Àjọ NCC fi òfin de àwọn tó ń lo nọ́mbà GLO láti má le pe MTN tàbí gba ìpè láti ibẹ̀

Ami idanimọ MTN ati GLO

Oríṣun àwòrán, Other

O ṣe é ṣe ki awọn ọmọ Naijiria to n lo oju opo ibanisọrọ Globacom (Glo), ma le pe awọn to n lo MTN mọ.

Eyi ko ṣeyin bi ajọ to n mojuto ibaraẹnisọrọ ni Naijiria, Nigeria Communications Commission, NCC, ṣe fi ofin de awọn onibara Glo.

Ninu atẹjade kan ti oludari ẹka ikede ninu ajọ NCC, Ọgbẹni Reuben Muoka, fi sita lọjọ Ajé, ni wọn ti sọ pe ileeṣẹ Glo jẹ MTN ni gbese owo to yẹ ko san lori iru ipe bẹẹ.

Owo naa ti awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ ma n san fun ara wọn ni wọn n pe ni interconnection charges.

Ọgbẹni Muoka sọ pe NCC ti fi ọwọ si i pe ki wọn o ja oju opo to so Glo pọ mọ MTN Nigeria, kuro fun igba diẹ.

O ni awọn fi to Globacom leti nigba ti MTN kọ iwe lati beere fun jija a kuro.

"A si fun wọn ni anfaani lati sọ ti ẹnu wọn.

" A ṣe ayẹwo awọn idi ti Globacom fi jẹ MTN ni gbese, a si ri i pe Globacom ko ni idi kankan to ni itumọ tabi ni awijare lati ma san owo oju opo to so wọn pọ."

NCC ti wa sọ pe awọn ti fun Globacom ni gbedeke ọjọ mẹwaa, bẹrẹ lati ọjọ kẹjọ, oṣu Kinni, ọdun 2024.

"Ti ọjọ mẹwaa yii ba pe, awọn to n lo Globacom ko nii le pe awọn to n lo MTN tabi gba ipe lati ori MTN."

Ajọ naa sọ pe igbesẹ oun wa ni ibamu pẹlu abala kẹsan-an ofin ọdun 2012 to nii ṣe pẹlu jija ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ kuro loju opo.

Sugbọn ofin yii ko nipa lori ipe lati nọmba Glo kan si òmíràn.

Ikede ti NCC fi sita

Oríṣun àwòrán, NCC

Àkọlé àwòrán, Ikede ti NCC fi sita