Èèyàn méjì kù, ọlọ́pàá mú afunrasí 75 nínú làásìgbò tó bẹ́ sílẹ̀ ní àdúgbò Pákó-Aguda

Oríṣun àwòrán, Twitter/rrslagos767
Eeyan meji lo ku ninu laasigbo to waye ladugbo Pako Aguda Surulere nilu Eko lọjọ Aje.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nilu Eko Bala Elkanna to fidi ọrọ yi mulẹ sọ pe ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn afunrasi àádọ́rin to kopa ninu ija to waye naa.
Niṣe ni ọrọ di boolọ ọ yago mi ni adugbo Pako Aguda lagbegbe Ijẹṣa Tẹdo, Surulere nilu Eko nigba tawọn janduku ṣe ikọlu ara wọn.
Ikọ awọn janduku ti wọn n fi ada ṣọṣẹ tawọn miiran si n yinbọn soke la gbọ pe wọn da adugbo ru ti onikaluku si n sa asala ẹmi rẹ.
Akọroyin wa, to ṣabẹwo sadugbo naa lẹyin ti gbogbo nkan ti rọlẹ sọ pe ija emi lọga iwọ kọ lo wa nidi ikọlu naa.
Akọroyin BBC sọ pe ijokoo mẹrinla lo n dari awọn agbero ni ipinlẹ Eko tẹlẹ ki wọn to fẹ sọọ di mẹrin.
Wọn yan agbegbe Palo Aguda lati fa ẹni kan kalẹ gẹgẹ bii olori ninu awọn mẹrin ti wọn fẹ yan ni eyi ti awọn kan ninu awọn agbero naa ko fẹ ẹni naa.
Abey to jẹ ọkan ninu awọn agbero naa ni ibọn kọkọ ṣeeṣi ba bakan naa, iroyin sọ pe awọn eeyan mẹta padanu ẹmi wọn tawọn janduku naa si ba ọpọlọpọ dukia jẹ nibẹ.
Ikọ ọlọpaa ayarabiaṣa nilu Eko ti a mọ si Rapid Response Squad loju opo Twitter wọn sọ pe awọn ti dẹwọ aawọ naa tawọn afurasi kan si ti wa lahamọ.

Oríṣun àwòrán, Twitter/rrslagos767
Ninu ọrọ ti wọn fi sita yi, wọn fidi ọrọ mulẹ pawọn janduku lo n ṣe ikọlu si ara wọn ṣugbọn wọn ko sọ boya eeyan kankan padanu ẹmi rẹ ninu ija naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ija laarin awọn janduku nilu Eko kii ṣe nkan ajoji.
Bi awọn awakọ ero ti a mọ si NURTW ko ba maa ṣe ikọlu si ara wọn, awọn ọmọ onilẹ naa a maa da wahala silẹ laarin adugbo.
Pupọ ninu awọn ikọlu wọnyi lo maa n ko ara adugbo laya soke ti ẹmi a si maa bọ nigba miran.














