Kíni Debbie ṣe gan an tí NNPC àtàwọn míì ṣe ń fi ẹ̀bùn ta á lọ́rẹ lórí ìtàkùn ayélujára X?

Aworan Debbie

Oríṣun àwòrán, Debbie/X

Ọna ti Eleduwa fi n ṣiṣẹ rẹ ko si ẹni to ye.

Bayii ni ọrọ ṣe ri pẹlu ọmọbinrin kan, Debbie ti awọn eeyan lori itakun agbaye X ṣadeedee ta a lọrẹ pẹlu oriṣiiriiṣi ẹbun.

Ohun to sẹlẹ ni pe Debbie sọrọ loju opo X rẹ pe ago marun-un idaji ku iseju mẹwaa loun maa ti n ji lati dana ounjẹ fun ọkọ oun.

O ni oun bẹrẹ si ni ṣe bẹẹ lẹyin ti ọkọ rẹ sọ fun un pe ṣibi meji ni akẹgbẹ oun mu wa nibi iṣẹ ki awọn lẹ jọ jẹ ounjẹ to gbe wa.

Ọrọ yii bẹrẹ si ni mi ori ayelujara X titi.

Awọn kan n bu Debbie pe iwa agọ ni ki o maa ji dana fun ọkọ rẹ.

Bakan naa ni awọn mii gbe osuba fun Debbie pe aya rere lọọdẹ ọkọ ni i ṣe.

Eyi lo mu ki ileeṣẹ epo rọbi orilẹ ede Naijiria kede pe awọn fun Debbie ati ọkọ rẹ ni ẹbùn epo bentiroolu ₦200,000.

Wọn ọrọ irin-ajo ifẹ oun ati ọkọ jẹ nkan iwuri fáwọn.

Ileeṣẹ to n ṣe foonu, Infinix naa kede awọn fi foonu ti Infinix ṣẹṣẹ ṣe eyun nu Infinix Hot 40 da Debbie ati ọkọ lọla.

Ẹlomiran tun fun wọn ni ẹrọ kọmputa ki ọkọ Debbie le maa fi ṣe iṣẹ imọ ẹrọ ti o ni o wu oun lati ṣe

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2