eyi ti wọn ti ke si ijọba pe ki wọn da Omoyele Sowore oniroyin silẹ lahamọ to wa lati ọjọ yii.
Àkọlé àwòrán, Awọn ọdọ naa pa ẹnu pọ sọ pe ohun kan ṣoṣo tawọn ọmọ Naijiria ni lati sọrọ fun ara wọn ni ori ayelujara ati pe ki wọn fi ẹtọ wọn silẹ jẹjẹ ki wọn si ma ṣe ofin yẹn mọ rara.