Ó ti pé èèyàn 48 tó ti gbẹ́mí mì nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ ríri tó wáyé ní Japan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alaṣẹ ni orilẹ-ede Japan ti fidi ẹ mulẹ pe, ogoji eeyan lo ti ku ninu iṣẹlẹ ilẹ riri to waye ni orilẹ-ede naa.
Bakan naa ni wọn sọ pe ogunlọgọ ile ni ilẹ riri naa bajẹ, ti awọn kan si jona lẹyin to waye.
Ọjọ Aje, ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2024, ni iṣẹlẹ ilẹ riri naa waye, ni awọn agbegbe to wa ni aarin gbungbun Japan.
Awọn onimọ sọ pe odinwọn ilẹ riri naa jẹ 7.6.
Ọpọ igba ni ilẹ ti mì titi lẹyin ilẹ riri to waye, lasiko ti awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi n wa awọn to ha.
Ijọba orilẹ-ede Japan sọ pe ẹgbẹrun mẹtadinlọgọta eeyan ni awọn ti ri ko kuro ni awọn agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ẹṣọ alaabo to le l'ẹgbẹrun ni wọn ti wa kaakiri agbegbe naa lati maa wa awọn to ha sabẹ ilẹ kiri, ti wọn si n gbe wọn jade.
Ohun kan to n mu ifasẹyin wa ninu iṣẹ yii ko ju ti awọn ile ati ọkọ to ti bajẹ to wa lẹba ọna kiri.
Olootu ilẹ naa, Fumio Kishida, ṣapejuwe iṣoro yii bii ogun to n ja ni ti ko si sasiko to lati koju rẹ, pẹlu bo ṣe jẹ pe gbogbo nnkan lo ti dẹnukọlẹ lorilẹ-ede naa, ti igbeaye si nira koko.
Idile to le ni ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn ni ọfọ nla ti ṣẹ bayii, bẹẹ ni wọn tun n koju iṣoro ai si nnkan amayedẹrun niluu ninu rẹ naa.
Awọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin nipa ilẹ riri to waye ni Japan
Awọn eeyan kan ti ha si abẹ alapa awọn ile to wo lulẹ, lẹyin ti ilẹ riri waye ni Japan.
Agbẹnusọ fun ijọba orilẹ-ede naa, Yoshimasa Hayashi, sọ pe ijọba ṣi n ṣe akojọpọ iye eeyan to ti farapa tabi ku ninu iṣẹlẹ naa.
O ni ṣugbọn iroyin sọ pe eeyan mẹfa lo ha si abẹ awọn ile to wo lulẹ, o ni amọ oun ko le sọ boya o pọ ju bẹẹ lọ nitori pe ile to wo lulẹ pọ.
Ọpọlọpọ ile ati opo ina lo ti wo lulẹ lẹyin ti iṣẹlẹ naa.
Ilẹ riri naa waye ni agbegbe awọn agbegbe to mule ti omi bii Noto, Toyama, ni owurọ kutu ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2024.
Awọn alaṣẹ ati ileeṣẹ amunawa sọ pe ẹgbẹrun mejilelọgbọn ile ni ko ni ina ẹlẹtiriiki bayii.
Ilẹ riri naa mu ki riru omi to ga to ẹsẹ bata mẹrin kọlu ibudokọ oju omi to wa ni Ishikawa, ni nnkan bi aago mẹrin abọ irọlẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Iṣẹlẹ naa ti mu ki awọn onimọ ni Japan fi ikilọ sita pe fun awọn eeyan to n gbe ni awọn agbegbe to wa nitosi omi, paapaa ni ẹkun Noto, ni wọn kilọ fun pe ki wọn fi agbegbe naa silẹ.
Awọn alaṣẹ kilọ pe o ṣeeṣe ki riru omi lọ soke to mita marun-un ni Noto.
Yatọ si eyi, wọn tun fi ikilọ sita fun awọn agbegbe to mule ti i, Niigata ati Toyama, pe o ṣeeṣe ki riru omi de mita mẹta.
Bakan naa ni ijọba ti da lilọ-bibọ ọkọ ojur’in duro ni awọn agbegbe kan ni orilẹ-ede naa, paapaa laarin Tokyo ati Ishikawa nibi ti ilẹ riri naa ti l’agbara ju.
O le ni igba ọgbọn ti ilẹ riri ti waye laarin wakati mẹta pere - ti iwọn wọn si wa laarin 3.6 si 7.6m, ni aarin gbungbun Japan.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ipa ilẹ riri naa fa ẹkun omi ni South Korea
Orilẹ-ede South Korea ti kede pe riru omi to l'agbara ṣẹlẹ ni awọn bebe omi to wa ni ila oorun orilẹ-ede naa lẹyin ti ilẹ riri waye ni Japan, to jẹ alamuleti rẹ.
Riru omi to to ẹsẹ bata kan ataabọ waye ni agbegbe Gangwon, gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Yonhap ṣe sọ.
Ṣaaju ni awọn alaṣẹ ti kede pe ki awọn eniyan to wa ni agbegbe naa kuro lọ si ibi ti ilẹ ti ga, nitori ibẹru pe òkun yoo kun kọja bebe rẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters












