Ìdí rèé tí mo ṣe lọ sọ́dọ̀ àjọ EFCC - Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo
Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Iyabo Ojo ti ṣalaye eredi ti ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC, ṣe fiwe pe e.
Iyabo lo fi ọrọ naa lede loju opo Instagram lati fesi si ibeere ọgọrọ awọn ololufẹ rẹ to n bere ohun to gbe lọ si ọgba ajọ naa.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, ilẹ Gẹẹsi lo wa ti EFCC ti ke si amọ ọjọ karun un, oṣu Karun un yii gan lo to yọju si EFCC.
Oṣere naa ṣalaye pe eredi ipe EFCC ko ṣẹyin bi awọn eeyan kan ṣe na owo loju agbo igbeyawo ọmọ oun, Priscilla.
O ni "Laipẹ yii ni mo ni iriri kan pẹlu EFCC lẹyin ti wọn fi iwe pe mi nigba ti mo wa ni UK.
"Ni kete ti mo pada de ni mo de EFCC lalejo lọjọ karun un, oṣu Karun un, ọdun 2025 nibi ti wọn ti bere oniruru ibeere lọwọ mi nipa bi mo ṣe jẹ, iṣẹ oojọ mi, iriri mi lẹnu iṣẹ, awọn ileeṣẹ ti mo ni atawọn ibere mii.
"Awọn oṣiṣẹ EFCC fi fidio ibi ti awọn ọrẹ atawọn akẹgbẹ mi ti n na owo naira ati owo ilẹ okere loju agbo igbeyawo ọmọ mi."
Iyabo ṣalaye pe oun bere lọwọ EFCC boya ẹṣẹ ni labẹ ofin ki eeyan maa na owo loju agbo nitori ohun ti oun ka si ẹṣẹ ni ki eeyan maa ba owo naira jẹ.
O ni EFCC sọ fun oun pe ko tọ lati maa lẹ owo naira tabi dọla mọ eeyan loju ni Naijiria, eyii to jẹ iyalẹnu fun oun.
Lẹyin o rẹyin, Iyabo ni EFCC fi oun silẹ lọjọ kan naa lai ti oun mọle.
O ni agbẹjọro oun, O.I Salami yoo maa ṣoju oun ni gbogbo igba ti ajọ naa ba tun nilo oun fun ohunkohun.
Lẹyin naa lo gba awọn ololufẹ rẹ nimọran pe ki wọn ṣọra fun owo nina loju agbo ariya papa aṣa lilẹ owo mọ eeyan loju.















