Mọ̀ nípa Joan, obìnrin tó ṣe bí ọkùnrin tó fi di Póòpù ìjọ Àgùdà

Àkọlé fídíò, Pope Joan: the legend of the only woman pontiff
Mọ̀ nípa Joan, obìnrin tó ṣe bí ọkùnrin tó fi di Póòpù ìjọ Àgùdà

Gẹ́gẹ́ bí òfin àti ìlànà ìjọ Àgùdà, ọkùnrin nìkan ló lè di póòpù nítorí àlùfáà ìjọ nìkan ló lè di póòpù, tí obìnrin kò sì le jẹ àlàfáà.

Àmọ́ ìròyìn obìnrin kan wà tí ìgbàgbọ́ wà pé ó ṣe póopù ìjọ Àgùdà láyé ijọ́hun, tó sì bímọ lásìkò tí ìsìn ń lọ lọ́wọ́.

Póòpù Joan ni ìgbàgbọ́ wà pé ó ṣe Póòpù fún ọdún bíi méjì.

Ìtàn yìí gbajúmọ̀ àmọ́ tó tún fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye lásìkò tó ṣẹlẹ̀ náà.

Joan pa orúkọ dà di John, ó darí ìjọ Àgùdà pẹ̀lú orúkọ Póòpù John VIII, Johanes Anglicus, kí àwọn èèyàn tó padà mọ̀ pé John tó ń jẹ́ kìí ṣe John ọkùnrin bíkòṣe Joan

Gẹ́gẹ́ bí ìtàn, ní sẹ́ńtúrì Kẹsàn-án ni Joan ṣe bí ẹni pé ọkùnrin ní òun.

Ó lọ sí ìlé ẹ̀kọ́ gíga, ó yege lẹ́nu ẹ̀kọ́ èyí tó mu gbajúmọ̀ fún ìmọ̀ tó ní.

Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ ló ń di ipò gíga mú nínú ìjọ Àgùdà, kó tó di pé wọ́n dìbò yàn-án láti di Póòpù.

Póòpù náà darí ìjọ Àgùdà pẹ̀lú orúkọ Póòpù John VIII, Johanes Anglicus, kí àwọn èèyàn tó padà mọ̀ pé John tó ń jẹ́, kìí ṣe John ọkùnrin bíkòṣe Joan.

Gẹ́gẹ́ bí ìṣe àti ìlànà ìjọ Àgùdà, ẹni tó bá jẹ́ Póòpù kìí ní ìbálòpọ̀ àmọ́ ohun tó tú àṣìrí Póòpù Joan kò ṣẹ̀yìn bí ó ṣe bí ọmọ lásìkò tó ń ṣáájú ìjọsìn lọ́wọ́.

Ẹ̀rí wà pé àwọn Póòpù tó jẹ́ ọkùnrin náà máa ń yẹ àdéhùn wọn láti má bà á obìnrin ní àjọṣepọ̀ bíi Pope Jacob tí ìgbàgbọ́ wà pé ó ní ọmọ mẹ́rin.

Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí obìnrin, Joan kò yẹ kó di óòpù rárá.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Katherine Lewis, onímọ̀ nípa ìtàn ayé àtijọ́ sọ pé kò sí bí ìmọ̀ Joan ṣe lè pọ̀ tó, kò sí bó ṣe lè mọ ara a mú bí ọkùnrin tó, bá gbogbo nǹkan tó ṣe náà jẹ́ pẹ̀lú ìbálòpọ̀ tó ní níkẹyìn, tó sì lóyún.

Àwòrán Joan

Ṣé òótọ́ ni ìtàn pé Joan jẹ Póòpù ?

Tí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn onítàn kan kò gbàgbọ́ pé ìtàn Póòpù Joan kìí ṣe òótọ́, wọ́n máa ń sọ ìtàn rẹ̀ bíi àlọ́, ìwáásù fáwọn èèyàn láti fi kẹ́kọ̀ọ́.

Bákan náà ló sọ nípa ìhà tí àwọn èèyàn ayé ìgbaǹnì kọ sí àwọn obìnrin.

Àwọn àpẹẹrẹ tí a lè mú jáde ni láti sẹ́ńtúrì kẹtàlá nígbà táwọn póòpù bíi méjì sí mẹ́ta ń jà fún ìdí tí kò ṣe yẹ kó jẹ́ pé èèyàn kan péré ló ń darí ìjọ, wọ́n lo ìtàn Joan gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n tọ́ka sí.

Bẹ́ẹ̀ náà láwọn Protestant lo ìtàn Joan láti fi bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọ Àgùdà lásìkò àtúntò tí wọn ń pè ní Reformation.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Katherine Lewis ní ìtàn Joan ṣe pàtàkì nítorí ó di èèyàn pàtàkì sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹgbẹ́ àti aládàni fún ọ̀pọ̀ sẹ́ńtúrì.

"Ó jẹ́ èèyàn tó ṣe ohun ìyàlẹ́nu nípa àṣà, mo rò pé a lè fi wé àwọn èèyàn bíi Robinhood àti ọba Arthur, òun ni a lè pè ní obìnrin tó bá wọn.

"Ìtàn nípa rẹ̀ jẹ́ ohun tí wọ́n máa ń sọ ní àsọtúnsọ."

Ní sẹ́ńtúrì ogun àti ìkọkànlélógún, ìtàn nípa Joan ṣì ń jẹyọ nínú àwọn eré sinimá, ìwé kíkọ àti àwọn àríyàjiyàn lórí ẹni tí ó le dì àlùfáà ìjọ.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé olóògbé Pope Francis ṣe àwọn àyípadà láti ri pé àwọn obìnrin tún ń dé ipò gíga ju ti àtẹ̀yìnwá lọ nínú ìjọ Àgùdà, amọ wọn kò tíì lè di àlùfáà ìjọ.

Díde ìpo póòpù fáwọn obìnrin sì jẹ́ ìtàn ayé ìgbannì.