Aó dà á bíbuwọ́ lu ìwé ẹ̀rí fásitì láti Kenya, Uganda àti Niger dúró - Ìjọba àpapọ̀

Awọn akẹkọọ fasiti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lẹyin ti ijọba apapọ kede pe awọn ti fi ofin de iwe ẹri awọn fasiti lati orilẹede Benin ati Togo, wọn tun jẹ ko di mimọ pe igbesẹ naa yoo na ọwọ aṣẹ maa de awọn orilẹede mii bi Kenya, Uganda ati Niger Republic.

Minisita fun eto ẹkọ lorilẹede Naijiria, Tahir Mamman lo sọ eyi lasiko to n sọrọ lori eto kan ni Channels TV l'Ọjọbọ.

“A ko duro lori Benin ati Togo nikan,

“A tun tẹsiwaju lati fofin de awọn orilẹede bi Uganda, Kenya ati Niger nibi ti iwa yii ti wọpọ."

Mamman ni awọn akẹkọọ to n lọ awọn ile ẹkọ yii ko yatọ si ọdaran.

“Anu ko se awọn akẹkọọ yii, wọn lara awọn ọdaran ti o yẹ ki a fi ọlọpaa gbe.”

O fikun pe awọn ẹṣọ abọ yoo bẹrẹ si ni matọ pinpin awọn alagbata to n pese ayederu iwe ẹri lati awọn fasiti oke okun yii.

Wo fásitì 58 tí ìjọba tún fi òfin dè ní Naijiria nítorí àìkójú òsùnwọ̀n

Awọn akẹkọọ fasiti

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ National Universities Commission ni Naijiria ti fi ibẹrẹ ọdun tuntun 2024 yii mu ti awọn ileewe giga ti wọn ko kunju oṣuwọn gbọ, o si ti fofin de mejinlọgọta (58) ninu wọn.

Ikede naa waye lati ẹnu minisita fun eto ẹkọ ni Naijiria, lasiko to kopa lori eto kan nileeṣẹ amohunmaworan Channels, lowurọ Ọjọbọ.

Lati ọsẹ to kọja ni awuyewuye ti n waye lẹyin ti akọroyin kan tu aṣiri bo sẹ gba iwe ẹri fasiti laarin oṣu meji pere, lati ile ẹkọ kan ni orilẹ-ede Benin Republic.

Awọn ileewe giga ti wọn ni kẹnikẹni ma ya sibẹ kawe tabi gba iwe-ẹri, nitori sabukeeti ibẹ ko ni i ṣee fi ṣiṣẹ, kawe si i tabi sinru ilu naa ree lẹsẹẹsẹ:

  • University of Accountancy and Management Studies, nibilkibi ti wọn ba wa ni Naijiria .
  • Christians of Charity American University of Science & Technology to wa ni Nkpor, nipinlẹ Anambra ati nibi yoowu ti wọn ba tun wa ni Naijiria.
  • University of Industry to wa ni Yaba, l’Ekoo abi nibo mi-in ti wọn ba tun wa.
  • University of Applied Sciences & Management to wa ni Port Novo ateyi to wa ni marosẹ Eko s’Ibadan, t’Ikorodu Road, ti Benin atawọn yooku wọn ni Naijiria.
  • Blacksmith University, Awka atawọn ibi yoowu ki wọn wa ni Naijiria.
  • 6. Volta University College, Ho, Volta Region, Ghana atawọn ẹka wọn ni Naijiria.
  • Royal University Izhia, P.O. Box 800, Abakaliki, nipinlẹ Ebonyi atawọn ẹka wọn yooku.
  • Atlanta University to wa ni Anyigba, ni Kogi atawọn ẹka wọn mi-in.
  • United Christian University, Macotis Campus to wa nipinlẹ Imo atawọn ẹka wọn mi-in.
  • United Nigeria University College, Okija, l’Anambra atawọn ẹka wọn gbogbo ni Naijiria.
  • Samuel Ahmadu University, Makurdi, ni Benue atawọn ẹka rẹ gbogbo.
  • UNESCO University, Ndoni, nipinlẹ Rivers atawọn ẹka rẹ.
  • Saint Augustine’s University of Technology, Jos, ipinlẹ Plateau atawọn ẹka rẹ.
  • Di International University, Missouri, USA, Kano ati Lagos International Professional College of Administration, Science and Study Centres, abi ẹka wọn yoowu ni Naijiria.
  • Collumbus University, UK , nibi yoowu ti wọn wa ni Naijiria, ayederu ni.
  • Tiu International University, UK, nibi yoowu ti wọn wa ni Naijiria, ayederu ni.
  • Pebbles University, UK,nibi yoowu ni Naijiria, ayederu ni.
  • London External Studies UK to n kọ wọn niwee ni Naijiria, irọ ni.
  • Pilgrims University nibikibi ni Naijiria.
  • Lobi Business School Makurdi, ipinlẹ Benue ati nibikibi ti wọn wa ni Naijiria.
  • West African Christian University nibikibi ni Naijiria.
  • Bolta University College, Aba ati nibikibi ni Naijiria .
  • JBC Seminary Inc. (Wukari Jubilee University) ni Kaduna, ayederu .
  • Westlan University, Esie, ni Kwara State abi nibikibi tileewe naa ba ti n kọ awọn eeyan niwee ni Naijiria.
  • St. Andrews University College, Abuja abi ẹka wọn yoowu ni Naijiria.
  • EC-Council University, USA, ẹka Ikeja, l’Ekoo.
  • Atlas University, Ikot Udoso Uko, Uyo,nipinlẹ Akwa Ibom abi eyikeyi ẹka wọn lorilẹ-ede yii, arumọjẹ ni.
  • Concept College/Universities (London), Ilọrin abi eyikeyi ẹka wọn ni Naijiria, ofege ni.
  • Halifax Gateway University, Ikẹja abi ẹka wọn yoowu ko jẹ ni Naijiria.
  • Kingdom of Christ University, Abuja abi ẹka wọn yoowu ko jẹ.
  • Acada University, Akinlalu, nipinlẹ Ọyo abi ẹka wọn eyikeyi ni Naijiria.
  • Fifom University, Mbaise, ipinlẹ Imo abi ẹka wọn yoowu ni Naijiria. .
  • Gbogbo ẹka Houdegbe North American University ni Naijiria.
  • Atlantic Intercontinental University, Okija, l’Anambra.
  • Open International University, Akurẹ
  • Middle Belt University (North Central University), Otukpo nipinlẹ Benue.
  • Leadway University, Ughelli, ni Delta.
  • Metro University, Dutse/Bwari, Abuja
  • Southend University, Ngwuro Egeru (Afam) Ndoki, ipinlẹ Rivers.
  • Olympic University, Nsukka, ipinlẹ Enugu.
  • Federal College of Complementary and Alternative Medicine,Abuja.
  • Temple University, Abuja.
  • Irish University Business School London, tawọn eeyan n kẹkọọ lẹka wọn nibikibi ni Naijiria.
  • National University of Technology, Lafia, ipinlẹ Nasarawa.
  • University of Accountancy and Management Studies, Mowe, ipinlẹ Ogun.
  • University of Education, Winneba Ghana,ti wọn n kẹkọọ nibẹ ni Naijiria.
  • Cape Coast University, Ghana, nibikibi ni Naijiria, ofege ni.
  • African University Cooperative Development (AUCD), Cotonou, ẹka wọn yoowu ni Benin ati nibikibi ni Naijiria.
  • Pacific Western University, Denver, Colorado to lẹka l’Owerri, ipinlẹ Imo.
  • Evangel University of America & Chudick Management ati ẹka wọn gbogbo ni Naijiria.
  • Enugu State University of Science and Technology, Gboko abi ẹka wọn yoowu
  • Career Light Resources Centre, Jos.
  • University of West Africa, Kwali-Abuja.
  • Coastal University, Iba-Oku, ipinlẹ Akwa-Ibom.
  • Kaduna Business School, Kaduna.
  • Royal University of Theology, Minna, ipinlẹ Niger.
  • West African Union University pẹlu ajọṣepọ International Professional College of Administration, Science and Technology Nigeria, nibikibi ti wọn wa ni Naijiria.
  • Gospel Missionary Foundation (GMF), Theological University. 165 Iselo Road, Cele bus stop, Egbe-Ikotun, nipinlẹ Eko.

Awọn ti wọn ṣi n ṣewadii wọn lọwọ fun jijẹ ayederu tun ree

1) National University of Nigeria, Keffi, nipinlẹ Nasarawa.

2) North Central University, Otukpo, ni Benue.

3) Christ Alive Christian Seminary and University, ipinlẹ Enugu.

4) Richmond Open University, Arochukwu, ipinlẹ Abia.

5) West Coast University, Umuahia.

6) Saint Clements University, Iyin Ekiti, ipinlẹ Ekiti.

7) Volta University College, Aba, ipinlẹ Abia.

8) Pẹlu awọn ibudo ikawe Ambrose Alli ti ko bofin mu ti wọn wa kaakiri.

Fasiti mejidinlogun ti ijọba kọkọ kede

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ Ìṣegun, ọjọ keji, ọdun 2024 ni ijọba Naijiria kede pe oun da bibuwọ lu iwe ẹri lati awọn fasiti orile-ede Benin Republic ati Togo.

Ìjọba fi ẹsun kan wọn pe wọn n ṣe magomago asiko ikawe, ti wọn si n kopa ninu eto agunbanirọ lai jẹ pe awọn akẹkọo lo ọdun to yẹ ki wọn to fun wọn ni iwe ẹri. Eyi si ti mu ki wọn o fi ofin de awọn fasiti kan to ni ẹka ni Naijiria. Eyi si ni awọn fasiti ti ijọba fofin de ni Naijiria

1. University of Applied Sciences and Management, Port Novo, Republic of Benin, pẹlu awọn ẹka wọn lorilẹ-ede Naijiria.

2. Volta University College, Ho, Volta Region, Ghana, ati awọn ẹka wọn ni Naijiria.

3. The International University, Missouri, USA, Kano ati Eko atawọn ibi yoowu ti wọn ba tun lẹka si ni Naijiria.

4. Collumbus University, UK, ati nibi yoowu ti wọn ba ti n kọ awọn eeyan niwee ni Naijiria.

5. Tiu International University, UK ati nibikibi ti wọn ba ti n kọ awọn eeyan niwee ni Naijiria.

6. Pebbles University, UK ati ti Naijiria.

7. London External Studies UK, ati ni Naijiria.

8. Pilgrims University, nibikibi ti wọn ba nileewe si ni Naijiria.

9. West African Christian University,nibikibi ti wọn ba ni ileewe si ni Naijiria.

10. EC-Council University, USA, ateyi to wa n’Ikẹja, niluu Eko.

11. Concept College/Universities (London), Ilorin ati awọn ẹka wọn yooku ni Naijiria.

12.Gbogbo ẹka Houdegbe North American University ni Naijiria.

13. Irish University Business School London, ati gbogbo awọn ẹka wọn ni Naijiria.

14. University of Education, Winneba, Ghana ati nibi gbogbo ti wọn ti nileewe ni Naijiria.

15. Cape Coast University, Ghana, nibi gbogbo ti wọn ti n kẹkọọ ni Naijiria.

16. African University Cooperative Development, Cotonou, Benin Republic ati nibi gbogbo tileewe naa wa ni Naijiria.

17. Pacific Western University, Denver, Colorado, ẹka rẹ to wa l’Owerri, ni Naijiria

18. Evangel University of America and Chudick Management Academic niluu Eko.

Ìdí tí ìjọba Naijiria fi dá bíbuwọ́ lu ìwé ẹ̀rí fásitì láti Benin Republic àti Togo dúró

Ijọba orilẹ-ede Naijiria ti da eto ṣiṣe agbeyẹwo ati bibuwọlu awọn iwe ẹri fasiti to wa lati orilẹ-ede Benin ati Togo.

Ileeṣẹ eto ẹkọ ni Naijiria kede idaduro naa ninu atẹjade kan ti wọn fi sita ni ọjọ Iṣẹgun. ọjọ keji, oṣu Kinni, ọ̀un 2024.

Adele oludari fun ikede nileeṣẹ naa, Augustina Obilor-Duru, to buwọlu atẹjade naa sọ pe igbesẹ ọhun jẹ dandan lẹyin iwadii ikọkọ kan ti akọroyin kan ṣe lati wadii bi awọn eeyan ṣe n gba iwe ẹri fasiti to yẹ ko gba akẹkọọ ni ọdun mẹrin, laarin ọsẹ mẹfa pere ni awọn orilẹ-ede ti ọrọ kan.

O ni abọ iṣẹ iwadii naa ti akọroyin ileeṣẹ iwe iroyin Daily Nigerian ṣe, ti wọn si gbe jade ni ọgbọnjọ, oṣu Kejila, ọdun 2023, “jẹ ifidi mulẹ bi ara ṣe ti n fu awọn eeyan kan pe awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan n gba ọna ẹburu lati gba iwe ẹri pẹlu afojusun lati ri iṣẹ ti wọn o koju osunwọn fun”.

Akọroyin naa dibọn bi ẹni to fẹ ẹ wọ ile ẹkọ fasiti ni orilẹ-ede Benin Republic, eyi to mu ko kàn si awọn eeyan kan to ma n ba ni ṣeto kara-kata iwe ẹri fasiti.

Oṣu Kejila ọdun 2022 lo bẹrẹ igbesẹ naa, amọ iyalẹnu lo jẹ pe nigba ti yoo fi di oṣu keji, sun 2023, o ti kẹkọọ jade, ti wọn si fun ni iwe ẹri akọkọ ninu iṣẹ iroyin lati fasiti kan.

Igba wo ni aṣẹ idaduro naa yoo bẹrẹ iṣẹ?

Ileeṣẹ eto ẹkọ sọ pe ni kiakia ni aṣẹ naa bẹrẹ iṣẹ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2024, ti wọn pa a.

Wọn ni aṣẹ naa yoo wa titi ti abajade iwadii ti wọn ṣe pẹlu awọn ileeṣẹ ilẹ okeere ni awọn orilẹ-ede mejeeji, yoo fi sọ igbesẹ to kan.

“Awọn ileeṣẹ eto ẹkọ ni orilẹ-ede mejeeji, to fi mọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ati ajọ NYSC, ni yoo mojuto iwadii naa.”

Ileeṣẹ eto ẹkọ Naijiria rọ awọn araalu lati ṣe atilẹyin fun akitiyan rẹ, ki wọn si ran an lọwọ nipa pipese awọn ẹri to le ran igbimọ oluwadii lọwọ lati wa ọna abayọ ki iru nnkan bẹ o ma waye mọ.

Njẹ ofin yii yoo nipa lori awọn to fẹ sinru ilu?

Lori ipa ti igbesẹ ijọba yoo ni lara awọn akẹkọọ to ti jade ni awọn fasiti to wa ni orilẹ-ede Benin Republic ati Togo, to si fẹ sinru ilu ni Naijiria labẹ eto NYSC, agbẹnusọ fun ileeṣẹ eto ẹkọ sọ fun BBC pe igbimọ to n mojuto ọrọ awọn akẹkọọjade ni yoo ṣe iwadii boya iru awọn akẹkọọ bẹẹ wa nilẹ ni bayii ti ofin tuntun bẹrẹ isẹ.

Ọgbẹni Benjamin Gong sọ pe ofin Naijiria fi aaye gba awọn ileeṣẹ lati da ẹnikẹni ti aṣiri rẹ ba tu pe o fi ayederu iwe ẹri gba iṣẹ.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe, o yẹ ki akẹkọọ kankan to ba fẹ lọ kawe nilẹ okeere, lọ si ileeṣẹ eto ẹkọ lati mọ boya ojulowo tabi ayederu ni iru fasiti bẹẹ - boya ijọba fọwọ si i, tabi boya iru eto ẹkọ wọn wa nibẹ.

“Asiko ti wọn ba fẹ sinru ilu, ni wọn to ma n wa si ileeṣẹ eto ẹkọ, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.”