Àlàyé rèé lórí ìdí tí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ṣe fìdí rẹmi nínú ìdánwò UTME, bí JAMB ṣe kéde èsì ìdánwò náà

Oríṣun àwòrán, JAMB
Àjọ tó ń rí sí ètò ìdánwò ìgbaniwọlé sílé ẹ̀kọ́ gíga ìyẹn Joint Admissions and Matriculation Board, JAMB ti ṣàgbékalẹ̀ bí èsì ètò ìdánwò UTME ọdún 2025 tó parí láìpẹ́ yìí ṣe máa lọ.
Gẹ́gẹ́ bí JAMB ṣe sọ, nínú èèyàn 1,955,069 tó ṣe ìdánwò náà, àwọn tó lé ní ìlàjì ni kò gba tó máàkì 200.
Àwọn 4,756 ló gba máàkì tó lé ní 320 nígbà táwọn tí wọ́n gba máàkì láti 300 lọ sókè sì jẹ́ 12,414.
JAMB ṣàlàyé pé àwọn ọmọdé tí ọjọ́ orí wọn kò ì tíì tó ìdánwò náà tí wọ́n fún láàyè láti ṣe nítorí ìkápá wọn jẹ́ 40,247 àmọ́ 467 nínú ló ní máàkì tí JAMB ń gbà wọlé fún irú àwọn ọmọdé bẹ́ẹ̀ níbi ètò ìdánwò tó parí náà.
Wọ́n tún ṣàlàyé pé èèyàn 97 ni ọwọ́ tẹ̀ fún ṣíṣe èèrú lásìkò ìdánwò ọ̀hún nínú gbogbo àwọn tó ṣe ìdánwò náà, tí àwọn 2,157 sì ń kojú ìwádìí fẹ̀sùn pé wọ́n ṣèrú lásìkò ìdánò náà.
Wọ́n fi kun pé èèyàn 71,701 tó forúkọ sílẹ̀ fún ètò ìdánwò náà ni kò kópa níbẹ̀ àti pé àwọn tó jẹ́ pé àwòrán ojú wọn ni kò jẹ́ kí wọ́n rí ìdánwò náà kọ láwọn máa pèsè àǹfàní fún láti kọ ìdánwò náà ní gbọ̀ngán táwọn bá mú tó bá yá.
Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin ni ètò ìdánwò 2025 UTME bẹ̀rẹ̀ káàkiri Nàìjíríà, tó sì parí lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Karùn-ún.
UTME jẹ́ ìdánwò táwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá fẹ́ wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga, yálà ilé ẹ̀kọ́ aládàáni tàbí ti ìjọba àpapọ, gbọdọ̀ ṣe tó sì jẹ́ àjọ JAMB ló máa ń ṣe agbátẹrù rẹ̀.
Ìgbà wo ni JAMB máa fi èsì ìdánwò 2025 UTME síta?
JAMB kò sọ pé ìgbà kan pàtó báyìí ni èsì ìdánwò náà máa jáde.
Àtẹ̀jáde kan tí JAMB fi sójú òpó X rẹ̀ lọ́jọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹrin ní àwọn máa fi èsì ìdánwò UTME síta ní kété tí àwọn bá ti parí gbogbo àyẹ̀wò tó yẹ lórí wọn.
Bákan náà ni wọ́n rọ àwọn tó kópa nínú ìdánwò náà láti ṣe sùúrù pẹ̀lú àwọn.
Wọ́n ní kí gbogbo àwọn èèyàn náà láti máa kàn sí àwọn ojú òpó wọn lórí ayélujára láti mọ̀ nípa àwọn nǹkan tó bá ń ṣẹlẹ̀ lórí èsì ìdánwò náà.

Oríṣun àwòrán, JAMB
Báwo lo ṣe le è ṣàyẹ̀wò èsí ìdánwò UTME rẹ?
Akẹkọ to ba joko se idanwo asewọle sawọn ile ẹkọ giga, nílò láti lọ sí ilé ìforúkọsílẹ̀ fún ìdánwò láti ṣàyẹ̀wò èsì ìdánwò UTME.
Tí JAMB bá ti fi èsì ìdánwò náà síta, ohun tí o nílò láti ṣe ni kí o kọ àtẹ̀jíṣẹ́ "RESULT" sí 55019 tàbí 66019 pẹ̀lú nọ́mbà fóònù tí o fi forúkọ sílẹ̀ fún ìdánwò.
Wà á gba àtẹ̀jíṣẹ́ èsì ìdánwò rẹ.
Bákan náà ni àwọn tí èsì ìdánwò wọn náà kò bá ì tíì délẹ̀ náà máa gba àtẹ̀jíṣẹ́ pé iṣẹ́ ṣì ń lọ lọ́wọ́ lórí èsì wọn.
Àwọn tí àyẹ̀wò tàbí tí iṣẹ́ ń lọ́wọ́ le gba àtẹ̀jíṣẹ́ báyìí:
- Verification Investigation
- Under Investigation (A)
- Under Investigation (B)
- Alleged Infraction
Kí ni èsì ìdánwò UTME rẹ túmọ̀ sí?
Ìbéèrè ńlá tó máa ń tẹ̀lé èsì ìdánwò UTME ni pé kí ló kàn?
Àwọn nǹkan tí wà á gbé yẹ̀wò nìyí:
Gbèdéke máàkì tí JAMB ń fẹ́:
Àjọ JAMB máa ń fi gbèdéke sí máàkì tí ẹni tó bá fẹ́ wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì àti ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe gbọdọ̀ gbà.
Ní ọdún tó kọjá, máàkì 140 ni JAMB buwọ́lu fáwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, tí wọ́n sì buwọ́lu ọgọ́rùn-ún (100) máàkì fáwọn ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe àti ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni.
Àmọ́ JAMB ló gbé gbèdéke yìí sílẹ̀, àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga náà máa ń fi iye máàkì tí wọ́n ń fẹ́ síta.
Bákan náà láwọn ìmọ̀ ẹ̀kọ́ bíi ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbò, ìmọ̀ òfin àti ìmọ̀ ẹ̀rọ náà máa ń ní gbèdéke máàkì wọn ní ilé ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan.
Ìgbáradì fún Post-UTME
Níní gbèdéke máàkì ti JAMB jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ètò ìgbànisílé ẹ̀kọ́ gíga. Ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ máa ń ṣe ìdánwò fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n máa ń pè ní Post-UTME.
Ọ̀pọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ ló máa ń tẹmpẹlẹmọ Post-UTME ju gbèdéke tí JAMB máa ń gbé jáde lọ.
Láti gbáradì,
akẹ́kọ̀ọ́ le wá àwọn ìbéèrè tó ti kọjá lórí Post-UTME ilé ẹ̀kọ́ náà.
Kà nípa àwọn ẹ̀kọ́ tó jọ mọ́ ètò ẹ̀kọ́ tí akẹ́kọ̀ọ́ fẹ́ kọ́
Mọ̀ ìgbà gbèdéke ìforúkọsílẹ̀ máa wá sópin.
Lẹ́yìn ìdánwò UTME àti Post-UTME, ètò ìgbanisílé ẹ̀kọ́ máa lọ báyìí:
JAMB CAPS (Central Admission Processing System):
Ibi yìí ni JAMB máa fi orúkọ àwọn tí ilé ẹ̀kọ́ gíga bá gbà sí tí akẹ́kọ̀ọ́ sì lè:
- Gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ náà tàbí kọ̀ ọ́
- Ṣe àyẹ̀wò bóyá wọ́n ti gba òun sílé ẹ̀kọ́
- Fi èsì ìdánwò ilé ẹ̀kọ́ girama rẹ̀ síbẹ̀.
Láti lè ní àǹfàní sí CAPS, akẹ́kọ̀ọ́ máa wọlé sí CAPS lórí ayélujára, tó sì máa tẹ lẹ́yìn náà lo máa ló sí CAPS.
Ìgbéjáde àwọn tí ilé ẹ̀kọ́ gbà wọlé
Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹ̀ẹmẹta láwọn orúkọ tí ilé ẹ̀kọ́ bá gbà sílé ẹ̀kọ́ wọn máa ń jáde.
Àkọ́kọ́ ni ti àwọn ti máàkì wọn pọ̀ dáadáa. Ìkejì ni àwọn ti máàkì wọn tẹ̀lé wọn, tí ipele tó kẹ́yìn sì jẹ́ táwọn tí m'[akì kò pọ̀ àmọ́ tí wọ́n le fi sí ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ míì.
Ṣíṣe àyípadà ilé ẹ̀kọ́
Tí èsì ìdánwò rẹ kò bá wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí o yàn tẹ́lẹ̀, JAMB fi ààyè sílẹ̀ láti ṣe àyípadà ilé ẹ̀kọ́ sí ilé ẹ̀kọ́ míì.
Ní orí ayélujára ni èèyàn ti lè ṣe èyí.















