Òkò ọ̀rọ̀ ń bọ́ bí Ibadan àti Oyo ṣe ń tahùn síra wọn lórí ẹni tí ipò alága ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba l'Oyo tọ́ sí

Oríṣun àwòrán, Others
Alaafin ti ilu Oyo, Oba Akeem Ọwọade ti ni inu oun dun pupọ, ti oun si fọwọ si igbesẹ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo lati sọ Alaafin di alaga laelae fun igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo.
Agbẹnusọ fun oriade naa, Bode Durojaye lo sọ eyi di mimọ lasiko to ba BBC Yoruba sọrọ lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ.
Durojaye ni iwọsi nla lo jẹ fun Alaafin lati ma pin ipo alaga jẹ pẹlu awọn Oba to ku nitori Alaafin ki I ṣe ẹni Arifin rara.
"Igbesẹ nla ni eyi jẹ nitori abuku nla ni ki Alaafin ma ba Ọba miiran ma pin oye jẹ.
Ọwọ nla lo yẹ ki a fun Alaafin.
"Ta a gan lo kaju ẹ lati gbena wo oju Alaafin, ewo ninu awọn Ọba nipinlẹ Oyo lo ni irufẹ ifẹ apọnle ti alaafin ni, ṣe Olubadan, Soun tabi Olugbon ni? "
"Alaafin nifẹ si igbesẹ yii, to si fọwọ si pẹlu.
Alaafin nikan lo lẹtọ lati jẹ alaga lọbalọba nipinlẹ Oyo, ti a ba wo o lati ibi itan ati agbara."
Ninu ọrọ rẹ, Durojaye ni pẹlu itan adayeba, ko si Ọba kankan nipinlẹ Oyo to le fi ẹgbẹ kẹgbẹ pẹlu Alaafin nibikibi.
O ni awọn ilu yoku to n fariga lori igbesẹ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo, ni ẹtọ lati ṣe bẹẹ ṣugbọn o ni ko si ẹnikẹni ninu wọn toto bẹẹ lati gbena woju Alaafin Oyo.
"Ta a gan lo kaju ẹ lati gbena wo oju Alaafin.
Wọn ni ẹtọ lati fi ẹdun ọkan wọn han sita lori abadofin ṣugbọn otitọ ni pe Alaafin ni olori fun awọn lọbalọba nigba kugbakugba.
"Emi ko ri pe igbeṣẹ yii le fa wahala nipinlẹ Oyo, ṣugbọn ẹ ma jẹ ka fi ọrọ si abẹ ẹnu sọ.
Ewo ninu awọn Ọba nipinlẹ Oyo lo ni irufẹ ifẹ apọnle ti alaafin ni, ṣe Olubadan, Soun tabi Olugbon ni."
"Awọn asiko kan naa wa to jẹ pe Ibadan lo n da ri gbogbo ilẹ Yoruba nigba ti Oyo Empire fọ, igba kan wa ti Ibadan paṣẹ fun Alaafin lati ma ko ẹrẹ wa si ibadan lati kọ aafin Ogumola"
Aarẹ fun gbogbo Mogaji nilẹ Ibadan, Mogaji Nurudeen Akinade naa ba BBC Yoruba sọrọ pe gbogbo nnkan ti ilu nilo lati di alaga igbimọ lọbalọba ni ilu Ibadan ni, to si jẹ pe eyi gan lo fa ti ijọba lasiko Gomina Alao Akala fi gbe ofin naa sita lọdun 2011.
Akinade ni Ibadan ti fi igba kan dari gbogbo ilẹ Yoruba nigba ti ilu Oyo fọ.
"Iha ti a kọ si igbesẹ yii ni gbogbo ibadan kọ si nitori a mọ itan.
"Ko si ẹni to n ba Alaafin ja. Ti wọn ba n sọ pe Alaafin n bẹ nigba kan ri, awọn asiko kan naa wa to jẹ pe Ibadan lo da ri gbogbo ilẹ Yoruba nigba ti Oyo Empire fọ, Ibadan lo gba wọn silẹ."
Akinade tẹsiwaju pe, ko si nnkan to buru ninu pe ki awọn Ori Ade nla mẹta nipinlẹ Oyo ma pin ipo alaga naa jẹ.
"Ko si nnkan to buru ninu rẹ, bẹẹ ti a ba ni ki Olubadan jẹ, Alaafin jẹ, ki Soun naa jẹ.
Ti a ba ni ki a ma sọ itan, nnkan yoo bajẹ.
Igba kan wa ti Ibadan paṣẹ fun Alaafin lati ma ko ẹrẹ wa si ibadan lati kọ aafin Ogumola.
"Ijọba Ipinlẹ Oyo ti gbe igbesẹ yii pe ki awọn Oba ma pin ipo alaga jẹ, ti Oba Odulana Odugbade, Olubadan lasiko naa si dari ipade naa."
Akinade wa fi ọrọ ransẹ si awọn aṣofin ipinlẹ Oyo pe, ki wọn mase gbe igbesẹ ti yoo ṣe akoba nla fun wọn.
"Mo n rọ awọn aṣofin ile igbimọ, paapa awọn to jẹ ọmọ Ibadan, lati maṣe nnkan ti yoo ko ba ara wọn.
Ohun ti Ibadan ba fẹ ni ki wọn ṣe fun Ibadan. Mo si mọ pe wọn ko ni gbe igbesẹ to le ṣe akoba fun ara wọn."
Ilé aṣòfin bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti sọ Aláàfin di alága ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba l‘Oyo, Olubadan ni igbákejì, Soun ni igbá kẹta, Olubadan bá yarí
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti bẹrẹ igbesẹ lati mu atunṣe ba ofin igbimọ lọbalọba ati ijoye nipinlẹ Oyo.
Ijiroro ile asofin lori eyi waye ni Ọjọ kẹẹdogun oṣu karun un ọdun 2025 ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo.
Saaju ninu iwe ofin lọbalọba ti ọdun 2000, Alaafin ni olori igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo pẹlu aṣẹ lati ọwọ ijọba lati dari ipade ati awọn nnkan mii .
Ṣugbọn lasiko iṣejọba Gomina Adebayo Alao Akala, atunṣe ba ofin naa lọdun 2011, ti wọn si yi ofin ọhun pada si pe ki awọn Ọba ma pin ipo alaga jẹ.
Ipo naa wa laarin Alaafin Oyo, Olubadan ti ilẹ Ibadan ati Soun Ogbomoso.
Abadofin tuntun ti ọdun 2025 naa to wa ni iwaju ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo bayii lo n gbero lati da ofin ọdun 2000 pada, eyi ti yoo sọ Alaafin di alaga laelae fun igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo.
"Ipo Alaga laelae ti igbimọ lọbalọba yoo jẹ ti Alaafin ti ilu Oyo, ti Olubadan ti ilẹ Ibadan ati Soun ti Ogbomoso yoo si ma pin ipo igbakeji alaga jẹ," Ofin naa ṣalaye.
Eyi tumọ si pe Alaafin yoo ma dari ipade awọn lọbalọba, ti Olubadan yoo si ma rọpo Alaafin lasiko ti aye ba yọ.
Ẹwẹ, ti Alaafin ati Olubadan ko ba si ni ile, Soun ti ilẹ Ogbomoso yoo ma dari ipade.
Ọpọ eeyan ni ko tẹwọ gba igbesẹ yii rara
Apapọ ẹgbẹ ọmọ Ibadan, Mogaji tako igbesẹ to sọ Alaafin di alaga laelae fun igbimọ lọbalọba
Ẹgbẹ gbogbo ọmọ bibi ilẹ Ibadan CCII, Mogaji ilẹ Ibadan, Baalẹ ati Ọba ni wọn ti dide tako igbesẹ ijọba ipinlẹ Oyo lati sọ Alaafin ti ilu Oyo di alaga laelae fun igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo.
Bakan naa ni ẹgbẹ ọmọ Ibadan tun ṣe ikilọ fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo pe, ki wọn mase da rogbodiyan silẹ, ti wọn si tẹnu mọ pe ipo alaga igbimọ lọbalọba jẹ ipo ti wọn ma n pin jẹ, ki ṣe fun eeyan kan ṣosọ.
Ninu atẹjade ti Aarẹ Mogaji ilẹ Ibadan, Mogaji Nurudeen Akinade fisita, Ibadan ko fi igba kankan jẹ igbakeji si Oyo ṣugbọn o wa fun aabo gbogbo ilẹ Yoruba.
Akinade ni igbala Ibadan tobi, to si ti gba ilẹ Yoruba silẹ ni ọpọ igba.
O tẹsiwaju pe ti Ibadan ko ba ṣe idaduro fun awọn Fulani lasiko ogun Fulani, ọpọ ilẹ Yoruba ni yoo jẹ pe Emir ni yoo maa jẹ ni ilu wọn.
"Oloye Obafemi Awolowo ko le di olori ijọba iwọ oorun Naijiria ti ki i ba ṣe ti awọn ọmọ Ibadan to fọwọsowọpọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu Action Group (AG) lati koju NCNC ti Nnamdi Azikwe.
"Ibadan ti n gba ilẹ Yoruba silẹ fun ọjọ pipẹ, ko si igba kankan ti a jẹ ipo keji si Oyo tabi ilu kankan nilẹ Yoruba, koda Ibadan lo yẹ ko jẹ alaga laelae fun igbimọ lọbalọba.
"Nitori a ko sọrọ ko tumọ si pe a ya oponu rara.
Nigba ti Ibadan ko ja fun ipo Alaga laelae, ki lo de ti Oyo fi fẹ ṣe bẹẹ? Ile igbimọ aṣofin yoo da ara wọn ni ẹbi ti abadofin yii ba di ofin.
"Gomina nigba kan ri, Christopher Alao Akala lo bu wọlu ki ipo alaga lọbalọba jẹ pinpin lasiko iṣejọba rẹ.
Oba Samuel Odulana Odugbade, si lo jẹ alaga fun igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo.
Ibadan ko ni tẹwọgba aba yii rara nitori awa ni a maa n siwaju ninu gbogbo nnkan."
















