Àbúrò ṣá ẹ̀gbọ́n pa nítorí ó fẹ́ ní ìbálòpọ̀ akọ sí akọ pẹ̀lú rẹ̀ nípìnlẹ̀ Ogun

Ẹnikan to n pọn ada fun iṣẹ oko

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Afurasi kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ibrahim Salisu lo ti wa ni ahamọ Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun fun ẹsun pe o fi ada ṣa ẹgbọn rẹ, Malaimi pa nitori o n bere ibalopọ akọ si akọ lọwọ rẹ.

Isẹlẹ naa ni iroyin sọ pe o waye ni adugbo Araromi, l'agbegbe Sango-Ota ni nnkan bi ago mọkanla alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni afurasi naa, Salisu, sọ pe ẹgbọn oun, to ti di oloogbe bayii jẹ ẹni ọdun mẹrinlelaadọta, lo ti n bere ibalopọ lọwọ aburo rẹfun ọjọ pipẹ ko to di pe isẹlẹ sisa ladaa waye.

Ọlọpaa ni igbati nnkan ti oloogbe Mailami n beere kọja afarada fun afurasi, lo ba binu fa ada jade, to si gba ẹmi rẹ.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Odutola Omolola sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle, The Punch ninu ifọrọwerọ kan pe awọn ti gbe oku oloogbe naa lọ si ile igbe oku si ni ile iwosan gbogbo tri ilu Ifo fun ayẹwo.

“O jẹwọ ẹsẹ rẹ. O sọ fun awọn eeyan wa to mu pe oun ni oun sekupa ẹgbọn oun nitori o n da oun lamu fun ibalopọ akọ si akọ.

“A gbẹ ẹjọ naa lọ sia bi to yẹ lẹyin ti a ba pari iwadi wa,”