Oyo 2020 Budget: Èyí ni àtúpalẹ̀ abá ìṣúná 2020 tí Seyi Makinde gbé kalẹ̀

Seyi Makinde n gbe aba isuna ọdun 2020 siwaju awọn asofin Ọyọ

Gomina Seyi Makinde gbe aba eto isuna ọdun 2020 kalẹ siwaju awọn asofin lọsan ọjọru eyi ti apapọ rẹ le diẹ ni igba biliọnu naira (208,802,972,878.00bn).

Bi atupalẹ́ eto isuna naa se lọ ree ati ipin owo ti ẹka kọọkan ko ninu aba isuna ọhun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ẹka to se koko ninu eto isuna 2020 nipinlẹ Ọyọ:

Ipo Kinni: Eto isẹ ode ati ipese awọn ohun eelo amayedẹrun

  • Ẹka eto isẹ ode ati ipese awọn ohun eelo amayedẹrun lo ko ipin to pọ julọ ninu eto isuna ọdun 2020 nipinlẹ Ọyọ eyi ti apapọ owo ti wọn bu fun ko ida mẹtalelogun ati diẹ, 23.93%
  • Atunse oju ọna ati lila awọn opopona tuntun si ni yoo ko ọpọ owo isuna ti wọn bu fun ẹka naa lọ , ti biliọnu marundinlogoji ati diẹ, N35.4bn si wa fun asepari awọn oju ọna atijọ ati lila awọn oju ọna tuntun
  • Ijọba Ọyọ si ẹka ileesẹ to n se atunse awọn oju popo nipinlẹ Ọyọ OYSTROMA si ẹkun kọọkan lọna ti ri daju pe atunse n ba awọn oju popo to wa nipnilẹ Ọyọ loore koore
  • Tunwẹ, isẹ riri awọn ina oju popo yika ipinlẹ Ọyọ naa wa ninu eto isuna ọdun 2020.

Ipo Keji: Ẹka eto ẹkọ

  • Ẹka eto ẹkọ lo ko ida to tobi julọ sikeji ninu eto isuna ọdun 2020 nipinlẹ Ọyọ pẹlu ida mejilelogun ati diẹ, 22.37%
  • Eyi ni Gomina Seyi Makinde lo kọja iye ida ti ajọ UNESCO n beere ninu aba eto isuna ipinlẹ kan
  • Gomina ni eto ẹkọ ọfẹ ti gberasọ nipinlẹ Ọyọ, tijọba si ti pin iwe kika ati iwe ajakọ fawọn akẹkọ lọfẹ
  • Bakan naa ni o ti pin iwe idanwo tẹlẹri fawọn akẹkọ lati fi gbaradi, to si n fọwọ sọya pe ipinlẹ Ọyọ yoo kuro ni ipo kẹrindinlọgbọn to wa ninu esi idanwo WAEC to kọja
  • Ijọba tun ti n wọna abayọ lati tan ọpọ isoro to n koju awọn ileẹkọ nipinlẹ Ọyọ bii aito awọn olukọ, to si n gba awọn olukọ tuntun sẹnu isẹ, to fi mọ ipese eto aabo to peye sawọn ileẹkọ, paapa awọn ti wọn ko mọ odi yika wọn.

Ipo Kẹta: Ẹka eto Ilera:

  • Ẹka eto ilera lo ko ipo kẹta ninu eto isuna ọdun 2020 nipinlẹ Ọyọ pẹlu ida marun ati diẹ, 5.18%
  • Makinde awọn ileewosan to wa nipinlẹ Ọyọ ni wọn jẹ ibudo ibeere lasan tẹlẹ, amọ ti ijọba oun ti pese awọn irinsẹ feto ilera igbalode si ilewosan Adeọyọ, ti awọn irinsẹ igbalode naa yoo si kari gbogbo ilewosan ijọba to wa nipinlẹ Ọyọ bii Tede, Eruwa ati Isẹyin
  • Ijọba yoo tun gba ẹẹdẹgbẹta awọn olukọ si nipinlẹ Ọyọ.

Ipo Kẹrin: Ẹka eto Ọgbin:

  • Ẹka eto ọgbin lo se ipo kẹrin ninu eto isuna ti gomina Seyi Makinde gbe kalẹ lọjọru pẹlu ida mẹrinlelogoji ati diẹ, 44.3%
  • Gomina Makinde ni meji ninu awọn ibudo eto ọgbin mẹsan to wa nipinlẹ Ọyọ, eyiun eyi to wa ni Eruwa ati Akufo nijọba yoo sọ di oko ijọba
  • Olu ileesẹ ajọ to n ri si idagbasoke eto ọgbin nipinlẹ Ọyọ, OYSADEP nijọba ti gbe kuro nilu Ibadan pada si Saki
  • Ibudo iko ohun eto ọgbin si ti wọn n kọ lọwọ, eyi ti ẹjọ wa lori rẹ lo ti ni yanju bayii, ti agbasẹse si ti n ba isẹ lọ lori rẹ, eyi ti wọn ko ni pẹ si laipẹ.

Ipo Karun: Owona lori awọn osisẹ

  • Owona lori awọn osisẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ lo ko ipo karun ninu eto isuna 2020, ti adinku ida ọgọrun si ti wọ iye owo ti awọn osisẹ n gbe lọ nipinlẹ Ọyọ
  • Makinde ni ọjọ kẹẹdọgbọn osoosu ni awọn osisẹ n gba owo osu bayii bẹrẹ lati osu kẹfa ọdun 2019, ti wọn si tun ti san lara obitibiti owo ajẹmọnu awọn osisẹfẹinti to wa nilẹ
  • Owoya fun ilegbe ti wọn maa n fun awọn osisẹ ijọba, to jẹ miliọnu meji naira tẹlẹ lo ti di miliọnu mẹta naira bayii
  • Owoya fun ọkọ ayọkẹlẹ, to jẹ ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira tẹlẹ, lo ti di ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira
  • Ijọba ti gunle ayẹwo orukọ awọn osisẹ ipinlẹ Ọyọ, ti yoo si gbe wọn sori ẹrọ ayarabiasa fun akọsilẹ titi laelae.

Ipo Kẹfa: Owona fun isẹ akanse nlanla

  • Owona fun isẹ akanse nlanla lo se ipo kẹfa ninu eto isuna ọdun 2020 nipinlẹ Ọyọ pẹlu ida ogun, eyi to kere si owo ti wọn ya sọtọ fun ẹka naa ninu isuna ọdun to kọja, eyi to ko ida mẹtadinlaadọta ati diẹ. 47.9%
  • Owo tijọba yoo maa pa wọle yoo ru gọgọ si ti yoo ba fi di osu Kinni ọdun 2020, ti yoo si di biliọnu mẹta naira lai jẹ pe owo ori awọn araale fo soke si

Gomina Makinde wa fi ọwọ gbaya pe gbogbo owo ti oun ba na, ni oun yoo se atupalẹ rẹ fun araalu, ti eto isuna ọdun 2020 yoo se amusẹ rẹ doju ami

Makinde wa rọ ile asofin lati tete se agbeyẹwo aba isuna naa, ki wọn si fọwọsi, ki amusẹ rẹ lee gberasọ loju ọjọ.

Makinde gbé ìṣúná ọdún 2020 kalẹ̀, iṣẹ́ òde ló kó ìpín tó pọ̀ jùlọ

Seyi Makinde ati Olori ile asofin Oyo, Debo Ogundoyin

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe, Gomina ipinlẹ Ọyọ, onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti se agbekalẹ aba eto isuna ọdun 2020, tii se akọkọ iru rẹ ti yoo gbe kalẹ lati igba ti ijọba rẹ ti bẹrẹ, eyi to pe ni eto isuna awọn araalu, fun araalu.

Apapọ owo isuna naa si lo le diẹ ni igba biliọnu naira (208,802,972,878.00bn).

Nigba to n sọrọ lori aba isuna ọhun, Makinde ni adinku ida mẹrindinlogoji, 36% lo ba eto isuna naa yatọ si eyi ti ijọba ana gbe kalẹ lọdun to kọja, bakan naa si lo ni ida ogoji lo ba eto isuna ti wọn bu fun ile ijọba ati ẹka asofin nipinlẹ Ọyọ, yatọ si bo se maa n waye tẹlẹ.

Makinde wa fi gbogbo ọwọ sọya pe oun yoo ri daju pe wọn se amusẹ eto isuna naa, o kere tan, ida aadọrin ninu ọgọrun, ki ọdun 2020 to buse, lọna ati ba aini awọn araalu pade.

Awọn eeyan to joko sile asofin

Makinde tun salaye pe gbogbo isẹ akanse ti ijọ to kogba wọle nipinlẹ Ọyọ se ni asepati ni oun yoo pari, to si tun kede pe oun ti gbe olu ileesẹ to n ri si idagbasoke eto ọgbin OYSADEP pada si ilu Saki ti wọn ti gbe kuro.

Bakan naa lo salaye pe nibamu pklu isẹ titan ina yika ipinlẹ Ọyọ ti oun ti dawọ le, oun yoo tun ri daju pe gbogbo ipinlẹ Ọyọ ni wọn tan ina oju popo si, to fi de awọn aafin awọn ọba alaye bii Olubadan tilẹ Ibadan, Alaafin tilu Ọyọ ati Sọun ti Ogbomọsọ.

Seyi Makinde ati Olori ile asofin Oyo, Debo Ogundoyin

Lori eto ẹkọ, Seyi Makinde salaye pe nigba ti esi idanwo WAEC yoo ba fi jade lọdun to n bọ, ipo kẹrindinlọgbọn ti ipinlẹ Ọyọ wa yoo ti sun siwaju nitori ijọba ti n se aayan lati gba awsn olukọ si, to si ti n pese awọn iwe idanwo to ti kọja fun awọn akẹkọ lati fi gbaradi fun idanwo naa.