Lẹ́yìn ò rẹyìn, EFCC ṣàlàyé ìdí tí VDM fi wà ní àhámọ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Verydarkman/Facebook
Àjọ tó ń gbógunti ìwà ọ̀daràn ní Nàìjíríà, EFCC ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ti nawọ́ gán gbajúmọ̀ ajáfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn, Martins Vincent Otse tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Verydarkman, VDM.
Agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún BBC.
Dele Oyewale sọ fún BBC lọ́jọ́ Ajé pé àwọn kan ló kọ̀wé ẹ̀sùn tako VDM ránṣẹ́ sí àwọn, láwọn fi nawọ́ gán an.
Nígbà tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ Oyewale pé bóyá fífi VDM sí àhámọ́ lọ́wọ́ ilé ìfowópamọ́ GTBank nínú, Oyewale ní kìí ṣe èèyàn kan ló kọ̀wé ẹ̀sùn lórí VDM ránṣẹ́ sáwọn àti pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti dá ààbò bo àwọn èèyàn náà.
Ó fi kun pé àwọn máa fi sílẹ̀ nígbà tó bá ti rí gbogbo ohun tí wọ́n nílò láti fi gba béèlì rẹ̀ àti pé àwọn máa gbé lọ sílé ẹjọ́ láìpẹ́.
"Ẹni tó máa ń tẹ̀lé òfin ni wá," Oyewale sọ.
Bákan náà ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìlú Abuja ni àwọn ti nawọ́ gan.
GTB fi fídíò kan síta pé VDM kúrò nínú ọgbà àwọn, kó tó di pé ó di àwátì
Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejì, oṣù Karùn-ún ni ìròyìn gba orí ayélujára pé àwọn kan nawọ́ gán VDM nígbà tó lọ sí ilé ìfowópamọ́ GTB.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n fẹ̀sùn kan GTB lórí ayélujára lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àmọ́ GTB lọ́jọ́ Àìkú fi fídíò kan síta pé VDM kúrò nínú ọgbà àwọn, kó tó di pé ó di àwátì.
Lára àwọn fídíò tó gba orí ayélujára ṣàfihàn báwọn olólùfẹ́ àti alátìlẹyìn VDM ṣe ya lọ sí ọ́fíìsì EFCC lópin ọ̀sẹ̀ pé àwọn fẹ́ fun lóúnjẹ àmọ́ táwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò EFCC kò jẹ́ kí wan wọlé, pé àwọn máa fún VDM láwọn oúnjẹ náà fúnra wọn.
Àwọn ọ̀dọ́ mìíràn tún ní àwọn máa ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn nílùú Abuja lórí ọ̀rọ̀ VDM.
Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn lórí ayélujára ni wọ́n ti ń pè fún ìtúsílẹ̀ VDM kúrò ní àhámọ́ EFCC.
Olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi àti gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé, David Adeleke tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Davido náà ti dá sí ọ̀rọ̀ náà.
Davido pè fún ìtúsílẹ̀ VDM àmọ́ tí Obi ní tirẹ̀ bu ẹnu àtẹ́ lu bí wọ́n ṣe nawọ́ gán VDM bíi ẹni pé wọ́n jí i gbé.
Omoyele Sowore sọ pé EFCC mọ̀ọ́mọ̀ nawọ́ gán VDM láti pa á lẹ́nu mọ́ ni nítorí tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà.
Kí ni agbẹjọ́rò VDM sọ?
Agbẹjọ́rò VDM, Deji Adeyanju ní lóòótọ́ ni pé EFCC ló gbé oníbàárà òun àmọ́ àwọn kò faramọ́ bí wọ́n ṣe mú un.
Àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ rẹ̀ fi síta sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ EFCC ti VDM mọ́ inú ọ́fíìsì wọn tó wà ní Abuja àti pé wọ́n ní VDM ní òun kò ṣetán láti bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ nígbà tí àwọn débẹ̀.
Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ fi ìwé àṣẹ tí Njideka Iloanya ti ilé ẹjọ́ Májísíréètì fáwọn láti nawọ́ gán VDM fẹ́sùn wí pé ó tọpinpin àwọn èèyàn lórí ayélujára.
Wọ́n ní àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọ́n gba ìtúsílẹ̀ rẹ̀ àmọ́ inú àwọn kò dùn pé EFCC kò sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gangan fáwọn.
Ta ni VDM?

Oríṣun àwòrán, Verydarkman/Facebook
Ajàfẹ́tọ̀ọ́ tó máa ń pe ara à rẹ̀ ní ẹlẹ́yinjú àánú tó máa ń ṣe ìtọrẹ ni Martins Vincent Otse tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Verydarkman.
Ó gbajúmọ̀ fún títako àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, ìwà àjẹbánu àtàwọn èèyàn tó bá ń lòdì sí òfin míì lórí ayélujára.
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti nawọ́ gán VDM fáwọn nǹkan tó máa ń jà fún, tó sì ní ọ̀pọ̀ ẹjọ́ tó ń ṣe láwọn ilé ẹjọ́ káàkiri.















