Ilé-ẹjọ́ pàṣẹ pé kí ìjọba san N100m fún Emefiele fún títẹ ẹ̀tọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, GODWIN EMEFIELE/TWITTER
Ileẹjọ giga kan niluu Abuja ti pàṣẹ pe ki ijọba apapọ san ọgọrun un naira fun gomina banki apapọ Naijiria, CBN tẹlẹ ri, Godwin Emefiele fun títẹ ẹ̀tọ́ rẹ mọlẹ.
Ileẹjọ sọ pe bi wọn ṣe fi Emefiele si ahamọ lai gbe e lọ sile ẹjọ tako ẹtọ ọmọniyan rẹ.
Ninu idajọ rẹ, adajọ Kayode Adeniyi fofin de ijọba apapọ lati mu Emefiele pada tabi tun fi i si ahamọ lai gbaṣẹ nile ẹjọ.
Idajọ yii waye lẹyin ti gomina banki apapọ Naijiria tẹlẹ pe ẹjọ lori bi ajọ DSS ṣe sọ ọ si atimole.
Biliọnu kan naira ni Emefiele beere fun gẹgẹ bi owo gba mabinu, o si tun rọ ileẹjọ lati fofin de ijọba pe ko gbọdọ̀ mu oun mọ.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ajọ EFCC, Dele Oyewale ti fi aidunnu rẹ han si idajọ ileẹjọ ọhun.
Ọgbẹni Oyewale sọ pe ajọ EFCC yoo pe ẹjọ kotemilorun lori idajọ naa.
O ṣalaye pe ajọ EFCC gba aṣẹ ileẹjọ lati fi Emefiele si ahamọ.
Oyewale ni ajọ naa yoo morile ileẹjọ bayii lati yii idajọ naa danu.












