Wo bí òkú ṣe báwọn tó pa á sọ̀rọ̀ lásìkò ìgbẹ́jọ́ ikú rẹ̀ pẹ̀lú AI
- Author, Ana Faguy
- Role, BBC News
- Author, Lily Jamali
- Role, North America Technology Correspondent
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Chris Pelkey padanu ẹmi rẹ lasiko ti ija kan bẹ silẹ ni bii ọdun mẹta sẹyin ni Arizona, lorilẹede Amẹrika.
Ṣugbọn pẹlu iranlọwọ ti aapu atọwọda AI, o pada ninu oṣu yii fun idajọ awọn to ṣe ku pa a lati tan tan imọlẹ si ohun to ṣẹlẹ gan an.
Awọn ẹbi oloogbe sọ pe awọn lo imọ-ẹrọ lati jẹ ki Ọgbẹni Pelkey lo ọrọ ẹnu ara rẹ lati fi sọrọ nipa iṣẹlẹ naa to gba ẹmi rẹ.
Bi awọn kan ti gbe orinyin fun AI pe yoo wulo fun ọjọ iwaju ni awọn kan ni ko dara to paapa fun eto igbẹjọ.
Arabinrin Stacey Wales ti sọ fun BBC wi pe ẹbi lo gba ohun, fidio ati aworan Ọgbẹni Pelkey silẹ, ẹni ọdun mẹtadinlogoji nigba to jade laye, lati ṣe fidio kan ti wọn fi AI peelo rẹ.
Arabinrin Wales ni oun loun kọ awọn ọrọ ti oloogbe naa ka ni lasiko igbẹjọ lati ṣafihan bi oloogbe naa ṣe ni ẹmi iforinjin.
"Fun Gabriel Horcasitas, ọkunrin to yin ibọn lu mi, ohun ibanujẹ lo jẹ pe a pade ara wa lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye," AI ti wọn ṣe fun Pelkey lo sọ bẹẹ nile ẹjọ.
"Mo gbagbọ ninu ṣiṣe aforinjin ati Ọlọrun to n forinjin. Mo si gbagbọ ninu ṣiṣe aforinjin.
Inu adajọ Arizona to dari igbẹjọ naa, Todd Lang, dun si lilo AI fun igbẹjọ ọhun.
Adajọ naa wa ju Horcasitas si ẹwọn ọdun mẹwaa fun ẹsun iṣekupani.
"Mo fẹran AI ti wọn lo, mo gbọ bi ẹbi oloogbe ṣe sọ nipa aforinjin, mo si mọ pe lati ọkan awọn mọlẹbi ni o ti wa.
Paul Grimm, adajọ fẹyinti to tun Ọjọgbọn ninu iṣẹ amofin, sọ fun BBC pe ko jọ oun loju pe awọn olupẹjọ lo AI fun igbẹjọ Horcasitas.
















