"Ìyàwó àti ọmọ mi márùn-ún kú lọ́jọ́ kan ṣoṣo lẹ́yìn tí wọ́n jẹ ìrẹsì tán"

Aworan Arinze Robinson Ahalu,
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ibanujẹ dori agba kodo, ọkunrin kan ti ṣalaye bi o ti padanu ọmọ rẹ mẹrin ati iyawo lọjọ kan ṣoṣo.

Lọjọ kẹta oṣu Karun un ọdun yii ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni 7th Mile Nkwelle-Ogidi ni ijọba ibilẹ Ariwa Idemili nipinlẹ Anambra.

Ọkunrin naa, Arinze Robinson Ahalu, ṣalaye ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC pe irẹsi lawọn ọmọ oun ati iyawo jẹ lọjọ naa, ti wọn si gba ibẹ ku.

Ọgbẹni Ahalu ni mama awọn ọmọ naa lo se irẹsi ti wọn jẹ lalẹ ọjọ naa, ki onikalulu to lọ sun.

Amọ, o ni ko pẹ ti wọn jẹun tan ni inu bẹrẹ si i run ọkan ninu awọn ọmọ naa ti o si n bi.

Loju ọna wọn sile iwosan ni ọmọ naa ti jẹ Ọlọrun nipe, lẹyin naa lawọn ọmọ yoku ati mama wọn naa bẹrẹ si ni bi .

Bayii lawọn oṣiṣẹ ile iwosan ti wọn gbe wọn lọ sọ pe ki wọn maa gbe awọn eeyan lọ si ile iwosan mii tori wọn o mọ nnkan ti wọn le ṣe mọ.

Amọ, ẹmi ti bọ lẹnu awọn maraarun ki wọn to de ile iwosan mii.

''Eleyii to dagba julọ ninu awọn ọmọ mi ni ọdun mẹtadinlogun, ọmọ ọdun mẹẹdogun ni eyi to tẹle e nigba ti ẹlẹkẹẹta jẹ ọmọ ọdun mẹtala.

Ọmọ ọdun mọkanla ni ẹlẹẹkẹrin nigba ti abigbẹyin jẹ ọmọ ọdun mẹsan,'' Ọgbẹni Ahalu ṣalaye.

Ọkunrin naa n bẹ ijọba wi pe ki wọn kọ ile ti oun le maa gbe fun oun tori oun ko nile lori.

Kate Valentine Nwafor, to jẹ aburo ọkunrin naa ni ibanujẹ nla ni iku awọn ọmọ naa ati iya wọn jẹ fun gbogbo ẹbi.

Ọgbẹni Ahalu tun rọ ijọba lati se iranwọ fun oun lori ọmọ kan ṣoṣo to ku, eyi to n ṣe idanwo WAEC lọwọ.

Ohun ti ọlọpaa Anambra sọ lori iṣẹlẹ naa

Aworan Ọlọpaa Anambra

Oríṣun àwòrán, Anambra State police

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ti sọ pe awọn ti gbe ile ti iṣẹlẹ yii ti waye ti pa lagbegbe Ogidi nijọba ibilẹ ariwa Idemili nipinlẹ Anambra.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ọmọ iya kan naa mẹrin lo ku nibi iṣẹlẹ ọhun.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra, Tochukwu Ikenga, lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọlọpaa lo ko oku awọn ọmọ naa lọ si ile igbokusi.

Ọgbẹni Ikenga sọ pe iya awọn ọmọ naa, toun naa jẹ ninu ounjẹ ọhun si n gba itọju lọwọ nile iwosan.

Agbẹnusọ ọlọpaa ni iṣẹ iwadii ti bẹrẹ lori isẹlẹ naa, ati pe ayẹwo n lọ lọwọ lori irẹsi ti ẹbi yii jẹ ti wọn fi dero ọrun.

O wa fi da araalu loju pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo tu iṣu de isalẹ ikoko lati mọ ohun to ṣokunfa iku awọn ọmọ naa.