London Bridge: ọlọpàá kí àwọn aráàlú tó kojú agbésùnmọ̀mí náà kú akitiyan

London Bridge

Oríṣun àwòrán, @GeorgeBarden_

Àkọlé àwòrán, Wọ́n ti fi ọkunrin kan si àhámọ́ lori bi wọ́n ṣe gún ènìkàn lọ́bẹ pa lóri afárá London.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile isẹ ilu London ti ni agbesunmọmi ni arakunri to sekọlu si awọn ara London ni Ọjọ Eti ti awọn yinbọn pa.

Wọn darukọ rẹ pe, Usman Khan ni, ati wi pe o ti se ẹwọn ri lori ẹsun to jẹ mọ igbesumọmi ni ọdun 20-12.

Stafford

Awọn ọlọpaa ni ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa ni awọn fi silẹ lọdun naa lọhun pẹlu ẹjẹ pe ko ni wuwa buruku lawujọ.

Eniyan meji lo padanu ẹmi wọn ninu isẹlẹ naa, ti mẹta si farapa.

Ilẹ isẹ ọlọpaa naa fikun pe iwadii n tẹsiwaju lori isẹlẹ naa, a ti wi pe awọn ti n tọpinpin bọya oun nikan lo se igbesunmọmi naa tabi pẹlu iranwọ awọn ẹlomiran.

Wàhálà to bẹ́ sílẹ̀ jọ ìgbésùnmọ̀mí, ọlọpàá yìnbọn pa ẹnikan.

Iròyìn to ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ lórí afárá London ni pé àwọn ọlọpàá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni àwọn ti pa ọkùnrin kan ọ́wọ́ ìgbésùmọ̀mi si ni àwọn fi mú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

People fleeing from the scene

Oríṣun àwòrán, PA Media

Ní báyìí wọ́n ti tí orí afára náà pa ti wọ́n si pa ọkùnrin kan to n gún àwọn ènìyàn lẹ́gbẹ̀ẹ́ afárá náà

Awọn ọlọpàá MET sàlàyé pé àwọn gba ìpè pé ẹnikan n gú àwọn ènìyàn lágbègbè afárá náà ni ààgo meji ku díẹ̀ lọ́sàn oni

Wọ́n fi kun pé àwọn ti mú ọkùnrinkan si ahámọ àwọn nítori pé kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ tó kan wáyé lásàn.

Ọlọpàá sọ pé ọkùnrin ti wọ́n yìn ni ìbọn náà to si kunibi iṣẹ̀lẹ̀ náà ni àwọn àdó olóro to dì mọ́ra.

London bridge

Oríṣun àwòrán, AFP/Getty Images

Fọ́nran kan lori ayélujára sàfihan bi wọ́n ṣe n di okunrin kan mọlẹ lori afára náà, lẹ́yìn náà ni àwọn ọọpàá de ti wọ́n si ni ki àwọn ènìyàn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ti wan si yín ọkùnrin náà nibọ̀n.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Akoroyìn BBC John MaManus to wà nibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà sàlàyé pé òun ri àwọn agbárijọ ọkunrin kan lori afára náà ti wọ́n n jà.

Àkọlé fídíò, Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!

Lẹ́yin náà ni àwọn ọlọpàá de ti wọ́n sì da ìbọn bolẹ̀ àwọn ọlọpàá to dé ibẹ̀

Awọn ọlọpàá ti gba àwọn ènìyàn ni ìyànjú pé ki maa tẹ̀lé ìlànà ti àwọn ọlọpàá fi lélẹ̀.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ