Ta a ni eku ẹdá tó tún dá wàhálà sílẹ̀ lẹ́yìn tí India àti Pakistan gbà láti sinmi ogun?

Oríṣun àwòrán, EPA
Orilẹede India ati Pakistan ti bẹrẹ si i naka ẹbi sira wọn lori adehun jẹ-ki-ogun-sinmi ti wọn jọ ṣe ṣugbọn ti ogun ko duro lẹnu ibode wọn.
Bi ibugbamu ṣe dun ni Kashmir; India, ni Akọwe ilẹ okeere ibẹ, Vikram Misri, ti sọ pe Pakistan ni ko sinmi ikọlu, wọn ko si tẹle adehun tawọn jọ ṣe.
Ko pẹ sigba naa ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni Pakistan naa sọrọ pe, awọn ṣetan lati tẹle adehun, bo ti wu kawọn kan maa kọlu awọn to.
Ija to lagbara ju ti atẹyin wa lọ lo ti n waye laaarin India ati Pakistan lati bii ọjọ mẹrin sẹyin.
Ikọ ologun awọn orilẹede mejeeji si n fori gbari bayii ninu ija to ti le logun ọdun ti wọn bẹrẹ rẹ.
Ohun ti a mọ si drone, ado oloro ati awọn ọkọ ti ọta ibọn kun inu rẹ ti wọn si fidi ẹ kalẹ ni India fi bẹrẹ ikọlu si Pakistan loṣu to kọja.
Pakistan pẹlu da a pada latari ikọlu Pahalgam, bo tilẹ jẹ pe wọn ni ko sọwọ awọn nibẹ.
Lẹyin ọjọ mẹrin ti awọn orilẹede mejeeji ti n kọlu ara wọn , India ati Pakistan ni awọn ti gba lati ṣiwọ ogun lẹsẹkẹsẹ.
Aarẹ ilẹ America, Donald Trump, paapaa kede rẹ pe oun ti pari ija laaarin awọn ilu mejeeji naa.
Bakan naan ni Minisita ilẹ okeere fun Pakistan fidi rẹ mulẹ.
Ṣugbọn wakati diẹ lẹyin ikede, awọn akọroyin BBC pẹlu awọn araalu Kashmiri; Srinagar ati Jammu bẹrẹ si i gbọ ibugbamu, bẹẹ ni mọnamọna ado oloro bẹrẹ si i kọ loju ọrun.
Ìkọlù tó pa arìnrìnàjò afẹ́ 26 ló fa wàhálà
Iroyin sọ pe ija to n ṣẹlẹ yii ko ṣẹyin iku awọn arinrianjo afẹ mẹrindinlọgbọn ti wọn pa ni Pahalgam lọsẹ meji sẹyin.
Lọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin 2025 ni ọmọ orilẹeede India mẹẹẹdọgbọn ku, pẹlu ọmọ Nepal kan.
Ninu ọrọ wọn, ileeṣẹ ologun India ṣalaye pe oun ṣe ikọlu lati le fi oju awọn ẹni ibi han ni.
Pakistan ni tiẹ sọ pe eeyan mẹrindinlogoji (36) ni India ti fi ado oloro pa ni Pakistan lati Ọjọruu.
Awọn ologun India naa si sọ pe eeyan mọkanlelogun ni ado oloro Pakistan pa lọdọ awọn.
Ọjọ Ẹti ni ija ajakuakata naa tun peleke si i, pẹlu bi awọn orilẹ ede mejeeji ṣe n fẹsun kan ara wọn pe ikini n dọdẹ ibudo ologun ati tawọn ọmọ ogun ofurufu ikeji.
Ṣaa, ọrọ ti Olootu ijọba Pakistan; Shehbaz Sharif, sọ ṣaaju ni pe bawọn ba sinmi ogun, fun anfaani gbogbo eeyan ni.














