Ìyàwó kejì rán agbanipa sí ọ̀rẹ́bìnrin ọkọ rẹ̀ ní Ilorin

Àwòrán àwọn tó fẹ́ pa ara wọn

Oríṣun àwòrán, Others

Ewu ina ki i pa awodi, awodi o ku ewu” lorin to gba ẹnu obinrin kan, Iṣọla Afusat Alagbẹdẹ, lasiko yii.

Eyi ko sẹyin bi Ọlọrun ṣe ko Afusat yọ lọwọ iku ojiji lọjọru, ọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni ọdun 2024 nigba ti afurasi kan, Alaja Iyabọ Oníwàrà ran agbanipa ko lọ yinbọn pa a fẹsun pe o n fẹ ọkọ oun.

Ni agbegbe Laduba, ijọba ibilẹ iwọ oorun Ilorin, ipinlẹ Kwara ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Lọjọbọ, ọjọ Kẹrin oṣu Kiini ni Iṣọla Afusat ṣalaye pe lootọ ni ọkọ rẹ pe oun fẹ fẹ oun amọ oun ko kọkọ dahun.

“Ṣugbọn nigba to n da mi laamu ni mo gba fun un, ọkọ mi kuku ti ku tẹlẹ, emi ni mo si n da gbọ bukata awọn ọmọ bii marun-un ti mo bi fun un ko to ku.

"Lọjọ kan ni Alaaja Iyabọ Oniwara , to n gbe lagboole Ọlọ́kà, lagbegbe Ogidi, niluu Ilọrin, pe mi lori ago pe ki ni mo n wa pẹlu Alaaji ọkọ oun, o ni ti mi o ba dẹyin lẹyin ọkọ oun, oun ko bimọ buruku ṣugbọn oun ni awọn ọmọ buruku toun yoo ran si mi.

"Emi naa sọ fun Alaaji ko maa pe mi mọ nitori pe iyawo rẹ n dunkoko mọ mi.”

O ṣalaye pe nigba to ya awọn kan bẹrẹ si ni fi nọmba ajeji pe oun ti wọn n dunkoko mọ ẹmi oun ati pe wọn fẹ gba ẹmi lọrun oun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

“Wọn pe mi laarọ ọjọ kan, ti wọn si ni "wo o, ori lo ko ẹ yọ, mo n wo ẹ to gbọmọ lọwọ, mi o ba ti fibọn yanju ẹ danu, ṣe o mọ pe Alaaji ni iyawo atawọn ọmọ rẹ ni to fi n tẹle kiri" ti wọn si ni ti mi o ba fi Alaaji silẹ awọn yoo pa mi.

"Ni alẹ ọjọru, lasiko ti mo n kirun lọwọ ni afurasi agbanipa kan Lateef, de to si n beere pe ṣe ẹyin ni wọn n pe ni iya ibeji? Mo dahun pe emi ni.

“O ni ki n ka tẹle oun pe oun ni oore kan ti oun fẹ ṣe mi, mo sọ fun un pe mi o le lọ sibi kankan, o si oju ẹ o ni ṣe mo mọ oun, mo ni rara, nigba to ni ki n tẹle oun pẹlu tulaasi ni mo pariwo ole, ole, tawọn aladugbo fi mu un.

"Nigba tọwọ tẹ afurasi naa, ni wọn ba ibọn ilewọ kekere kan lapo rẹ, to si jẹ wọ pe Alaaja Iyabọ Oníwàrà, lo ran oun lati wa pa mi nitori ti mo n fẹ ọkọ rẹ.

O rọ gbogbo ọmọ Naijiria, ati ijọba Kwara, ki wọn ṣaanu oun ati awọn ọmọ oun ki wọn maa jẹ ki Alaaja Iyabọ ran oun atawọn ọmọ oun lọ sọrun ojiji.

O ni ọrọ naa ti wa ni agọ ọlọpaa nitori pe wọn ti mu afurasi agbanipa Lateef lọ ṣugbọn Alaaja Iyabọ ti sa lọ bayii.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ti ńdọdẹ Alaja Iyabo

Awọn adari agbegbe Laduba fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, wọn ni pẹlu igbiyanju awọn lọwọ ṣe tẹ afurasi Lateef, tawọn si ti fa a le ọlọpaa lọwọ ṣugbọn Alaaja Iyabọ ti di ẹni tawọn ọlọpaa n wa bayii.

Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori ẹrọ ibanisọrọ lọjọ kẹfa, osu Kiini ọdun 2024.

O ni iwadii ti ileesẹ ọlọpaa ṣe fi han pe, Alaaja Iyabọ Oniwara jẹ iyawo keji ti ọkọ rẹ si n gbiyanju lati fẹ iyawo kẹta.

O salaye pe, igbiyanju yii lo fa ibadọrẹ oun ati Isọla Afusat ko to di pe Alaaja Iyabọ n lepa ẹmi rẹ gẹgẹ bi ijewọ ti afurasi agbanipa naa ṣe.

O ni Alaaja Iyabọ ti na papa bora, awọn o si dẹkun lati rii pe ọwọ tẹ ẹ.

Bakan naa lo fi kun pe Kọmiṣọna ọlọpaa Kwara ti ni ki awọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka to n ri si iwa ọdaran fun iwadii to peye.