Nínú ọba 82, ìjọba kéde ojúlówó ọba 16 péré ní ilẹ̀ Benin, ariwo sọ
Ni ilẹ Yoruba, ipo pataki ni awọn ọba alaye wa, ti wọn si maa n pe wọn ni alasẹ, ekeji orisa.
Ilẹ Yoruba ko si mọ si orilẹede Naijiria nikan, koda, o tun na ọwọja rẹ de orilẹede olominira Benin pẹlu.
Oniruuru itan lo fi ye wa nipa ajọsepọ ati okoowo to wa laarin awọn Yoruba ni Naijiria ati ni Benin paapaa nilu Cotonou, Ajasẹ ati Dahomey.
Ọpọ ọmọ Yoruba si lo jẹ ọba alade ni ilẹ Benin, nibi ti apapọ awọn ọba to wa nilẹ naa ti jẹ mejidinlọgọrun.
Lara awọn ọba to jẹ tilẹ Yoruba laarin wọn ni Onisabẹ, Onipopo, ọba Ajasẹ, ọba Itako, Ọba Isakete, ọba Ilasọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ijọba ilẹ Benin ni abọ igbimọ iwadii ti oun gbe kalẹ jabọ pe ọpọ awọn oriade yii kii se ọba alade lati igba iwasẹ
Sugbọn iyalẹnu nla lo jẹ fawọn oriade naa ati gbogbo ilu lapapọ bi ijọba orilẹede Benin se kede pe ọba alade mẹrindinlogun pere ni oun da mọ ni orilẹede naa.
Bakan naa, ijọba Benin tun kede pe awọn ọba mejilelọgọrin yoku ni wọn jẹ oloye lasan, ti wọn kii si se oriade mọ.
O tun wa fofin de awọn ọba mejilelọgọrin naa lati mase maa de ade sori mọ ni orilẹede naa.
Alaye ijọba ilẹ Benin to se gbe igbesẹ naa ni pe abọ igbimọ iwadii ti oun gbe kalẹ jabọ pe ọpọ awọn oriade yii kii se ọba alade lati igba iwasẹ.
O ni awọn se awari rẹ pe iwadii nipa ori itẹ wọn sisọ loju rẹ pe ọba igbalode lasan ni ọpọ wọn lai ni itan laelae to gbe itẹ wọn kalẹ.
Ikede yii lo ti da awuyewuye silẹ ni orilẹede naa, idi sir ee ti BBC Yoruba fi kalẹ silẹ olominira Benin lati tan wadii isẹlẹ naa.
A ba awọn oriade ti ijọba gba ade lori wọn sọrọ nipa ero wọn lori isẹlẹ yii, ti a si tun kan si ijọba orilẹede olominira Benin pẹlu.

"Ọpọ awọn eeyan lo n dide, ti wọn n pe ara wọn ni ori ade, idi ree ti ijọba fi gbe igbesẹ to gbe naa"
Nigba to n ba BBC Yoruba lẹsẹ, Ọba ilu Itakọn ti ọrọ naa kan, ọba Aderobiojo Iloufemiloye salaye pe kii se ẹjọ ijọba ni ọrọ yii rara.
"Ọpọ awọn eeyan lo n dide, ti wọn n pe ara wọn ni ori ade, idi ree ti ijọba fi gbe igbesẹ to gbe naa.
Nigba to ba ya, ijọba si tun maa se agbeyẹwo ofin yii, ti yoo si tun kede awọn ọba miran to ti yọ nipo tẹlẹ, gẹgẹ bii ojulowo ọba.
Lọwọ bayii, ijọba ko mọ ilu mi Itako gẹgẹ bi ilu ọlọba, ilu Isakete ni ijọba mọ, wn si ni abẹ ilu Isakete ni Itako wa, eyi ni alaye ti wọn se."

"Ijọba gan mọ pe awa ọba ni orilẹede yii ju mẹrindinlogun lọ, amọ ka dupẹ pe ijọba tiẹ kede pe oun da oriade mẹrindinlogun mọ laarin wa"
Bakan naa, ọba miran ti ijọba gba ade lori rẹ, oriade ti ilu Ilasọ, Ọba Adehoumi Kifouli Adepadawale ni ijọba gan funra rẹ mọ pe awọn oriade to wa nilẹ olominira Benin ju mẹrindinlogun to mu lọ.
"Ijọba gan funra rẹ mọ pe awa ọba ni orilẹede yii ju mẹrindinlogun lọ, amọ ka dupẹ pe ijọba tiẹ kede pe oun da oriade mẹrindinlogun mọ laarin wa.
Bi ijọba ko ba kede pe oun da wa mọ rara n kọ, ki la fẹ se?
Amọ mo mọ pe nigba to ba ya, wọn yoo pada kede awa ọba yoku naa, amọ ka tiẹ kọkọ dupẹ lọwọ wọn fun eyi to se.
Ijọba ilẹ Benin sẹsẹ bẹrẹ isẹ lori eleyi lọwọ ni, mo bẹ awọn eeyan pe ka fi ọwọ sowọpọ pẹlu wọn.
Ni ti emi, mo fi gbogbo apa ati ẹsẹ mi fara mọ igbesẹ ti ijọba gbe naa lori awọn lọba lọba, ka sa maa gbadura pe ki ẹmi olori wa gun, atunto to fẹ se nipa isẹsẹ pọ, ki Ọlọrun fun se."

Ki ni igbesẹ tawọn ọba alaye tọrọ kan n gbe lati fi ẹhonu wọn han lori bi ijọba se gba ade lori wọn?
Nigba to n salaye igbesẹ ti awọn oriade ti ijọba gba ade lori wọn n gbe lori isẹlẹ naa, ọba Iloufemiloye ni awọn ti lọ sile asofin orilẹede naa lati fi ẹhonu wọn han.
"A lọ si Assembly nigba ti ikede ijọba yii jade, pe bawo ni wn se maa ni awọn ko mọ ilu Itakọn, to jẹ pe lati aye Ceaser ni ilu naa ti ni ọba.
Amọ wọn sọ fun wa nibẹ pe isọri akọkọ ni wọn se, nigba to ba ya, wọn yoo tun kede awọn ọba miran bii ojulowo oriade nilẹ Benin."






