UK gbé ìlànà tuntun kalẹ̀ lórí 'Visa' gbígbà ní Nàìjíríà àti orílẹ̀èdè méjì míì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Joe Pike
- Role, Political investigations correspondent
- Author, Fiona Nimoni & Alex Boyd
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Ìjọba UK ti ní àyípadà máa wáyé sí bí àwọn èèyàn ṣe ń gba físà wọ orílẹ̀ èdè náà pàápàá láti àwọn orílẹ̀ èdè tó jẹ́ pé àwọn èèyàn wọn kìí fẹ́ kúrò mọ́, tí wọ́n bá ti wọ orílẹ̀ èdè náà.
Lábẹ́ èròńgbà Home Office tuntun yìí, èyí tí Times kọ́kọ́ gbé jáde, àwọn èèyàn láti Pakistan, Nigeria àti Sri Lanka ni ó ṣéeṣe kó ṣòro láti rí físà wọ UK tún le díẹ̀ si.
Àwọn Mínísítà gbàgbọ́ pé àwọn tó ń wọ UK bó ṣe tọ́ lábẹ́ òfin láti àwọn orílẹ̀ èdè náà fún iṣẹ́ tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n kìí fẹ́ kúrò mọ́, tí wọ́n sì máa ń bèèrè fún ààbò láti máa gbé UK lọ títí.
Agbẹnusọ Home Office kan sọ pé ètò gbígba àwọn èèyàn wọ ilẹ̀ náà, tó máa jáde láìpẹ́ máa ṣe àgbéjáde àwọn ìlànà láti fi ṣàmójútó ìlànà gbígba àwọn èèyàn wọ orílẹ̀ èdè náà.
Kò ì tíì sí àgbéjáde lórí orílẹ̀ èdè táwọn èèyàn rẹ̀ máa ń pẹ́ jùlọ ní UK bó ṣe jẹ́ pé Home Office kò ì tíì ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn tó ti kúrò ní UK láti ọdún 2020.
Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti kúrò ní UK ni kò sí àkọ́ọ́lẹ̀ wọn, èyí túmọ̀ sí pé àwọn èèyàn tí kò sí àkọ́ọ́lẹ̀ pé wọ́n ti kúrò ni ó ṣeéṣe kí wọ́n má sì í ní UK mọ́.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Jonathan Portes, tó jẹ́ àgbà ọ̀jẹ̀ lórí ètò Changing Europe sọ pé ipa tí fífi òfin dé físà gbígba máa ní lórí iye àwọn tó ń bèèrè fún ààbò ní UK ṣeéṣe kó kéré jọjọ.:
"Mo lérò pé ipe tí wọ́n fẹ́ kó ní kìí ṣe lórí iye èèyàn, èròńgbà rẹ̀ ni láti mú àdínkù bá iye èèyàn tó ń bèèrè fún ààbò, tí wọ́ n ń ṣàmúlò rẹ̀ lọ́nà tí kò yẹ," ó sọ fún ètò BBC Radio 4's Today.
"Nígbà tí èèyàn bá wọlé pẹ̀lú físà akẹ́kọ̀ọ́, tó kàn ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí ní bèèrè fún ààbò lójijì… ìwà kò tọ́ nìyẹn – ohun sì ni ìjọba ń gbìyǹjú láti mú àdínkù bá."
Àtẹ̀jáde tí Home Office fi hàn pé èèyàn tó lé ní 108,000 ló bèèrè fún ààbò ní UK ní ọdún tó kọjá. Èyí ni àkọ́ọ́lẹ̀ àwọn tó ń bèèrè fún ààbò tó pọ̀ jùlọ láti ọdún 1979.
Lápapọ̀, 10,542 ló bèèrè fún ààbò tó jẹ́ ọmọ Pakistan, 2,862 láti Sri Lanka nígbà tí 2,841 sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Àtẹ̀jáde tuntun fún ọdún 2023/24 ṣàfihàn pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ òkèèrè 732,285 ló w[qa ní UK tí ọ̀pọ̀ wọn sì jẹ́ ọmọ India àti China.
Iye físà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ àti fún iṣẹ́ dínkù lọ́dún 2024 sí ti 2023.
Iye èèyàn tó ń wọ UK àti iye èèyàn àwọn tń kúrò jẹ́ 906,000 nínú oṣù Kẹfà, ọdún 2023 àmọ́ tó rí ìjákulẹ̀ sí 728,000nínú oṣù Kẹfà ọdún 2024.
Láti ìgbà tó ti di olóòtú ìjọba UK lọ́dún tó kọjá, Sir Keir Stammer ti ṣèlérí láti mú àdínkù bá báwọn èèyàn ṣe ń wọ orílẹ̀ èdè náà lábẹ́ ìlànà tó bá òfin mu àti ọ̀nà tí kò tọ́.
Èrò ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ni láti mú adínkù bá ìwọ́lewọ̀de èèyàn ní UK nípasẹ̀ sísọ fífi ẹ̀mí àwọn èèyàn wéwu lórí odò di ìwà ọ̀daràn àti díndín gbígba àwọn òṣìṣẹ́ láti ilẹ̀ òkèèrè kù nípa ṣíṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fáọn ẹ̀ka tó máa ń gbáralé àọn òṣìṣẹ́ láti ilẹ̀ òkèèrè.
Sir Keir bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative pé wọn kò ṣe àmúṣẹ iye tó yẹ lórí ètò mímú àdínkù bá àwọn tó ń wọ UK àtàwọn tó ń jáde.
Iye èèyàn tó ń wọ UK àti iye èèyàn àwọn tń kúrò jẹ́ 906,000 nínú oṣù Kẹfà, ọdún 2023 àmọ́ tó rí ìjákulẹ̀ sí 728,000nínú oṣù Kẹfà ọdún 2024.
Àwọn ìlànà tuntun tí olóòtú ìjọba àná, Rishi Sunak gbé kalẹ̀ lójúnà àti mú àdínkù bá iye èèyàn tó ń wọ UK wà lára àwọn nǹkan tó fa ìjákulẹ̀ ètò náà.
Ìjọba lábẹ́ ẹgbẹ́ Conservative mú àlékún bá iye owó oṣù tí ẹni tó ní iṣẹ́ gidi lọ́wọ́ láti ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n fẹ́ gbà síṣẹ́ di £38,700 láti £26,200, tí wọ́n sì fòfin de àwọn tó wà lẹ́ka ṣíṣe ìtọ́jú láti máa kó ẹbí wọn wọ UK papọ̀ mọ́ wọn.
Labour ni wọ́n ti ń dúnkokò mọ́ láti mú àyípadà bá ètò ìwọléwọ̀de orílẹ̀ èdè náà àmọ́ tí ìdúnkokò náà peléke si lẹ́yìn àṣeyọrí ẹgbẹ́ Reform rí níbi ètò ìdìbò abẹ́lé tó wáyé lọ́sẹ̀ tó kọjá.
Ẹgbẹ́ Reform jáwé olúborí 677 nínú ìjókòó 1,600 níbi ètò ìdìbò ọjọ́rú èyí tó wáyé láwọn agbègbè tí Tory ti rọ́wọ́ mú níbi ètò ìdìbò 2021.
Lásìkò ìpolongo, ẹgbẹ́ Reform ní àwọn máa ṣe ìdádúró àwọn tó ń wọ UK láì sí ìdí kan pàtó, tó sì jẹ́ pé àwọn tó níṣẹ́ kan, bí àpẹẹrẹ lẹ́ka ètò ìlera, ṣì máa rí ààyè wọ UK.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí èsì ìbò náà, Sir Keir ní òun rí ìdí táwọn olùdìbò fi ń kọ̀ láti fẹ́ dìbò fáwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tó gbajúmọ̀, bó ṣe ní ìgbésẹ̀ náà ta òun jí láti tètè àmúṣẹ àwọn ìlérí tí òun ṣe nípa ìwọléwọ̀de àti ètò ìlú.
Èrò láti ṣe àtúnṣe sí báwọn èèyàn ṣe ń pẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ ló ti ń wáyé ṣáájú ètò ìdìbò.
Inú oṣù Karùn-ún yìí ni wọ́n máa gbé ìlànà tuntun lórí ìwọléwọ̀de tí ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe síta ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
Agbẹnusọ Home Office kan sọ pé "àwọn ti ń gbé ìgbésẹ̀ láti máa ṣe ìdánimọ̀ àwọn tó bá fi físà ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ UK tí wọ́n fẹ́ wá máa bèèrè fún ààbò ní kíákíá àti lásìkò.
"À ń ṣe àgbéyẹ̀wò ètò báwọn èèyàn ṣe ń gba físà lóòrèkóòrè, ibi tí a bá sì ti rí ìlànà tó ń jọra, èyí tó lè ní ipa lórí àwọn òfin ìwọléwọ̀de wa, a ò ní rosẹ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ.
"Lábẹ́ ètò àyípadà tuntun tó ń lọ lọ́wọ́, a máa ṣe àfihàn ìlànà láti mú àtúntò bá ètò ìwọléwọ̀de tó ti mẹ́hẹ."















