Retirement Benefits: Èyí ni mùdùnmúdùn tó wà nínú owó ifẹ̀yìntì àwọn Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Google
Ko jẹ tuntun mọ pe awọn aṣofin ipinlẹ Zamfara ti wọgile owo ifẹyinti tabua ti awọn Gomina to fi ipo silẹ n gba.
Eyi ko ṣẹyin bi Gomina ana Abdulaziz Yari ṣe kọwe beere owo ifẹyinti rẹ oṣu meji ti wọn ko ti san fun.
Igbesẹ yii mu iriwisi ọtọọtọ wa, ti o si tun mi ki awọn eeyan ma sọrọ nipa bi owo obitibiti ṣe rọ mọ didi ipo mu lagbo oṣelu Naijiria.
Ki ọrọ naa ba le ye wa daada, a ni ki a darukọ awọn ipinlẹ miran ti wọn ṣe agbekalẹ ofin owo ifẹhinti fawọn Gomina ati igbakeji wọn, lẹyin ti wọn pari saa ijọba wọn.
Iru mudunmudun wo lo ba awọn owo ifẹhinti yii wa, eyi to yẹ ki a dijọ yẹ wo lawọn ipinlẹ kọọkan lorileede Naijiria, ti iru eto yii wa fawọn to ti fi ipo oselu silẹ
Kwara:
Lọdun 2018 ni ijọba ipinlẹ Kwara mu ayipada ba ofin to de sisan owo ifẹyinti fawọn to ti jẹ Gomina tabi igbakeji wọn ni ipinlẹ naa.
Wọn gbe igbesẹ yii lẹyin ti ariwo pọ lori bi awọn Gomina tele ri kan nipinlẹ ọhun, ti n gba owo laaye wọn gẹgẹ bi Sẹnẹtọ ati lakoto ijọba ipinlẹ bakanna.
Bukola Saraki ati Shaba Lafiaji wa lara awọn to jẹ Gomina tẹlẹ ri taa n sọ, ti wọn si tun jẹ Sẹnẹtọ to n soju agbegbe wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Toun ti pe ofin tuntun ni ki wọn mase san owo fawọn to di ipo miran mu lẹyin ti wọn fi ipo Gomina tabi igbakeji silẹ, wọn ko wọgile sisan owo yii bi ipinlẹ Zamfara ti ṣe ṣe.
Titi di bi a ti ṣe n sọrọ yii, owo tabua ati ajẹmọnu lofin bu fawọn to dipo mu tẹlẹ yii.
Lara mudunmudun ti ofin yii la kalẹ fun wọn ni pe:
- wọn yoo laanfaani ọkọ ayọkẹlẹ mẹta, ti ijọba yoo si ma parọ wọn lọdun mẹta mẹta
- wọn o fun wọn ni ile oniyara marun un
- owo ẹsọ taa ko sile (furniture allowance) ti iye owo rẹ jẹ ida ọgọrun mẹta owo oṣu wọn
- Awọn amugbalẹgbẹ marun un,oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ mẹta ti yoo ma ṣọ wọn
- itọju ilera ọfẹ fun Gomina ati igbakeji
- ida ọgbọn owo oṣu wọn gẹgẹ bi owo lati fi tun ọkọ ṣe ati awọn ajẹmọnu miran
Akwa Ibom:
Akwa Ibom labẹ ofin Pension Act, 2014 maa n na okere tan, miliọnu lọna mẹrinlelaadọjọ o le diẹ naira N174.16 lori awọn Gomina tẹlẹri, ti wọn a si ma na miliọnu lọna mẹtalelaadọrun o le diẹ naira, N93.62 fawọn to jẹ igbakeji gomina tẹlẹri.
Eleyi yatọ si miliọnu mẹẹdọgbọn naira ti wọn ma fi n parọ ọkọ fun wọn ati ẹgbẹrun mẹta milọnu ti wọn fi n kọ ile fawọn Gomina ana silu Abuja.
Senẹtọ Godswill Akpabio ni Gomina to wa lori oye nigba ti wọn gbe ofin yii kalẹ ni 2014.

2015 ni Akpabio pari saa keji rẹ gẹgẹ bii Gomina, ti o si tun bọ si ile aṣofin agba Naijiria gẹgẹ bi Sẹnẹtọ.
A ko le fidi ọrọ mulẹ boya o gba owo ifẹyinti yii lasiko to jẹ Senetọ ṣugbọn ipinlẹ Akwa Ibom ko ti mu ayipada tabi ki o pa ofin yii rẹ, di baa ti ṣe n sọrọ yii.
Eko:
Ofin ti ipinlẹ Eko ti wọn fi lọlẹ lọdun 2007 laa kalẹ pe, awọn Gomina tabi igbakeji wọn ti wọn ko ba yọ nipo laanfani lati gba deede owo oṣu wọn gẹgẹ bi owo ifẹhinti.
Wọn a tun fun wọn ni ile meji, ọkan ni ilu Eko ati omiran nilu Abuja, bi Gomina naa ba ṣe saa kan, ile kan ṣoṣo ni wọn yoo fun wọn.
Yatọ si awọn ohun ti a ka kalẹ yii, wọn tun n gba ọkọ ayọkẹlẹ mẹfa pẹlu awọn ajẹmọnu miran pẹlu oṣiṣẹ ti yoo ma ba wọn ṣiṣẹ.

Gomina mẹrin lo ti jẹ ni ipinlẹ Eko lati igba ti ijọba awarawa ti bẹrẹ. Lateef Jakande, Bola Tinubu, Babatunde Raji Fashola ati Akinwumi Ambode.
Tinubu ati Fashola ṣe saa meji pe perepere, ṣugbọn saa kan ni Jakande ati Ambode ṣe .
Osun:
Ọdun 2011 ni ofin ti wọn fidi mulẹ, deede owo ti wọn n gba lasiko ti wọn wa lori oye si ni owo ifẹhinti Gomina ati igbakeji rẹ.
Fawọn Gomina mẹrin to ti jẹ ni ipinlẹ naa, eeyan kọọkan gẹgẹ bi isiro kan ti iwe iroyin kan gbe jade lọdun 2017, yoo maa gba miliọnu meji naira le diẹ lọdun.

Oríṣun àwòrán, @Akinwumi Ambode
Sẹnẹtọ Isiaka Adeleke to ti doloogbe, Bisi Akande, Olagunsoye Oyinlola ati Rauf Aregbesola lawọn Gomina Osun to n jẹ mula yii.
Awọn ipinlẹ miran tawọn Gomina ati igbakeji wọn ti n jẹ iru anfaani yii
Loju opo Twitter wọn, BudgIT Nigeria fi orukọ awọn ipinlẹ ti ofin ṣe agbekalẹ owo ifẹhinti to yatọ si eleyi ti ajọ to n mojuto sisan owo fawọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria gbe kalẹ.
Awọn ipinlẹ naa re e:
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ọrọ owo ọna meji tabi ọna mẹta fawọn to di ipo mu tẹlẹ naa jẹ ohun ti o n kan awọn eeyan lominu.
Loju opo Twitter, n ṣe ni ero ṣe ọtọọtọ lori ofin ọhun
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

End of X post, 3

End of X post, 4