Igbákejì adarí ikọ̀ Hamas, Saleh al-Arouri jáde láyé nínú ìkọlù tó wáyé ní Beirut

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Saleh al-Arouri jẹ́ ọ̀kan lára èèkàn nínú ikọ̀ Hamas - ẹni tó jẹ́ aṣíwájú lórí ètò òṣèlú àti ikọ̀ ológun Hamas.
Saleh al-Arouri, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ọ̀hún ló jẹ́ igbákejì ikọ̀ òṣèlú Hamas, tó sì wà lára àwọn tó dá ikọ̀ ológun Izzedine al-Qassam ẹgbẹ́ náà sílẹ̀.
Ó wà lára àwọn tó fara sí ikọ̀ ológun ikọ̀ Hamas dáradára.
Níbi ìkọlù kan tó wáyé ní gúúsù Beirut ní ẹ̀bá Dahiyeh ní orílẹ̀ èdè Lebanon ni ó ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, tí àwọn kan sì ń fẹ̀sùn kan pé Israel ló wà nídìí ìkọlù náà.
Ní ọdún 1987 ni Saleh al-Arouri darapọ̀ mọ́ ikọ̀ Hamas tó sì wà lára àwọn ikọ̀ Hamas to ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Iran àti ikọ̀ Hezbollah ní Lebanon.
Ó ti fi ọ̀pọ̀ ìgbà wà ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Israel. Lẹ́yìn tó gba ìtúsílẹ̀, ó wà lára àwọn tó dúnàádúrà láti tú ẹgbẹ̀rún kan àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Palestine tó wà ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Israel.
Ètò yìí ni wọ́n fi tú ọmọ ogun Israel, Gilad Shalit sílẹ̀ lọ́dún 2011.
Ní ọjọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù Kéwàá ni àwọn ọmọ ogun Israel lọ wó ilé rẹ̀ tó wà ní West Bank ní ìlú Arura ní ẹ̀gbẹ́ Ramallah.
Orílẹ̀ èdè Lebanon ni Arouri ń gbé títí tó fi jáde láyé.
Àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn Lebanon ní ìkọlù tí àwọn ológun ṣe sí ọ́fíìsì ikọ̀ Hamas ní gúúsù Beirut ní ẹ̀bá Dahiyeh ni Arouri ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mẹ́fà mìíràn tí ìgbàgbọ́ wà pé àwọn náà jẹ́ ọmọ ikọ̀ Hamas.
Adelé olóòtú ìjọba Lebanon, Najib Mikati ní bí àwọn ọmọ ogun náà ṣe pa Arouri sí Hezbollah ti fi hàn pé Israel fẹ́ mọ̀-ọ́n-mọ̀ fẹ́ dá ti Lebanon sí ogun tí wọ́n ń gbé ti Palestine ni.
Hezbollah ní ìkọlù náà jẹ́ títẹ ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn àti ààbò ìlú àwọn mọ́lẹ̀ àti pé kò yẹ kí ìwà ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ láìsí ìjìyà kankan fun.

Oríṣun àwòrán, AFP
Pípa Saleh al-Arouri sí Beirut kìí ṣe láti fi ṣèkọlù sí Lebanon - Israel
Àmọ́ orílẹ̀ èdè Israel ní bí àwọn ṣe ṣekúpa Arouri sí Beirut kò túmọ̀ sí pé àwọn fẹ́ ṣe ìkọlù sí Lebanon.
Agbẹnusọ Israel, Mark Regev ní àwọn adarí Hamas ni àwọn fẹ́ ṣe ìkọlù àti pé ohun ló fa ikú Saleh al-Arouri.
Regev kò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Israel ló ṣe ìkọlù náà àmọ́ ó ní ẹnikẹ́ni tó bá ṣe ìkọlù náà kìí ṣe nítorí láti ṣe ìkọlù sí Lebanon tàbí sí Hezbollah gan.
Ó ní ohun tó fojú hàn ni pé ẹnikẹ́ni tó bá ṣe ìkọlù náà ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Hamas.
Arouri ni èèkàn ikọ̀ Hamas tí yóò pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ láti ìgbà tí ogun ti bẹ̀rẹ̀ láàárín Hamas àti Israel lẹ́yìn tí ikọ̀ Hamas kọ́kọ́ ṣe ìkọlù sí Israel lọ́jọ́ Keje, oṣù Kẹwàá.
Ní ọjọ́ náà ni Hamas kọlu Israel tí wọ́n sì ṣekúpa ènìyàn 1,200.
Láti ìgbà náà sì ni ìkọlù ti ń wáyé tí àwọn ènìyàn tó sì ti bá ogun lọ ní Palestine ti lé ní 22,000 tó fi mọ́ àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé.















