"Amotekun gbé àbúrò mi lọ́jọ́ Àìkú, pa á lọ́jọ́ Ajé, ọ̀gá wọn ń bẹ̀ mi, kí ń gba N1m láti fi sin ín"

Àkọlé fídíò, "Amotekun gbé àbúrò mi lọ́jọ́ Àìkú, pa á lọ́jọ́ Ajé, ọ̀gá wọn ń bẹ̀ mi, kí ń gba N1m láti fi sin ín"
"Amotekun gbé àbúrò mi lọ́jọ́ Àìkú, pa á lọ́jọ́ Ajé, ọ̀gá wọn ń bẹ̀ mi, kí ń gba N1m láti fi sin ín"

Adura ti ọpọ eeyan maa n gba ni pe ki Ọba Oke mase jẹ ka rin arinfẹsẹsi, ki wọn ma si ṣi wa mu, ka ma jọ ẹni ti wọn n wa.

Gende ọkunrin to to iyawo fẹ ni Sunday Joseph, tii se ọmọ ipinlẹ Delta amọ adura yii ko gba lori rẹ, bo se ko sọwọ ikọ Amotẹkun nipinlẹ Ondo, to si jade laye.

Iroyin iku Sunday yii lo gba ilẹ kan lori ayelujara, eyi to mu ki BBC Yoruba gbera lọ silu Owo lati tanna iwadi wa si ohun to se okunfa isẹlẹ naa.

Gẹgẹ bi a se gbọ, ọrẹbinrin Sunday Joseph wa nibẹ nigba ti Amọtẹkun wa mu afẹsọna rẹ.

A ba ẹgbọn Sunday to jẹ obinrin sọrọ pẹlu ọrẹbinrin rẹ to wa nibẹ nigba ti ikọ Amọtẹkun mu afẹsọna rẹ ati agbẹjọro fun ẹbi Sunday.

Sunday Joseph ati ẹgbọn rẹ, Veronica Joseph

"Ikọ Amotekun mu Sunday Joseph ni ọjọ Aiku, wọn si pa ku ni ọjọ Aje"

Ẹgbọn Sunday Joseph to jẹ obinrin, Veronica Joseph salaye fun BBC Yoruba pe ilu Ibadan ni oun wa, ti aburo oun fi pe oun pe ikọ Amọtẹkun ti gbe aburo oun, Sunday.

"Bi wọn se fi iroyin naa to mi leti, mo ni ki wọn fi ọrọ naa to agbẹjọro leti.

Ile ọrẹ

binrin rẹ ni wọn ti mu, ọrẹbinrin rẹ si wa nibẹ, oun lo jẹ ka mọ pe ikọ Amọtẹkun lo gbe Sunday lọ.

Aburo mi ni oun lọ sileesẹ ikọ Amọtẹkun, ti oun si ri Sunday, ti wọn di ọwọ ati ẹsẹ rẹ, ti wọn si bẹrẹ si ni na a.

Nigba to di ọjọ keji ni aburo mi tun pe mi pe oun n gbọ iroyin pe wọn ti pa Sunday.

Wọn mu Sunday ni ọjọ Aiku, wọn si pa ku ni ọjọ Aje."

Veronica Joseph

"Ọga ikọ Amọtẹkun n bẹ mi, o ni ki n gba milliọnu kan Naira lati fi sin aburo mi"

Arabinrin Veronica tẹsiwaju pe oun sare pada si Akure ni ọjọ Isẹgun, ti oun si lọ sile isẹ Amotekun amọ wọn ko jẹ ki oun wọle.

"Mo ba tun gba ileesẹ Amotekun to wa ni ilu Owo lọ, se ni awọn osisẹ wọn n fi mi se yẹyẹ, ti wọn ko si jẹ ki n wọle sile isẹ wọn.

Mo ba sare lọ sile igbokusi lati mọ boya ikọ Amọtẹkun gbe oku kankan wa sibẹ, ibẹ si ni a ti ri oku Sunday ti wọn gbe wa sibẹ.

Mo lọ ba ọga awọn Amotekun ni Owo, o bẹrẹ si ni bẹ mi, o si ni ki n gba milliọnu kan Naira lati fi sin aburo mi.

Amọtẹkun n daabo bo awọn to pa aburo mi, amọ ọga wọn n bẹ mi.

Mo si sọ fun pe ọmọ ipinlẹ Delta ni wa, awọn ẹbi fẹ ri oku rẹ, ki wọn si mọ iru iku to paa.

Monday Joseph ni ọmọkunrin kan soso ti daddy wa bi, obinrin ni awa yoku."

Veronica Joseph wa rawọ ẹbẹ si ijọba ati gbogbo ọmọ Naijiria lati da si ọrọ naa, ki awọn le mọ ohun ti Sunday se, ti wọn fi pa a.

Aminat Surajudeen

"Emi ati Sunday n lọ sọdọ ẹgbọn wa, Amotekun da ọkada ti a gun duro, wọn si gbe afẹsọna mi lọ"

BBC Yoruba tun ba ọrẹbinrin Sunday Joseph sọrọ, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ Aminat Surajudeen lati mọ bi isẹlẹ naa se waye.

Aminat salaye pe "A n lọ silu wa, a gun ọkada lọ silu wa lọ sọdọ ẹgbọn wa, bi ọkada se fẹ ya soju opopona ile wa ni ọkọ Amotekun duro, ti wọn si gbe Monday lọ.

Ọọfisi Amọtẹkun wa ladugbo ẹgbọn mi naa, a ko mọ boya wọn ti n tẹle wa bọ amọ bi a se fẹ ya, ni wọn da wa duro.

Wọn gbe Sunday lọ lai mọ oun to se."

Sunday Joseph

Mo ti kọwe si gomina ipinlẹ Ondo lori isẹlẹ yii, mo tun kọwe si ileesẹ ikọ Amotekun amọ ko ti fesi – Agbẹjọro

Nigba toun naa n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹjọro fun ẹbi Joseph ni oun ti kọwe si gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Ayedatiwa nipa isẹlẹ naa.

Bakan naa lo fikun pe oun ti kọwe si Amọtẹkun to wa nipinlẹ Ondo amọ wọn ko tii fesi lori isẹlẹ naa.

"Bi a maa lọ sile ẹjọ abi a ko ni lọ sile ẹjọ, iyẹn wa ku sọwọ ẹbi Sunday Joseph lati pinnu lori rẹ.

Amọ igbesẹ wa lori rẹ nitori ikọọkan la n yọsẹ lẹku."