Ẹ̀ṣọ́ Amotekun ká orí àti ara èèyàn mọ́ afurasí méjì lọ́wọ́ ni Saki

Oríṣun àwòrán, Oyo Amotekun
Awọn afurasi meji, Adebisi Alli ati Abdullahi Salami ni awọn ẹṣọ eleto aabo Amotekun ti fọwọ ofin mu bayii lẹyin ti wọn ba ori eeyan lọwọ wọn niluu Saki ni ẹkun Oke Ogun nipinlẹ Oyo.
Wọn tun ba ẹya ara eeyan ninu peeli to wa pẹlu ọkan lara awọn afurasi naa, Abdullahi.
Bakan naa l'awọn ẹṣọ Amotekun tun ka ikoko ti eegun ẹsẹ eeyan ati oriṣiiriiṣi ẹya ara eranko wa ninu rẹ mọ afurasi Kejì lọwọ.
Ohun ti a gbọ ni pe ọjọ Aje ni wọn ge ori eeyan naa kuro lara oku kan lẹyin wakati diẹ ti wọn sin oku naa.
Igbakeji ọga Amotekun nipinlẹ Oyo, Ọgbẹni Kazeem Babalola Akinro ṣalaye pe "ni aarọ ọjọ Isẹgun ni a gbọ pe wọn ri ori eeyan labẹ ọkọ kan.
Ẹni to ni ọkọ naa lo sọ fawọn ẹṣọ Amotekun pe nigba ti oun fẹ jaaki ọkọ oun soke loun ri nkan naa to wa ninu ọra labẹ ọkọ oun.
O ni iyalẹnu lo jẹ fun oun pe ori eeyan lo wa ninu ọra naa nigba ti oun tu wo, eyi to mu ki oun pe awọn Amotekun.
Lẹyin naa l'awọn ẹṣọ Amotekun lọ wo ile Alli, ọkan lara awọn afurasi, nibi ti wọn ti ba ikoko lori ina eyi ti egungun ẹsẹ eeyan ati ẹya ara ẹranko ati ẹyẹ wa ninu rẹ.
Bakan naa ni a ba awọn eroja mii ninu ile rẹ eleyii to jẹwọ pe oun n lo pẹlu ẹyà ara eeyan."
Alli tun jẹwọ pe afurasi keji, Abdullahi lo ni ori eeyan at'awọn ẹya ara ti oun n jo ninu ikoko.
Abdullahi naa ni Alli lo ni ki oun lọ wa ori eeyan wa.
O tun jẹwọ pe oun ati ẹnikan l'awọn jọ lọ ge ori oku ti wọn ṣẹṣẹ sin ni ibi isinku.
Abdullahi ni ẹgbẹrun l'ọna ogoji naira lo yẹ ki Alli san fun oun ki aṣiri to tu.
Alli naa gba wi pe oun loun ran Abdullahi n'isẹ lati wa ori eeyan wa.
Ọgbẹni Akinro ṣalaye pe ẹṣọ Amotekun ti jọwọ awọn afurasi naa at'awọn nkan ti wọn ka mọ wọn lọwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fun iwadii.















