Ẹ wo ààfin ìlù níbi tí wọ́n ti n bọ ilù gúdúgúdú tí obìnrin tó bá n ṣe nnkan oṣù kò gbọdọ̀ fọwọ́ kàn
Awọn ọba alade nilẹ Yoruba la mọ to n gbe laafin, amọ ara ọtọ ni nigba ti a de aafin kan niluu Ede, nipinlẹ Osun, nibi to jẹ pe ilu lo n gbe nibẹ, ti wọn si tun ni ọba.
Ohun iyalẹnu yii lo gbe ikọ iroyin BBC Yoruba de aafin ọhun nibi ti a ti fi ọrọ wa ọba aafin naa, Ọmọba Adewale Laoye, sọrọ.
Ọba Aafin ilu to jẹ ọmọbibi Ọba John Adetoyese Laoye, Timi ilu Ede nigba kan, sọ pe aafin naa ni awọn ti n fi ilu gbe aṣa Yoruba larugẹ.
O ni ile ni oun ba aṣa ilu lilu, paapaa bi baba rẹ ṣe jẹ gbajugbaja oniluu to lu ilu ti ileeṣẹ redio ijọba Naijiria, Radio Nigeria, fi ma n polowo ileeṣẹ naa titi di oni.

Ọmọọba Laoye sọ pe nigba ti oun ṣakiyesi pe awọn ilu kan ti n parun lo mu ki oun kọ aafin naa lati daabo bo wọn.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo naa lo tun ti sọ awọn eewọ kan to rọ mọ ilu. Lara awọn ilu to mẹnuba ni ilu gudugudu. O ni awọn ma n bọ ilu gudududu, ti obinrin to ba n ṣe nnkan oṣu ko si gbọdọ fi ọwọ kan an.
Lara awọn eewọ to tun mẹnuba ni pe wọn ko gbọdọ gbe ilu yoowu si ilẹẹlẹ lasan.





