"Àwọn ológun wà níbí lóòótọ́, ṣùgbọ́n kò sí ààbò fún wa"

Boko Haram

Oríṣun àwòrán, Boko Haram

Àkọlé àwòrán, Ikọ Boko Haram, ọdun 2009 ni wọn gberasọ
    • Author, Aisha Babangida
    • Role, Broadcast Journalist
    • Reporting from, BBC News, Abuja
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ni oṣu Kẹsan-an ọdun to kọja, lẹyin ti Boko Haram kọlu ilu kan ti a mọ si Mafa, nipinlẹ Yobe, apa Ariwa-Ila Oorun Naijiria, iṣẹlẹ naa mu ẹru wa si ọkan awọn eeyan pada, wọn bẹrẹ si i ronu pe ogun tawọn ro pe o ti ṣẹ tun ti gberi pada. Lẹyin ikọlu yii, eeyan to le lọgọrun-un (100) ni wọn ba ogun Boko Haram naa lọ.

Ohun ti ikọ Boko Haram da le lori ni pe pe ẹsin Islam ko faaye gba Musulumi lati kopa ninu oṣelu, igbagbọ wọn ni pe eewọ ni ninu Islam lati lọwọ si ohun aye kankan.

Boko Haram gbagbọ pe awọn keferi alaigbagbọ lo n darii Naijiria, ko baa jẹ pe Musulumi ni aarẹ to wa lori ipo. Iwadii ti BBC ti ṣe ṣaaju fidi eyi mulẹ.

Ero awọn eeyan tẹlẹ ni pe ologun Naijiria pẹlu ajọṣepọ awọn orilẹede alamuleti, ti ṣẹgun Boko Haram, ṣugbọn ni bayii, ikọlu naa n waye leralera lati nnkan bii ọdun mẹta sẹyin.

Ni 2022, ikọlu marunlelọgọrun-un (105) lo ti ọwọọ Boko Haram wa, o di 147 ni 2023, 191 ni 2024, gẹgẹ bi BBC ṣe ko o jọ lati SBM intelligence, ileeṣẹ kan to n ri si ọrọ aabo l'Africa.

Ninu ọdun 2025 yii, ikọlu Boko Haram akọkọ waye lọjọ kẹrin, oṣu Kin-in-ni, nigba ti wọn dena de awọn ṣọja Naijiria ni abule Sabon Gari , ti wọn si pa mẹfa ninu wọn.

Ọjọ mẹsan-an lẹyin eyi, iyẹn ọjọ kẹtala oṣu Kin-in-ni, Boko Haram tun ṣọṣẹ ni abule Dumba, nitosi Baga, wọn pa ogoji agbẹ ati awọn apẹja.

Awọn ikọlu mi-in tun waye loṣooṣu lẹyin eyi ninu ọdun yii, o si n ko ipaya ba araalu leralera, o n fi han pe wahala wa pẹlu bi wọn ṣe n da oju sọ awọn abule kereje kiri ati igboro ilu pẹlu.

Ǹ jẹ́ àpẹẹrẹ pé wọ́n tún ti ń gbérí ti ń fojú hàn?

Ọkan lara awọn ile ti Boko Haram kọlu ree, o ti jona raurau. Ẹnikan duro lẹnu ọna rẹ, o di ogiri mu o si n wo orere.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọkan lara awọn ile ti Boko Haram kọlu ree, o ti jona raurau. Ẹnikan duro lẹnu ọna rẹ, o di ogiri mu.
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin 2025, Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Umara Zulum, figbe ta pe awọn Boko Haram ti n peleke si i ninu ikọlu ati ijinigbe. O ni ikọ naa ti n pete ati padabọ, ibudo awọn ologun lo ni wọn n dọdẹ rẹ, wọn si n pa awọn araalu.

"Bi wọn ṣe n pa awọn araalu ti ko ṣẹ wọn lẹṣẹ kan ati awọn ologun ti n peleke si i, eyi si jẹ ifasẹyin fun ipinlẹ Borno ati apa Ariwa-Ila Oorun orilẹede yii lapapọ." Gomina Zulum lo sọ bẹẹ.

Pẹlu awọn ikọlu to n ṣẹlẹ kaakiri Borno ati ipinlẹ Yobe, itumọ rẹ ni pe wọn ko ti i ṣẹgun Boko Haram bi wọn ṣe ro tẹlẹ.

"Kekere kọ ni rogbodiyan ti a koju, itumọ to ni ni pe ireti wa ti n ja sofo bayii, agbara aforiti wa si ti pin. Gbogbo eeyan lẹru n ba, ọkan o balẹ, awọn eeyan n gbiyanju ki awọn iṣẹlẹ yii ma ya wọn ni were ni."

Aliyu Harande, olugbe Mafa lo ṣalaye bẹẹ fun BBC lẹyin ikọlu ọdun to kọja.

"Fun awa ti a ti ro pe wọn ti sinmi ninu iṣẹ laabi wọn, awọn ohun to n ṣẹlẹ yii ti jẹ ko ye wa pe wọn lọọ mura ogun si i ni."

Ninu alaye Zanna Umara, oṣiṣẹ kan nileeṣẹ ijọba ibilẹTarmuwa , o sọ fun BBC pe: " A ko gbadura fun ipadabọ wọn, ṣugbọn bi a ba wo bi ikọlu Mafa ṣe lagbara to, o jọ pe wọn ti n dira ogun lati pada wa loootọ."

Diẹ lara awọn obinrin ti idaamu awọn Boko Haram ti sọ di alainile lori.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Aworan awọn obinrin ti ko nile lori mọ, ibudo aabo ti ogun Boko Haram le wọn de ni wọn rọra duro si.

Ohun tó ń fa ìkọlù lemọ́lemọ́

Gẹgẹ bi alaye Dokita. Kabir Adamu, Adari Beacon Security and Intelligence Limited, o ni akọkọ ni pe wọn ti paṣẹ fun wọn lati fi kun bi wọn ṣe n kọlu awọn eeyan.

Dokita Adamu sọ pe o jọ pe wọn ti n tẹle aṣẹ yii, nitori ọpọ awọn ikọ alakatakiti naa ni wọn ti n dahun si ipe ipaniyan naa, ti wọn n ṣoro ju ti tẹlẹ lọ.

Nnkan keji to fa ikọlu leralera yii bi Dokita Adamu ṣe tọka ni ti oju ọjọ ti wọn maa n wo ṣiṣẹ. "To ba ti n ku diẹ ki asiko ojo de, awọn ikọ yii maa n mulele si i nipa iṣẹ laaabi wọn, wọn ti mọ pe awọn ṣọja yoo fẹẹ sinmi lasiko naa, nitori o maa n ṣoro fun wọn lati riran ri gbogbo agbegbe naa."

Ikẹta bo ṣe sọ ni rogbodiyan to n ṣẹlẹ lawọn aṣalẹ bii Chad, Niger, ati Burkina Faso. Adamu sọ pe o ti jẹ ki aabo sọnu lẹnu ibode awọn orilẹede yii. Eyi n jẹ kawọn alakatakiti yii rọna wọle, wọn n gba ọmọ ogun tuntun, wọn si n ri iranlọwọ ti wọn nilo gba.

Ayipada abẹle to n waye ninu iṣẹ ologun Naijiria naa tun jẹ idi kan gẹgẹ bo ṣe sọ, paapaa bi wọn ṣe n ko awọn nnkan ija ati awọn ologun lati Ariwa-Ila-Oorun(North-East) lọ si Ariwa-Iwọ-Oorun (North-West).

Ṣugbọn ijọba Naijiria tako eyi, o ni ipadabọ Boko Haram ko ṣẹyin ikọlu lemọlemọ to n waye ni awọn orilẹede alamuleti Naijiria.

"Ikọlu to n lera wọn yii ki i ṣe ti ibi kan ṣoṣo, awọn ohun to n ṣẹlẹ lawọn orilẹede to mule tiwa naa lagbara, awọn agbesunmọmi ti fi kun ọwọja iṣẹ wọn kaakiri, iya rẹ lawa naa n ba fa a bayii ni Naijiria.

" Mohammed Badaru Abubakar,Minisita ọrọ aabo lorilẹede Naijiria lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ United Nations Development Program (UNDP), o ti le ni eeyan ẹgbẹrun marundinlogoji ( 35,000) ti Boko Haram ti pa latari ikọlu, laaarin 2009 si 2024. Meje ninu awọn ikọlu yii ni 2024 nikan, pa eeyan to le ni igba (200), o si kere tan, ọọdunrun eeyan (300) farapa, eyi to pọ ju ti bo ṣe maa n ri tẹlẹ lọ.

Aworan awọn ologun ninu ọkọ nigboro Borno.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi UNDP ṣe wi , apa Ariwa-Ila-Oorun ni awọn ikọlu yii ti n waye ju, paapaa julọ, ipinlẹ Borno, nibi ti Boko Haram ati ikeji rẹ, ISWAP, ti n dọdẹ araalu ati awọn ologun.

Bi Naijiria ṣe n koju ọwọngogo ati igbeaye lile, bẹẹ ni awọn agbesunmọmi ko tun fi wọn lọkan balẹ. O si jọ pe wọn n dan awọn eeyan wo bi wọn ṣe lagbara si lati koju awọn nnkan wọnyi ni.

"Ewo ni ka kọkọ gbọ ninu ẹ, igbesi aye to le koko ni tabi tabi ipayinkeke awọn agbebọn?" Harande lo beere bẹẹ.

Gẹgẹ bii ara abule, awọn naa ni ikọlu yii n ba ju. Wọn yoo daro ara wọn bi iku ba ti ọwọ Boko Haram pa eeyan wọn, wọn yoo tun tẹsiwaju ninu irinajo aye, pẹlu ifoya pe ikọlu tun le ṣẹyọ nigbakigba ati nibikibi.

Aworan abule kan ti Boko Haram ti kọlu ri ni Borno, ipaya han lara wọn, kaluku n sa kiri.
Àkọlé àwòrán, Aworan abule kan ti Boko Haram ti kọlu ri ni Borno, ipaya han lara wọn, kaluku n sa kiri.

''Ẹrù ń bà wá, a kò mọ̀ bóyá a ti lè padà sílé''

"Ẹru n ba awọn ọmọ mi, ko si da wa loju pe a ti le pada silee wa bayii, a ko mọ boya aabo ti wa nibẹ. Awọn ologun wa nibi, ṣugbọn mi o ri aabo kankan"

Obinrin kan, Hajara Idris (ki i ṣe orukọ rẹ gan-an), lo ṣalaye bẹẹ fun BBC lẹyin ikọlu Mafa.

Oun nikan kọ ni ẹru n ba. Fatima Bukar (ki i ṣe orukọ tiẹ naa) naa ṣalaye tiẹ. O ni ikọlu naa ti daamu ọkan oun gan-an. ''A ti koju ohun ti a ko lero pe yoo ṣẹlẹ si wa laye, o si dabii pe ko sibi ti aabo wa mọ fun wa. Koda pẹlu bawọn ṣọja ṣe wa nibi to, gbogbo alẹ lẹru maa n ba mi pe Boko Haram yoo tun pada wa."