Eleruwa: Ilé ẹjọ lé Ọba Èrúwà kúrò lórí Àpèrè lẹ́yìn ọdun 21

Oríṣun àwòrán, Eruwa/facebook
Adájọ Ladipo Abimbola ti ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti ní ìdájọ tó gbé Ọba Adegbola wolé lọdun 2011 kìí ṣe èyí to tọ̀nà rárá nítori náà ìmúlẹ̀ múfo ni.
Adajọ naa ni pe orí àpèrè náà kò tọ́ síi.
Pẹ̀lú ìdájọ yìí, ìlú Eruwa, ní ìpínlẹ̀ Oyo ko lọ́ba báyìí.
Ilé ẹjọ gíga ni ìpínlẹ̀ Oyo nínu oṣù kínní ọdun 2011 ti yọ ọba náà nípò lo tún fi morilé ilé ẹjọ kotẹmilọrun láti wọ́gile ìdájọ ilé ẹjọ ipinlẹ Oyo.
Adajo Oladipo Abimbola ni ọ̀nà alùmọkọ́rọ́yí ni Ọba yii gbà dé orí ipò náà.
Ẹjọ kòtẹ́mílọrun ti ọgbẹ́ni Adegbola àti àwọn mẹ́fà míran fi ṣọ́wọ́ lòdì sí ọgbẹ́ni James Idowu àti àwọn mẹ́rin míràn wáye nítori idajọ Adájọ Abimbola pé ọnà to gbà de ori àpèrè kò tọ̀nà.
Ọgbẹ́ni Adegbola tó jẹ́ Eleruwa ti ilú Eruwa dórí oyè lọ́dún 1998, lẹ́yìn ti Oba Bolanle Olaniyan kú lọ́dun 1994.
Lásìkò ìdájọ to yọ Eleruwa nípò, adájọ ni gbogbo ìgbésẹ̀, láti ori yíyàn ọmọ oye to fi mọ bi ìjọba ṣe gbe ọ̀pá àṣẹ fún kò tọ̀na rárá.














