Kí ló mú kí ìjọba Kwara gbé ilé ẹ̀kọ́ girama méjì tipa n'Ilorin?

Aworan ile ẹkọ girama n'Ilorin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ipinlẹ Kwara ti gbe ile ẹkọ girama Government High school, Adeta ati Government Day Secondary School, Adeta ni ilu Ilọrin ti pa.

Kọmisona feto ẹkọ ni ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọlọhungbẹbẹ Lawal, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe ijọba ti awọn ile ẹkọ naa latari aawọ to bẹ silẹ laarin awọn akẹkọọ lati ile ẹkọ mejeeji.

O fikun ọrọ rẹ pe awọn akẹkọọ ti wọn se idanwo asekagba ile ẹkọ girama WAEC nikan ni wọn yóò fun laaye lati maa wọ ọgba awọn ile ẹkọ naa bayii.

Ọjọ pẹ ti ija ti n waye laarin ile ẹkọ méjèejì - Akẹkọọ

Kọmiṣọna eto ẹkọ sọ pe ijọba ipinlẹ Kwara ko ni faramọ iwa jagidijagan lawọn ile ẹkọ.

O wa rọ awọn obi lati maa ri pe wọn ba awọn ọmọ wọn sọrọ lati yago fun iwa jagidijagan nile ẹkọ.

Lasiko to n ba BBC yoruba sọrọ lori iṣẹlẹ naa, ọkan lara awọn akẹkọọ, ọdọkunrin Lukman Mohammed, sọ pe ija to wa laarin ile ẹkọ méjèejì naa ti pẹ.

O fikun ọrọ rẹ pe lọpọ igba ni ija maa n waye laarin awọn akẹkọọ ile ẹkọ méjèjì naa.

''Ibẹru bojo gbalẹ lasiko ti awọn akẹkọọ naa n fi ada le ra wọn kiri''

Aworan ile ẹkọ girama n'Ilorin

Ninu ọrọ tiẹ, Ọgbẹni Yusuf to jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ naa sọ pe, ada ni awọn akẹkọọ naa yọ si ra wọn nigba ti wọn n ja.

O salaye pe ibẹru bojo gbalẹ lagbegbe naa lana Ọjọru ọjọ kẹrinla oṣu Karun un yii lasiko ti awọn akẹkọọ naa n fi àdá le ra wọn kiri inu ọgba ile ẹkọ naa.

Ọgbẹni Yusuf tun sọ pe lọpọ ìgbà obinrin lo maa n da ija silẹ laarin wọn.

O ni ọkan lara awọn akẹkọọ naa ti oun beere idi ti wọn fi n ja lọwọ rẹ sọ fun oun pe awọn akẹkọọ naa gba ọrẹbirin ara wọn ni.

Lasiko ti oun naa n ba BBC yoruba sọrọ, ọkan lara awọn obi awọn akẹkọọ, Arabinrin Muji, sọ pe ọrọ aawọ ile ẹkọ mejeji naa nilo igbesẹ kiakia.

Arabinrin Muji rọ ijọba ipinlẹ Kwara lati mọ odi to ga fi paala saarin awọn ile ẹkọ mejeji.

BBC Yoruba gbiyanju lati ba alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara sọrọ, ṣugbọn ko gbe ago rẹ.

Nigba ti BBC Yorùbá ṣabẹwo sawọn ile ẹkọ naa laarọ oni Ọjọbọ, se ni gbogbo rẹ da paroparo.

Koda, ni ṣe lawon oṣiṣẹ ile ẹkọ naa n da awọn akẹkọọ pada sile wọn, ayafi awọn to ba fe se danwo WAEC nikan ni wọn fun laaye lati wọle.