Mọ̀lẹ́bí ń bẹ̀bẹ̀ ìrànwọ́ ₦‎60m láti dóòlà bàbá àti ọmọ rẹ̀ mẹ́fà l'áhàmọ́ ajínigbé

Sheriffdeen Al-Kadriyar

Oríṣun àwòrán, Sheriffdeen Al-Kadriyar

Awọn mọlẹbi Alhaji Mansoor Al Kadriyar ti adugbo Okekere niluu Ilorin ti ke gbajare iranwọ owo idoola lati fi gba ọmọ iya wọn tawọn ajinigbe ji gbe lọ niluu Abuja.

Mansoor Kadriyar nikan kọ ni awọn alaburu yi gbe salọ bi kii ṣe pe wọn gbe awọn ọmọ rẹ pẹlu.

Sheriffdeen Al-Kadriyar to jẹ aburo ẹni ti wọn jigbe lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba.

O ni inu aibalẹ ọkan l'awọn wa lati igba ti iṣẹlẹ yi ti waye.

Sheriffdeen fi ọrọ gbajare sita loju opo ayelujara to si ni gbogbo mọlẹbi lo fọwọ si k'awọn baa le ribi ko ọgọta miliọnu t'awọn ajinigbe beere jọ.

Bi ìṣẹlẹ naa ṣe waye ree

Sheriffdeen salaye pe lọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ Keji oṣù kini 2024 ni awọn ajinigbe yi yabo ile ẹgbọn rẹ to wa ni adugbo Bwari ni Abuja.

O ni gẹgẹ bi awọn ṣe gbọ, awọn ajinigbe yi ti wọn to mẹwàá da ibọn bolẹ ti wọn si wọle to Alhaji Mansoor Al- Kadriyar ati awọn idile rẹ.

"Daddy ati awọn ọmọ lo wa ninu parlour ti mama wọn si wa ninu iyara"

Sheriffdeen sọ pe inu iyara yi lọ fun mama awọn ọmọ lanfaani lati pe eeyan kan ni tosi lori ago lati wa doola wọn.

"Iyawo Alhaji ni wọn pe aburo wọn ti wọn n gbe ni itosi adugbo wa ti wọn si sare lọ si agọ ọlọpaa nitosi."

Orukọ ẹni ti o jẹ aburo Alhaji Mansoor yi ni Abdulfatah Oladayo Al-Kadriyar.

Ati Abdulfatah ati awọn ọlọpaa ni wọn tara wa lati wa doola awọn mọlẹbi Al- Kadriyar lọwọ awọn ajinigbe ṣugbọn wahala bẹ silẹ nigba ti wọn de ibẹ.

Aworan Abdulfatah Al- Kadriyar

Oríṣun àwòrán, Sheriffdeen Al- Kadriyar

Awọn agbebọn yinbọn pa aburo to wa doola ẹgbọn

Ka to diju ka to laa, awọn ajinigbe yi sina ibọn bolẹ ti wọn si yìnbọn lu Abdulfatah Al- Kadriyar to wa pẹlu awọn ọlọpaa lati doola ẹgbọn rẹ.

Sheriffdeen salaye pe "wọn sọ fun wa pe awọn ajinigbe yi da ibọn bolẹ ti ẹgbọn wa Abdulfatah si faragbọta pẹlu awọn ọlọpaa meji tabi mẹta"

O tẹsiwaju pe awọn alaburu yi pada ribi sa lọ ti wọn si gbe Alhaji Mansoor ati awọn ọmọ mẹfa sálọ.

Amọ o sẹni laanu pe Abdullah to jẹ aburo to gbiyanju didoola ẹgbọn padanu ẹmi rẹ mọjumọ Ọjọru tii ṣe ọjọ kẹta osu Kini.

Ibanujẹ di meji awọn ajinigbe tun fariga pe ₦60m lawọn o gba

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nibi ti mọlẹbi ti n banujẹ awọn ti wọn jigbe ati ẹni to padanu ẹmi rẹ la ti gburo nkan to ṣẹlẹ ti iroyin rẹ sì gba oju opo ayelujara kan.

Nigba taa fi ribi ba Sheriffdeen sọrọ, o ni awọn ti gburo pe awọn ajinigbe ti tu baba awọn ọmọ yi silẹ ṣugbọn wọn láwọn yoo gba owo idoola ọgọta miliọnu ki awọn ọmọ to le gba itusilẹ.

" ₦10m ni wọn ni ka muwa ki wọn to le tu awọn ọmọ yi silẹ. A ko mọ ibi taa ti ri owo yi.A padanu ọmọ iya wa wọn si tun ni ka mu owo wa lati fi tu awọn ọmọ silẹ "

Lọwọ lọwọ Sheriffdeen sọ pe gbogbo ẹbi lo panupọ pe ki awọn fi ọrọ gbajare sita lati le fi ri owo ti awọn ajinigbe n beere yi.

Nigba taa beere pe ki ni ipa awọn ọlọpaa lori ọrọ yi o sọ pe wọn n gbiyanju ṣugbọn awọn ko le gbẹnu sọ fún wọn.

"Kọmisana ọlọpaa n kan sí awọn eeyan wa ni Abuja ti wọn si fi wá lọkàn balẹ pe wọn yoo ribi doola awọn to wa ni akata awọn ajinigbe. Mi o le sọ ju bayii lọ"

BBC Yoruba pe Agbẹnusọ ọlọpaa Naijiria Muyiwa Adejobi ṣugbọn ko gbe ipe rẹ.

Bẹẹ naa ni a ko gbọ esi lọdọ alukoro ọlọpaa Abuja Dsp Josephine Adeh lati le mọ ibi ọrọ de duro.

Ìṣẹlẹ ijinigbe jẹ ohun ipaya fún ọpọ lorileede Naijiria ti ko sí jọ pe ipa awọn agbofinro ka awọn alaburu ti ko fi ijinigbe mọ lori agbalagba nikan.