Russia fẹ̀sùn kan Ukraine pé ó ju àdó olóró sí Moscow ṣáájú ayẹyẹ ogun àgbáyé kejì

Oríṣun àwòrán, EPA
Ijọba Russia ti fẹsun kan Ukraine pe o sọ ado oloro lati oju ofurufu siluu Moscow.
Awọn alaṣẹ Moscow sọ pe ikọlu yii lo n waye lẹyin ti Aarẹ Vladimir Putin paṣẹ jogun-o-mi ti wọn si n mura lati yan fanda ni iranti ogun agbaye keji.
Ado oloro naa ni wọn sọ pe o balẹ si Moscow laarin ọjọ diẹ si ayẹyẹ iranti ogun agbaye keji.
Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹnikẹni to farapa tabi ti ẹmi rẹ sọnu ninu ikọlu naa, ijọba Ukraine ko tii sọ nnkankan nipa rẹ.
Ọjọ kẹsan an, oṣu Karun un, ọdun 2025 yii lo yẹ ki ayeyẹ iyanfanda naa waye lati sami si aṣeyọri Soviet Union lori Nazi Germany.
Ọdun yii lo pe ọgọrin ọdun ti ogun agbaye keji wa sopin, ọpọ awọn olori orilẹede lagbaye lo si fẹ ṣe ayẹyẹ iranti ogun naa ni Moscow, ninu eyii ti Aarẹ China, Xi Jinping, wa lara wọn.
Ṣaaju ni Putin ti pe fun jogun-o-mi ṣaaju ayẹyẹ naa fun ọjọ mẹta amọ ijọba Ukraine n fẹ ki ọjọ naa pọ ju iye ti Putin kede lọ.
Agbẹnusọ ijọba Russia, Dmitry Peskov sọ pe "A ko ni kọlu wọn ṣugbon ti ijọba Kyiv ba kọ lati tẹle adehun naa, a o o da a pada fun fun wọn lẹsẹkẹsẹ."
Amọ ṣa, Aarẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky ti sọ pe eremọde lasan ni jogun-o-mi ti Putin kede, to si bere pe ki wọn dawọ ogun naa duro fun o kere tan, ọgbọn ọjọ gbako.
Zelensky wa kilọ fun awọn eeyan rẹ ki wọn ṣora fun lilọ si iha Russia nitori ohunkohun lo le ṣẹlẹ lasiko jogun-o-mi ti Putin kede naa.















