Èyí ni bí Pásítọ̀ T.B. Joshua ṣe bo àṣírí ìpànìyàn rẹpẹtẹ nígbà tí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ dàwó l'Eko

Oríṣun àwòrán, AFP
Iṣẹ iwadii ikọ iroyin BBC ti ṣawarii bi Pasitọ agba nni, T.B Joshua ṣe tọju awọn oku eeyan to ku nigba ti ṣọọṣi rẹ da wo lulẹ lọdun 2014, to si tun dunkooko mawọn ẹbi teeyan wọn ku ti wọn ko fi le wi nnkankan.
Iṣẹlẹ ileejọsin to dawo naa lo buru ju ninu itan nipa ile ijọsin to wo ri nilẹ Adulawọ. Eeyan ọgọrun-un kan ati mẹrindinlogun (116) lo doloogbe ninu iṣẹlẹ naa.
Iṣẹ iwadii BBC yii fi aridaju iṣẹlẹ ṣọọṣi to wo lọdun mẹwaa sẹyin naa han kedere lati inu ijọ Synagogue Church Of All Nations (SCOAN), a ri i ifiyanjẹni to waye ninu ileejọsin agbaye ọhun latọwọ oludasilẹ rẹ.
Ṣugbọn ọjọ keji lẹyin ti ṣọọṣi naa wo, lọjọ kejila oṣu kẹsan-an ọdun 2014, Pasitọ T.B Joshua kede fun gbogbo aye pe baaluu kan to kọja labala ibi to wo lulẹ naa lo fa a to fi wo. Ibẹ si lawọn arinrinajo n de si.
Eyi tako abajade esi igbimọ oluyẹwo ipinlẹ Eko to ni aitẹle ilana ile kikọ lo jẹ ki ẹka ibi igbalejo naa wo lulẹ.
Wọn ni wọn kọ ile naa nilana ti ipilẹ rẹ ko duro daadaa lo ṣe wo.
‘Irọ ni T.B Joshua pa nipa baaluu to lo wo ṣọọṣi rẹ’

Awọn o ṣoju mi koro nilee ijọsin SCOAN fidi ẹ mulẹ, pe irọ nla ni T.B Joshua pa lori baalu to lo kọja.
Wọn lawọn ti kilọ fun un lọpọ igba kiṣẹlẹ naa too ṣẹlẹ, oun lo kọti ọgbọin simọran awọn.
‘’O mọ pe ile yẹn ko duro daadaa, a ti sọ fun un ko too ṣẹlẹ pe ile naa n mìn bii pe o fẹẹ wo.
‘’Ọpọlọpọ eeyan lo ku lẹsẹkẹsẹ nigba tile yẹn wo, awọn to ha si iho ilẹ si le lọgọrun-un. Mo n gbọ tawọn eeyan n pariwo ẹ gba wa.
‘’Nigba to ya, a ko gbọ daadaa mọ, wọn ti n ku lọ titi ti wọn fi ku patapata’’
Emmanuel, ọkan ninu awọn eeyan to ti lo ju ọdun mẹwaa lọ ni ṣọọṣi SCOAN lo sọ eyi fun BBC.
‘Awọn to padanu ẹya ara ko lonka yatọ sawọn to ku’
Ẹya ara bii ẹsẹ ati oju awọn ẹlomi-in nileejọsin naa ba iṣẹlẹ yii lọ, abala ile to wo lu wọn lo si fa a.
‘T.B Joshua gbe ile naa ga ju iye àjá tijọba fọwọ si lọ’
Rae, obinrin kan lati UK, to lo ọdun mejila ni ṣọọṣi Sinagọgu, sọ fun BBC pe Oloogbe T.B Joshua kọ ṣọọṣi naa ga ju iye aja tijọba fọwọ si fun un lọ.
O ni oju oun lo ṣe nigba ti Pasitọ T.B Joshua n paṣẹ fawọn oṣiṣẹ to n kọ ile naa pe ki wọn fi kun iye aja rẹ.
‘Awọn olujọsin kọminu, wọn ni ẹmi ko ba maa ṣofo bẹẹ ka ni Joshua tete dahun si iṣẹlẹ naa ni’
‘Odidi ọjọ kan gbako ni ko fi jẹ kawọn eleto pajawiri wọle lati ṣiṣẹ wọn lẹyin ti ile wo’
Awọn o ṣoju mi koro fidi ẹ mulẹ pe, Pasitọ T.B Joshua ko jẹ kawọn ẹṣọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri wọle lẹyin iṣẹlẹ naa. Gbogbo oju ọna pajawiri lo di pa mọ wọn.
Awọn ẹka iroyin si gbe e jade lododo pẹlu nigba naa.
Ikọ BBC to wa nibẹ pẹlu sọ pe awọn eeyan gbiyanju lati doola awọn to wa labẹ ile naa, wọn sa agbara wọn lai ni irinṣẹ kan pato, ki ẹmi ti yoo ṣegbe le dinku.
‘Pasitọ T.B Joshua paṣẹ pe kawọn oṣiṣẹ rẹ ko awọn oku pamọ, kawọn oniroyin ma baa ri i’
Yatọ si Micheal, ọmọ ẹyin pasitọ naa, awọn mẹta mi-in tun ṣalaye bi Joshua ṣe paṣẹ pe kawọn maa ko awọn oku pamọ loru kawọn akọroyin ma baa ri i.
Awọn meji ninu awọn oṣiṣẹ naa ni wọn ni ki wọn maa ka gbigbe oku naa silẹ, wọn fidio rẹ bo ṣe n lọ.
‘’ A n fidio rẹ bi wọn ṣe n gbe awọn oku naa sinu apo, oku eeyan rẹpẹtẹ bii ẹni gbe oku ẹran loko’’ Bẹẹ ni Micheal wi.
Obinrin kan, Chloe lati UK, toun naa jẹ ọmọ ẹyin Joshua tẹlẹ sọ pe, ‘’ Bi mo ṣe wọnu mọto lagbegbe ibi tawọn oku naa wa ni mo bẹrẹ si i gboorun buruku kan, dẹrẹba lo sọ fun mi pe oku eeyan lo kun inu mọto naa.
O lawọn fẹẹ gbe wọn lọ kawọn akọroyin ma baa ri i ni’’

‘T.B Joshua ko yọju si kootu bi jọba ṣe pe e to’
Bo tilẹ jẹ pe awọn oluwadii iṣẹlẹ naa sọ pe kijọba Eko pe Joshua lẹjọ fun ẹsun ọdaran, ti wọn si pe e si kootu, ọkunrin naa ko yọju si kootu ri
‘’ Ọpọlọpọ owo dọla, rand ati naira lo ṣiṣẹ abẹtẹlẹ tẹjọ fi ku s’Ake’
Iwadii fi han pe ọpọlọpọ owo dọla, rand ti South Afrika pẹlu naira Naijiria lawọn eeyan Joshua fi di awọn to padanu eeyan wọn lẹnu.
Owo nla nla ni wọn fi tu wọn loju ti ẹjọ naa fi dohun igbagbe.
85 awọn eeyan to doloogbe naa jẹ ọmọ South Afrika
‘Apo owo ni wọn gbe fun mi pe ki n lọọ fawọn ẹbi teeyan wọn ku labẹ ile naa ni South Africa’’
Shile, olutẹle T.B Joshua tẹlẹ ṣalaye pe iṣẹ ti wọn foun ni lati gbe apo owo nla lọ fawọn mọlẹbi teeyan wọn ku ninu iṣẹlẹ naa ni South Africa.
‘’A maa n sọ fun wọn pe wọn o gbọdọ ba oniroyin kankan sọrọ. Wọn o gbọdọ sọ bohun kohun ṣe ṣẹlẹ. A n pa ohun mọ agogo wọn lẹnu pẹlu owo ni’’
Mọlẹbi South Africa mẹta ti wọn padanu eeyan wọn ba BBC sọrọ
Ọkunrin kan,Llwandle Mkhulisi, lati Johannesburg, to padanu aburo rẹ obinrin sinu iṣẹlẹ naa ko gba owo ti wọn gbe wa fun un. O ṣapejuwe owo naa fun BBC bii owo ẹjẹ.
Sonny Madzhiye, lati Benoni, sọ fun BBC pe oun ti kọkọ 50,000 rand lọwọ awọn ti Joshua ran wa nigba tọmọ oun obinrin torukọ ẹ n jẹ Sibongile, ku ninu iṣẹlẹ ile to wo naa.
O ni nigba to ya loun ko gba a lọwọ wọn mọ. Oun ri i pe wọn n fowo naa dena oun lati ja fẹtọọ oun ni.
Gbogbo itakurọsọ rẹ pẹlu Oloogbe T.B Joshua lori ọrọ owo naa lo fi han BBC.
Ms Madzhiye lati South Africa kan naa pe SCOAN lẹjọ nigba naa ni, ẹjọ ọhun ṣi wa ni kootu ni Naijiria.
‘’Awọn akọroyin kan naa gba dọla lọwọ T.B Joshua nigba yẹn’
Awọn akọroyin kan n wa si ṣọọṣi SCOAN lẹyin iṣẹlẹ naa ti wọn n gbowo lati bo ododo mọlẹ, gẹgẹ bi Chloe, to ṣiṣẹ lẹka iroyin ṣọọṣi naa ṣe sọ fun BBC.
‘’A maa n ri awọn akọroyin ti wọn maa n wa, bi wọn ba n lọ, pẹlu apo iwe to kun fowo dọla ni’’
Akọroyin Naijiria kan, Nicholas Ibekwe, dọgbọn gba ohun T.B Joshua silẹ lori foonu, a si gbọ ti pasitọ naa n sọ fun un pe ki lo ku too tun fẹẹ kọ bayii o’’ Eyi jẹ lẹyin to ti fun awọn akọroyin kan lowo.
‘T.B Joshua dawọ bo gbogbo iṣẹ ibi rẹ mọlẹ, o fowo ra wọn pa’
‘’Gbogbo iṣẹ ibi rẹ dawọ bo mọlẹ, o fowo ra gbogbo eto pa’’ Bẹẹ ni Emmanuel wi
Ọdun 2021 ni T.B Joshua ku lẹni ọdun mẹtadinlọgọta (57)
‘Wọn ko ṣẹṣẹ maa sọrọ aburu nipa T.B Joshua, ahesọ ni- Awọn alakooso ijọ naa bayii’
BBC kan sawọn alakooso SCOAN lasiko yii lati sọrọ lori iwadii wa, ṣugbọn wọn ni ahesọ ni gbogbo ẹ.
Wọn ni oni kọ ni wọn ti n sọ ohun ti ko ri bẹẹ nipa baba awọn ninu Oluwa.















