Akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ iṣẹ́ ọnà jẹ́wọ́ ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí lẹ́yìn tó tajà fún 'agbódegbà Hezbollah'

Oríṣun àwòrán, Jordan Peck / Getty Images
Arakunrin onimọ nipa iṣẹ ọna kan to ti fi igbakan ri ba BBC ṣeto idunadura iṣẹ ọna ti jẹwọ pe lootọ loun kuna lati fi ọkan-o-jọkan iṣẹ ọna olowo iyebiye ti wọn ta fun eeyan kan ti wọn fura si pe o n ṣe agbodegba fun awọn agbesunmọmi Hezbollah.
Arakunrin Oghenochuko Ojiri, ẹni ọdun mẹtalelaadọta jẹwọ pe oun jẹbi ẹsun mẹjọ ti wọn fi kan an labẹ ofin to gbogun ti iwa igbesunmọmi, ti ọdun 2000 fun kikuna lati sọ fawọn agbofinro lasiko ti idunadura naa n lọ.
Akọkọ irufẹ igbẹjọ ati idajọ niyii.
Wọn fi to ile ẹjọ naa leti lọjọ Ẹti pe Ojiri ta iṣẹ ọna ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna ogoje pọun, (£140,000) fun Nazeem Ahmad, ẹni ti wọn n fi ẹsun kan pe o n ṣe agbatẹru ẹgbẹ agbesunmọmi naa to fi ikalẹ si orilẹede Lebanon.
Orilẹede Amẹrika gbẹsẹ le ẹgbẹ naa lọdun 2019.
Amofin olupẹjọ, Lyndo Harris ṣalaye pe pe Ojiri ti ka iroyin to sọ nipa Ahmad gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa, sibẹ o ṣi tun sọ fun awọn eeyan nipa rẹ.
Laarin oṣu kẹwaa ọdun 2020 ati oṣu kejila ọdun ni iṣẹlẹ naa waye.
Ojiri da ileeṣẹ ipatẹ iṣẹ ọna Ramp Gallery ti orukọ rẹ ti yi pada di Ojiri Galery silẹ lagbegbe East London.
Ogbẹni Harris sọ pe: "ijiroro kan waye laarin Ojiri at'awọn eeyan kan ninu eyi to ti han gbangba pe o ti pẹ ti ọpọ ti mọ nipa asopọ Ahmad ati igbesunmọmi."
O ni ileeṣẹ ipatẹ "Ramp Gallery lo alagata lati gba amọran lori bi idundura naa ṣe le lọ si" ṣugbọn wọn "ko tẹle amọran yii".
Ileẹjọ Majisreeti Westminster to gbọ ẹjọ naa ni Ọgbẹni Ojiri funra rẹ lo dunadura pẹlu Ahmad to si tun kii ku oriire rira ọja naa.
Olupẹjọ ni lasiko ti idundura naa waye, iroyin to pọ wa lori ayelujara lati fihan pe Ahmad n lọwọ ninu owo aibofin mu naa eyi ti wọn n lo lati fi ṣe agbatẹru fun iwa igbesunmọmi.
Bakan naa ni ijọba ilẹ Gẹẹsi pẹlu ti gbẹsẹ le awọn dukia rẹ loṣu kẹrin ọdun 2023, to si tun paṣẹ pe ọmọ ilẹ Gẹẹsi kankan ko gbọdọ ba a dowo pọ.
Ẹgbẹ ẹsin Musulumi Shia ti kede rẹ gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesunmọmi lawọn orilẹede kan, eyi ti Amẹrika ati ilẹ Gẹẹsi wa.
Ojiri, ti awọn eeyan tun mọ si Ochuko Ojiri di ero ileẹjọ lẹyin iwadii ileeṣẹ ọlọpaa, ati ẹka to n ṣe iwadii ọrọ aje, OFSI ati HMRC.
Labẹ ofin, ẹṣẹ lo jẹ bi eeyan ko ba fi to ijọba leti bi wọn ba mọ tabi kẹfin pe onibara wọn n ṣe agbodegba fun ẹgbẹkẹgbẹ ti wọn ti gbẹsẹ le.
Ojiri sọ fun ileẹjọ pe oun ko ṣe agbatẹru igbesunmọmi, to si tọrọ aforijin fun ohun to ṣe
O ni oun mọ iru eeyan ti Ahmad jẹ, ati pe kii ṣe owo ati ojukokoro lo sun oun de ọdọ rẹ.
Ojiri wa lara awọn ti wọn pe gẹgẹ bi ọkan lara awọn akọṣẹmọṣẹ lori eto kan ti wọn gbe kalẹ ti wọn pe orukọ rẹ ni Bargain Hunts.
Kii ṣe oṣiṣẹ BBC rara.
O ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi alejo atọkun, bẹẹ lo ti fi ara han lori awọn eto kan ati Channel 5 storage ti wọn pe ni Flog the I.
Ko si tii ṣe iṣẹ kankan fun BBC lati ọdun 2023.
Agbẹnusọ fun BBC, salaye pe, "Ko ni tọ lati sọrọ lori ẹjọ to wa nileẹjọ."
Adajọ agbegbe naa, Briony Clarke gba oniduro Ojiri, o ni ko jọwọ iwe irinna rẹ silẹ okeere fun ile ẹjọ.
Gavin Irwin, agbẹjọro rẹ sọ fun ileẹjọ pe Ojiri ko le sa mọ ofin lọwọ.
Ọjọ kẹfa oṣu kẹfa ni yoo gba idajọ rẹ nile ẹjọ Old Bailey.















