Àwọn agbébọn ṣekúpa èèyàn mẹ́wàá ní Zamfara

Ikọ awọn agbebọn ti sekọlu si agbegbe Kwanar Dutse ni Dansadau ni ijọba ibilẹ Maru nipinlẹ Zamfara, ti wọn si gbẹmi eeyan mẹwaa.
Isẹlẹ naa waye ni alẹ Ọjọru, Ọjọ kẹta oṣu kinni ọdun 2024.
Awọn olugbe agbegbe naa ni awọn agbebọn naa yabo ni alẹ nitori wọn kọ lati san owo kan to jẹ ogun milọnu naira ti wọn mu ni tipatipa fun lati san.
Isẹlẹ ijinigbe ati ikọlu awọn agbebọn ni o ti di ohun lemọlemọ to n waye lorekore nipinlẹ Zamafara.
Oṣeojumikoro to ba BBC sọrọ ni awọn wa nibi ti awọn ti n se karakata nigba ti awọn agbegbọn naa de, ti wọn si n sadede gbọ oro ibọn.
“Gbogbo wa bẹrẹ si ni ma sare, ti wọn bẹrẹ si ni ma yin bọn.”
Ẹlomiiran sọ fun BBC pe o le ni aadọta eeyan to wa ni akata awọn agbebọn naa bayii.
Bakan naa, agbẹnusọ ijọba ipinlẹ Zamfara, Sulaiman Bala Idris ni ayipada nla ti wa nipinlẹ Zamfara ju ti atẹyin lọ.
“Ohun iyalẹnu lo jẹ fun mi pe awọn eeyan ko sọ nipa aṣeyọri ijọba .
“Nitori ni ọdun to kọja, ọpọ awọn agbebọn yii ni wọn pade iku wọn..”
Ninu oṣu kọkanla ọdun to kọja, awọn agbebọn ji eeyan to le ọgọrun gbe paapa awọn obinrin ati ọmọde lọ sinu igbo.
Àwọn afurasí Boko Haram ṣekúpa èèyàn méjìlá ní Chibok

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn afurasi ẹgbẹ agbesunmomi Boko Haram ni iroyin kan sọ pe wọn ti ṣekupa eeyan mejila ni abule Tsiha ati Gatarmarwa ni ijọba ibilẹ Chibok nipinlẹ Borno.
Awọn araalu sọ fun iwe iroyin Daily Trust pe niṣe l'awọn janduku agbebọn ọhun ti wọn wọ aṣọ ologun da ibọn bo'lẹ nigba ti wọn wọ awọn abule yii eleyii to jẹ ki eeyan mejila di oloogbe.
Bakan naa ni wọn sọ pe awọn afurasí Boko Haram ọhun tun ji ẹnikan gbe lọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Borno ṣalaye pe awọn ti ri oku awọn eeyan to gbẹmi mi ninu ikọlu naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọjọ Aje ọjọ kinni oṣu Kinni ọdun 2024 yii ni iṣẹlẹ naa waye.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Nahum Daso ṣalaye pe eeyan meji lo f'arapa ninu ikọlu ọhun yatọ si awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.
Daso sọ lori ileeṣẹ tẹlifisan Channels pe ọkọ Hilux at'awọn ọkọda l'awọn agbebọn naa ti wọn pọ gun wọ ilu mejeeji ti wọn ti ṣọṣẹ.
Awọn araalu ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ni bii ago marun-un irọlẹ l'awọn agbebọn ọhun yabo abule Gatarmarwa pẹlu orisiirisii ibọn AK-47 lọwọ wọn ti wọn ṣí bẹrẹ si ni yin bọn fawọn to n bọ lati ibi isinku ni Gatarmarwa.
Wọn ni lẹyin ti wọn kuro ni Gatarmarwa ni wọn morile abule Tsiha nibi ti wọn ti pa eeyan mẹta ti wọn si tun dana sun ọpọlọpọ ile.
Koda, wọn ni àwọn agbebọn naa tun ji ounjẹ gbe lọ.
Ni nkan bi oṣu kan sẹyìn ni a gbọ pe awọn agbesunmomi ba opo ina nla mẹrin ọtọtọ jẹ lopopona Damaturu si ilu Maiduguri tii ṣe olu ilu ipinlẹ Borno lẹyin oṣu mọkanla ti ijọba ṣe atunṣe rẹ.
Awọn agbesunmọmi alakatakiti ẹsin yii ti ṣe ikọlu s'awọn ẹkun miran ni Naijiria ni bii ọdun meji sẹyin bayii yatọ si ipinlẹ Borno to jẹ ibi ti wọn fi ṣe ibugbe.
Ajọ iṣọkan agbaye fidi rẹ mulẹ pe awọn agbesunmọmi alakatakiti ẹsin ti ṣekupa ẹgbẹrun l'ọna ogoji eeyan nigba ti miliọnu meji ti di alainile lori lati ọdun 2009 ti wọn ti bẹrẹ si ni ṣọṣẹ lẹkun ila-oorun ariwa orilẹ ede Naijiria.















