Wo àwòrán báwọn èèyàn ṣe ń dunnú láwọn orílẹ́èdè tó ti bọ́ sínú ọdún tuntun 2024

Nigba tawọn ọmọ orilẹede Naijiria ati ọpọ orilẹede ṣi n duro di ago mejila oru oni ọjọ Aiku lati wọ ọdun tuntun 2024, orilẹede Kiribati ti wọ inu ọdun tuntun ni ti wọn.
Orilẹeede Kirimati ni o kọkọ wọ inu ọdun tuntun ninu gbogbo orilẹede to wa ni ẹkun ‘Pacific.’
Erekusu mẹtalelọgbọn ti wọn n pe ni Kiribass lo kora pọ di orilẹede Kiribati eleyii to wa ni ẹkun ‘Pacific’ to si sun mọ apa ila oorun pẹlu ẹgbẹrun mẹrin kilomita.

Orilẹede New Zealand ni orilẹede keji to ti wọ ọdun tuntun 2024
Ni bii ago mẹwaa aarọ oni ọjọ Aiku ni awọn eeyan orilẹede naa wọ inu ọdun tuntun.
Awọn eeyan dawọọ idunnu ọdun niluu Auckland lorilẹede New Zealand pẹlu banga atawọn nkan tana-tana mii.

Ero biba niluu Sydney bi wọn ti wọ ọdun tuntun 2024
Tonga ati Samoa ni o tun kan tawọn eeyan yoo ti dawọọ idunnu ọdun tuntun.
Ero biba ko ara wọn jọ niluu Sydney ni Australia nibi tawọn eeyan ti yin banga lati dawọọ idunnu ọdun tuntun.
Ni bi ago meji ọsan oni ni ọpọ eeyan duro sori afara Harbour Bridge ati ile Opera nibi ti wọn ti yin oriṣiiriṣii banga atawọn nkan iṣere mii lati dawọọ ọdun tuntun.


‘’Ati ago mẹta oru ni a ti ji lati le ri ibi to dara duro’’ – awọn arinrin-ajo igbafẹ niluu Sydney

Oríṣun àwòrán, Getty Images
BBC bawọn arinrin-ajọ igbafẹ ti inu wọn dun sọrọ nibi ti wọn ti n duro de ago mejila ti wọn yoo wọ inu ọdun tuntun ni Australia.
Christopher Maldonado lati Chile ni ‘’ohun to lamilaaka ni yinyin banga tori ohun lo maa jẹ akọkọ iruẹ lagbaaye.
O ṣi maa n jẹ nkan idunnu ti eeyan ba le ri ibi to sun mọ ori afara ti wọn yoo ti yin banga ọhun.’’
Arinrin-ajo afẹ mii sọ pe ‘’inu mi dun gan an, mo si n foju sọna lati yin banga.
Yinyin banga wa lara awọn ohun ti mo maa n ṣe fun bi ọdun mẹwaa bayii.’’
Ẹlomiran tun sọ bi o ṣe ji lati ago mẹta oru ni Australia lati le ri ibi to dara duro ju banga.
O ni ‘’iwaju afara Harbour ti a wa yii lo dara ju lọ fun wa.
Lati orilẹede France ni a ti wa, o ti pẹ ti a ti n foju sọna si ọjọ oni.’’

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/SHUTTERSTOCK















