Ètò yíyan Póòpù tuntun ń tẹ̀síwájú bí èéfí dúdú ṣe jáde láti Sistine Chapel

Oríṣun àwòrán, Reuters/Vatican Media
Ìgbésẹ̀ láti yan Póòpù tuntun ń tẹ̀síwájú lónìí báwọn cardinal tí wọ́n ń dìbò ní Vatican kò ṣe yọrí sórí ẹnìkan lọ́jọ́rú tí ètò náà bẹ̀rẹ̀.
Èéfí dúdú ló jáde lálẹ́ àná ní Sinistine Chapel tí ètò ìdìbò náà ti ń wáyé, tí èyí sì túmọ̀ sí pé àwọn cardinal náà kò ì fẹnukò lórí ẹni tó máa di póòpù tuntun.
Báwo ni ìgbésẹ̀ náà ṣe máa lọ lónìí?
Aago mẹ́fà ààbọ̀ òwúrọ̀ ni àwọn cardinal máa jẹun òwúrọ̀ kí wọ́n tó lọ ṣètò ìsìn ráńpẹ́.
Ẹ̀ẹmẹ̀rin ni wọ́n pín ètò ìdìbò sí lónìí – méjì láàárọ̀ àti méjì ní ìrọ̀lẹ́.
Aago mẹ́wàá àbọ̀ ni ètò ìdìbò àkọ́kọ́ máa wáyé nígbà tí ìkejì máa bẹ̀rẹ̀ ní aago méjìlá ọ̀sán.
Lẹ́yìn náà láwọn cardinal máa lọ jẹun ọ̀sán kí wọ́n tó tún bẹ̀rẹ̀ ètò ìdìbò míì ní aago márùn-ún àbọ̀ àti aago méje ìrọ̀lẹ́.
Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti dìbò àárọ̀ tán ni èéfí máa tún jáde láti ṣàfihàn ohun tí ìbò wọn yọrí sí. Tí èéfí funfun bá jáde lẹ́yìn ìbò àárọ̀, ó túmọ̀ sí pé wọ́n ti yan póòpù tuntun àmọ́ tó bá jẹ́ dúdú, ìbò dídì máa tẹ̀síwájú ní ìrọ̀lẹ́.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn èrò ló tò sí St Peter's Square láti mọ àbáyọrí ètò ìbò lánàá, àmọ́ tó lé ní wákàtí mẹ́ta kí èsì ìbò tó jáde.
Púpọ̀ nínú àwọn cardinal tó ń kópa níbi ètò ìdìbò náà ni ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọgọ́ta sí àádọ́rin ọdún, tó sì jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí ọ̀pọ̀ wọn ń kópa níbi ètò yíyan póòpù.
Lára àwọn èèyàn tó lọ wó bí ètò náà ṣe ń lọ sọ pé ó dùn mọ́ wọn pé ètò náà ń lọ lẹ́sẹlẹ́sẹ àti pé àwọn cardinal náà kò kánjú láti yan ẹnìkan.
Kleineck láti Texas sọ pé kò kọ ohun lóminú pé èéfí dúdú ló jáde lánàá nítorí òhun ní ìgbàgbọ́ pé ètò ìbò máa tẹ̀síwájú lónìí.
Barbara Mason tó lọ sí Conclave láti Canada láti lọ wo ètò náà ní òun ní ìrètí pé ẹni táwọn cardinal náà máa yàn máa tẹ̀síwájú àwọn iṣẹ́ rere tí Póòpù Francis ṣe sílẹ̀.
Bí ètò yíyan Póòpù tuntun ṣe bẹ̀rẹ̀, wo àwọn ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí yóò wáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn Cardinal káàkiri àgbáyé ti balẹ̀ sí Róòmù láti yan Póòpù tuntun lẹ́yìn ìpapòdà Pope Francis lọ́jọ́ Ajé.
A ò lè sọ pé ìgbà báyìí ni ètò náà máa fi wáyé àmọ́ yíyan Póòpù tuntun kìí pẹ́ púpọ̀ tí a bá wo bí wọ́n ṣe ti yan àwọn Póòpù sẹ́yìn.
Láyé ìjọhun ni àìyedè láàárín àwọn cardinal ló máa ń fa kí yíyan Póòpù tuntun pẹ́ fún ìgbà oṣù àmọ́ àyípadà tib á èyí jọjọ.
Àwọn Cardinal tó máa yan póòpù tuntun yóò kọ́kọ́ ṣe ìsìn ní St Peter's Basilica ní òwúrọ̀ ọjọ́rú kí wọ́n tó rìn lọ sí Sistine Chapel láti lọ dìbò fún ẹni tó máa di póòpù tuntun.
Ní kété tí wọ́n bá ti wọ inú Sistine Chapel, wọn ò ní bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ mọ́ níta títí tí wọ́n fi máa kéde yínyan póòpù tuntun.
Kí ni èéfín Pupa àti funfun túmọ̀ sí nínú ìgbésẹ̀ yíyan Pope tuntun?
Àwọn èèyàn máa nílò láti dúró máa ṣe irú èéfí tó máa jáde láti inú ilé ìjọ tí wọ́n wà láti fi mọ́ ìpinnu àwọn cardinal náà.
Tó bá jẹ́ pé èéfí dúdú ló jáde, ó túmọ̀ sí pé wọ́n ṣì máa tún ìbò dì, wọn ò tíì dìbò yan ẹnìkan àti pé ètò ìdìbò míì máa wáyé lọ́jọ́ kejì àmọ́ tí èéfín bá jẹ́ funfun ló jáde láti ibẹ̀, ó túmọ̀ sí pé wọ́n ti yan póòpù tuntun nìyẹn.
Póòpù tí wọ́n bá yàn yìí ni yóò jẹ́ Póòpù 267th tó máa jẹ láti ìgbà tí ìjọ Àgùdà ti ń yan póòpù.
Ní àkókó 30AD ni wọ́n yan St Peter, ẹni tí wọ́n gbà gẹ́gẹ́ bí póòpù àkọ́kọ́.
Báwo ni ètò yíyan póòpù yóò ṣe lọ?
Ni aago méje òwúrọ̀ ni àwọn cardinal ni yóò máa dé sí Sanctae Marthae, ilé ìgbàlejò tó wà ní Vatican. Àwọn míì ti máa wà níbẹ̀ láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun.
Aago mẹ́wàá òwúrọ̀ ni wọ́n máa kóra wọn sí St Basilica fún ìsìn
Tí aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ bá ti lù ni àwọn cardinal máa gbéra láti Pauline Chapel lọ sí Sistine Chapel.
Aago márùn-ún àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ni gbogbo àwọn èèyàn yàtọ̀ sí àwọn cardinal máa kúrò ní Sistine Chapel nígbà tí wọ́n bá kéde "extra omnes".
Ní nǹkan bí aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ ni ìrètí wà pé èéfí máa jáde lẹ́yìn tí wọ́n bá ti dìbò àkọ́kọ́ tán.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣé ó ṣeéṣe kí wọ́n kéde Póòpù tuntun lónìí?
Ó ṣeéṣe kí wọ́n kéde Póòpù tuntun lónìí tí àwọn cardinal bá dìbò yan ẹnìkan àmọ́ tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ìbò míì máa wáyé lọ́la, Ọjọ́bọ̀.
Kò sí òfin tó ní wọn kò lè yan Póòpù tuntun lẹ́yìn ìbò àkọ́kọ́ ṣùgbọ́n ó ti pẹ́ ti irú rẹ̀ ti wáyé.
Ìbò àkọ́kọ́ ṣe pàtàkì nítorí ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta gbogbo àwọn cardinal ni wọ́n nílò láti fi yan póòpù tuntun.
Àwọn ìbò tó bá kọ́kọ́ le sọ ẹni tí yóò di póòpù, tó sì lè mú káwọn cardinal fẹnukò lórí ẹnìkan.
Tí ìdìbò òní kò bá yọrí sí yíyan póòpù tuntu, àwọn cardinal máa padà sí ilé ìgbàlejò Casa Santa Marta fún oúnjẹ alẹ́. Wọ́n lè jíròrò láàárín ara wọn níbẹ̀ lórí ẹni tí wọ́n máa ṣàtìlẹyìn fún láti di póòpù tuntun.















