Ọlọ́pàá mú ìyàwó igbákejì ààrẹ Zimbabwe lórí ẹ̀sùn jẹgúdújẹrá

Oríṣun àwòrán, @ZimbabweZoom
Ajọ ọlọpaa orilẹ-ede Zimbabwe ti fi panpẹ ofin mu iyawo igbakeji aarẹ orilẹ-ede naa Constantino Chiwenga, lori ẹsun jẹgudujẹra.
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede ọhun sọ pe Marry Mubaiwa yoo foju bale ẹjọ lonii.
Lara ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o ra ọkọ olowo gọbọi meji lorilẹ-ede South Africa.
Wọn tun ni Constantino fi owo to le ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbaarun dọla ranṣẹ si South Africa lọna aitọ, pe oun fẹ fi ko ọja wọle, ti ko si ri bẹẹ.
Laipẹ yii ni awọn iroyin kan sọ pe arabinrin naa n gbe igbesẹ lati jawe ikọsilẹ fun ọkọ rẹ.
Aarẹ orilẹ-ede ọhun, Emmerson Mnangagwa n dojukọ ipenija nla lataari ọrọ aje to denu kọlẹ.

Oríṣun àwòrán, @Graphenes1
O si ti pinnu lati gbogun iwa ibajẹ lorilẹ-ede naa.









