Lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ kejì ní ikùn rẹ̀, Taiwo Awoniyi jí sáyé padà, ó kúrò ní ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run

Aworan Taiwo Awoniyi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Agba ọwọ iwaju Nottingham Forest ati ikọ Super Eagles, Taiwo Awoniyi ti ji lati ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun to wa, lẹyin isẹ abẹ to se.

Awoniyi lo farapa yanayana lasiko ifẹsẹwọnsẹ to gba fun ikọ agbabọọlu rẹ nilẹ Gẹẹsi.

Awoniyi ni wọn gbe digbadigba lọ ile iwosan ni ọjọ Aje, lẹyin to kọlu opo oju ile bọọlu lori paapa nigba ti ikọ agbabọọlu rẹ n koju ikọ Leicester City lọjọ Aiku to kọja.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni ikọlu Awoniyi naa ṣe ọpọ akoba fun awọn ifun inu rẹ.

O ṣe iṣẹ abẹ lọjọ Aje, ti o si lo gbogbo Ọjọ Isẹgun ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun.

Lọjọru, Awoniyi ṣe iṣẹ abẹ keji, ti wọn di oju awọn egbo to ni.

O taji ni irọlẹ Ọjọru, to n si gba itọju ni ile iwosan.

Taiwo Awoniyi

Àlàyé rèé lórí ìkọlù tó gbé Taiwo Awoniyi dé ilé ìwòsan tó fi wọ ‘Coma’

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe gbajumọ agbabọọlu to jẹ ọmọ ilẹ Naijiria, Taiwo Awoniyi, ẹni to tun n gba bọọlu fun ẹgbẹ agbabọọlu Nottingham Forest, ti wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun bayii.

Awoniyi lo dero ile iwosan lati se isẹ abẹ isọri kinni lori ọgbẹ to ni nikun rẹ, ti ko si ti i laju saye lẹyin isẹ abẹ naa.

Gbajumọ agbabọọlu ọhun, tii se ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn lo kọlu opo ojule lasiko ifẹsẹwọnsẹ Nottingham Forest pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Leicester nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ isẹju mejidinlaadọrun.

Isẹlẹ naa to waye ni papa isere Ground City lọjọ Aiku lo waye nigba ti agbabọlu naa n gbidanwo lati gba bọọlu lọwọ Anthony Elanga.

Atẹjade kan ti ẹgbẹ agbabọọlu Nottingham Forest fisita ni ara Awoniyi ti n ya lẹyin isẹ abẹ naa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ikọ elere idaraya ileesẹ BBC gbọ wipe ifun Taiwo Awoniyi bẹ lasiko to kọlu opo ojule naa

Alẹ ọjọ Aje ni wọn yara se isẹ abẹ fun to si w anile iwosan naa to si seese ki wọn pari awọn igbesẹ to ku nidi itọju rẹ ni ọjọru.

Atẹjade kan ti ẹgbẹ agbabọọlu Nottingham Forest fisita lọjọ Isẹgun ni ara Awoniyi ti n ya lẹyin isẹ abẹ naa.

Awoniyi, ẹni ti wọn fi rọpo Ibrahim Sangare nigba to ku diẹ ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari lọjọ Aiku, ni wọn kọkọ fun ni itọju pajawiri fun igba pipẹ lori papa ti wọn ti n gba bọọlu naa.

Elanga lo wa ni odikeji nigba to tẹwọgba bọọlu amọ ti igbakeji alamojuto ere bọọlu naa ko gbe asia soke titi ti ikọlu Awoniyi fi waye.

Ẹni to ni ikọ agbabọọlu Forest naa, Evangelos Marinakis wa bọ sori papa lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa, to si fi erongba rẹ han si alakoso ẹgbẹ agbabọọlu naa, Nuno Espirito Santo, lori ọwọ ti wọn fi mu itọju ọgbẹ Awoniyi.

Atẹjade ti ẹgbẹ agbabọọlu Forest fisita naa ni ọgbẹ ti Taiwo Awoniyi ni lori papa yii lo jẹ ohun iranti nipa ọpọ ewu to rọ mọ ere idaraya naa ati idi tie to ilera agbabọọlu kọọkan ati alafia wọn se gbọdọ jẹ ohun pataki lati kọkọ mu lọkunkundun.

Ta ni Taiwo Awoniyi?

Ọjọ Kejila osu Kẹjọ ọdun 1997 ni wọn bi Taiwo Michael Awoniyi sile aye ni ipinlẹ Kwara.

Akọsẹmọsẹ agbabọọlu ni Awoniyi, ẹni to n gba bii agbaarin fun ẹgbẹ agbabọlu fun Nottingham Forest ati ikọ agbabọọlu Naijiria.

Lọdun 2010 ni wọn dibo yan Awoniyi bii agbabọọlu to se iyebiye julọ nibi idije ere bọọlu ti Cocacola se onigbọwọ rẹ nilu London.

Isọwọ gba bọọlu Awoniyi lo mu ki gbajumọ agbabọọlu, Seyi Olofinjana kiye si, to si ransẹ pe e lati dara pọ mọ ile ẹkọ fawọn agbabọọlu, Imperial Soccer Academy.

Awoniyi lo gba bọọlu fun Naijiria nibi idije ife ẹyẹ agbaye fawọn ọjẹ wẹwẹ agbabọọlu ti ọjọ ori wọn ko to ọdun mẹtadinlogun lọdun 2013.

O si yege ninu idije ere bọọlu naa pẹlu ami ayo mẹrin.

Awoniyi jẹ ibeji, ti ekeji rẹ, Kehinde si jẹ obinrin.

Gbajumọ agbabọọlu naa lo seto idana pẹlu ibeji miran, Taiye Jesudun ni ọjọ kẹẹdogun osu Kẹfa ọdun 2018 nilu Kabba nipinlẹ Kogi.

Igbeyawo wọn lo waye nilu Ilorin ni ọjọ keji idana naa, ọmọlẹyin Kristi ni Taiwo Awoniyi I se.