Ariwo sọ bí ọ̀dọ́bìnrin kan ṣe parọ́ pé wọ́n jí òun gbé lásìkò tó wà pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀, ọlọ́pàà sọ̀rọ̀

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti fi ṣikun ofin mu ọdọbinrin kan, Helen Kayode, ẹni ọdun mẹrinlelogun.
Ẹsun ti ọlọpaa fi kan Helen ni pe o pa irọ pe awọn agbebọn kan ji oun gbe, ti wọn si gbe oun lọ sinu ile kan loju ọna Iworoko/Ado-Ekiti, niluu Ado Ekiti.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.
"Ọmọbinrin naa jẹwọ pe ọrẹkunrin oun ti ṣeleri ẹbun ọjọ ibi fun oun amọ awọn obi rẹ n fẹ ko de siluu Eko lasiko ọjọ ibi rẹ"
Abutu sọ pe ọdọbinrin ọhun fi atẹjiṣẹ ṣọwọ si ibatan rẹ obinrin lọjọ kinni, oṣu Karun un, ọdun 2025 pe oun ṣi ọkọ wọ laarin Iworoko ati Ado, ti wọn si ti ji oun gbe lọ.
Ọlọpaa ni afurasi naa sọ pe inu ile kan ti igbo pọ yika ibẹ ni awọn ajinigbe naa fi oun pamọ si.
Abutu ṣalaye pe, iroyin naa da ipaya si ọkan awọn eeyan lagbegbe Iworoko, lẹyin ti iroyin ọhun gba ori ayelujara kan.
O ni "Ninu iwadii wa, ni a ti ṣawari pe ko si ẹni to ji ọdọbinrin naa gbe, iroyin ofege lo fi sita lasiko to wa pẹlu ọrẹkunrin rẹ lorumọju ọjọ naa.
Lẹyin naa lo tẹ ọkọ leti lọ siluu Eko lọdọ awọn obi rẹ lọjọ keji.
"Afurasi naa jẹwọ lasiko iwadii pe oun ni oun mọọmọ fi atẹjiṣẹ ofege ṣọwọ si awọn mọlẹbi oun.
O ni oun gbe igbesẹ naa lọna ati le duro siluu Ado Ekiti lati sajọyọ ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ pẹlu ọrẹkunrin rẹ.
O ni ọrẹkunrin oun naa ti ṣeleri lati fun oun ni ẹbun agbayanu eyi to tako ifẹ inu awọn obi rẹ to n fẹ ko de siluu Eko lọjọ karun un, oṣu Karun un."
Abutu sọ pe kọmiṣona ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Joseph Eribo, koro oju si iwa ti ọdọbinrin ọhun wu.
Lẹyin naa lo kilọ pe ẹnikẹni to ba n pin iroyin ẹlẹjẹ kiri eyi to le da ipaya silẹ laarin ilu, yoo foju wina ofin.















