Thanksgiving Trump: Aàrẹ Trump kọ̀ láti jẹ Tọkí ìsìn ìdúpẹ́ 2019 nílé, ó gba Afghanista lọ!

Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aago mẹjọ abọ lalẹ ọ jọ Bọ ni aarẹ Trump de si Afghan ko to lọ pada laidagbere nitori eto aabo rẹ.

Aarẹ Donald Trump to n tukọ ilẹ America labẹ asia ẹgbẹ Republican ti lọ si orilé-ede Afhanista ni igba akọkọ.

Ni ayajọ ọjọ nla ninu itan America to jẹ ọjọ isin ọpẹ tọdun 2019 ni Trump ti ṣabẹwo sawọn ọmọ ogun naa.

Trump
Àkọlé àwòrán, Aarẹ Trump ṣabẹwo akọkọ si orilẹ-ede Afghanista

Aarẹ Trump kọkọ ya si papa ọkọ ofurufu Bagram Airfield lati sọro iwuri fawọn ọmnọ ogun to wa nibẹ.

O pin ẹran Tọki ati ounjẹ alẹ miran ti wọn pese silẹ fawọn ọmọ ogun to wa nibẹ, koda o ya fọto pẹlu ọpọ ninu awọn omọ ogun to wa nibẹ.

Lẹyin eyi lo ṣe ipade pọ pẹlu aarẹ Ashraf Ghani to n tukọ orilẹ-ede naa.

Aarẹ Trump ninu ọrọ rẹ fidiẹ mulẹ pe awọn Taliban ti ṣetan lati bawọn sọrọ bayii.

O ni America ti n din ọmọ ogun to wa ni Afghanista ku diẹdiẹ àti pe ẹgbẹrun mẹtala ọmọ ogun lo ku nibẹ lọdun mejidinlogun lẹyin ikọlu ọjọ kọkanla, oṣu késan an, ọdun 2001.

Ni ibẹrẹ oṣu yii ni awọn Taliban tu awọn ọjọgbọn meji silẹ ti wọn ti mu lati ọdun 2016 iyẹn: Kevin King ti America ati Timothy Weeks ti Australia.

Awọn meji yii ni wọn fi ṣe paṣipaarọ ọga agba ọmọ ogun ọlọtẹ Taliban mẹta.

trump
Àkọlé àwòrán, Aarẹ Trump ninu ọrọ rẹ fidiẹ mulẹ pe awọn Taliban ti ṣetan lati bawọn sọrọ bayii.

Trump fi da awọn ọmọ ogun loju pe didun lọsan a so lori ipe alaafia ti wọn fi silẹ ni gbendeke fun Taliban laipẹ.

O ti pẹ ti ijọba Afghan ti n pe fun alaafia ṣugbọn awọn alakatakiti Taliba to ti gba awọn agbegbe to pọ bayii ni rara.

trump
Àkọlé àwòrán, Aarẹ Trump lọ ṣe abẹwo ẹ kare sawọn ọmọ ogun ilẹ Amrica ni Afghanistan.

Awọn alaṣẹ Taliban ni tootọ ni ijiroro n waye.

Reuters ni wọn n pade pẹlu awọn ọga agba ọmọ ogun America ni Doha lati ọsẹ to kọja.

Kin lo tun ṣẹlẹ lasiko abẹwo Trump ni Afghanista?

Aago mẹjọ abọ lalẹ ọ jọ Bọ ni aarẹ Trump de si Afghan ko to lọ pada laidagbere nitori eto aabo rẹ.

Ile ijọba ilẹ America ni tootọ ni eto wa lati maa gbe ọrọ jade loju opo twitter Trump ki ara ma baa fu awọn oniṣẹ ibi lori irin ajo rẹ.

Adari ikọ apapọ ọmọ ogun America, Mark Milley lo kọkọ ki Trump kaabọ.

Aarẹ Trump fi idunnu rẹ fawọn ọmọ ogun ilẹ America pe tayọtaọ loun fi n jẹun idupẹ tọdun 2019 pẹlu wọn.

O gboriyin fun wọn gẹgẹ bi akọni loju ija to n san ẹbọ alaafia.

trump
Àkọlé àwòrán, Awọn alaṣẹ Taliban ni tootọ ni ijiroro n waye.

Aarẹ Ghani naa gboriyin fun wọn o si ni awọn ọmọ ogun Afghan naa ti n ji giri siṣẹ ogun lẹyin iranlọwọ America.

Trump

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Aarẹ Trump ninu ọrọ rẹ fidiẹ mulẹ pe awọn Taliban ti ṣetan lati bawọn sọrọ bayii.

Ounjẹ alẹ́ fùn idupẹ lọdọọdun ni America, Kini o tumọ si?

Idupẹ ni ọjọBọ ni oṣu kọkanla ni ọdọọdun ni orilẹ-ede America ṣe pataki pupọ sawọn eniyan ibẹ.

Idupẹ yii jẹ eyi ti onikaluku fi maa n ṣiro ibukun rẹ lọdun ti wọn yoo si fi imoore han si Ẹ lẹdaa wọn.

Wọn ni lasiko ti awọn ara Yuroopu rirnirnajo wa si America wa bẹrẹ igbe aye ọtun 1621.

adiyẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Thanksgiving Trump: Aàrẹ Trump kọ̀ láti jẹ Tọkí ìsìn ìdúpẹ́ 2019 nílé, ó gba Afghanista lọ!

Asiko yii lo maa n sami ibẹrẹ ayajọ keresi to jẹ ọjọ ibi Jesu Kristi ni America.

Ẹbi ati ara ati ọrẹ a jijọ jẹun alẹ ọjọBọ yii papọ pẹlu ayọ, wọn yoo dupẹ gbogbo oore ti wọn ti gbadun sẹyin.

Kini idi ti wọn fi maa n pa tolotolo?

Lati 1948 ni wọn ti n fun adari ọmọ ogun America ni tolotolo meji ṣaaju idupẹ naa ni eyi ti aarẹ yoo si gba ọkan ninu wọn la gẹgẹ bi aṣa.

Ko si ẹni to le sọ nipato idi to fi jẹ pe tolotolo ni awọn ara America maa n pa fi sami ayẹyẹ idupẹ yii.

idupẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn ẹbi kan ree lọdun 1935 ti wọn n jẹ ounjẹ alẹ idupẹ oṣu kọkanla ọdun naa

Awọn kan ni laye atijọ arinrinajo Edward Winslow kọ lẹta nipa ounjẹ adidun ti a fi tọkí ti oun ṣọdẹ sè.

Awọn miran sọ pe tolotolo pọ ni America nigba ti wọn da orilẹ-ede naa silẹ ni eyi to fi jẹ ki wọn maa pa wọn jẹ lasiko naa.

Won ni o le ni tolotolo aadọta miliọnu ti wọn n pa lọdọọdun ni amrica fun idupẹ ọdọọdun naa.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ