Wo àwọn kókó tó wà nínú àbá owó ètò ìṣúná ọdún 2024 tí àwọn aṣòfin buwọ́lù

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Vanguard Newsppaper

Awọn aṣofin orilẹede Naijiria ti fọwọ si owo to le ni tiriliọnu mejidinlọgbọn Naira, 28.77Tr, lati gbọ bukaata eto iṣuna ọdun 2024, lọjọ Abamẹta, ọgbọnjọ, oṣu Kejila, ọdun 2023.

Eyi lo waye lẹyin ti awọn aṣofin naa ṣe afikun tiriliọnu kan ati igba biliọnu naira si iye ti Aarẹ Bola Tinubu gbe ka iwaju ile naa lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹsan-an , ọdun 2023.

Ẹ wo atupalẹ bi wọn ṣe pin owo naa si ẹka kọọkan:

  • Ninu abadofin ọhun, tiriliọnu kan ati ẹẹdẹgbẹrin biliọnu Naira lo jẹ owo ti ijọba yoo fun awọn ẹka kan.
  • Tiriliọnu mẹjọ ati ọtalelẹẹdẹgbẹrin biliọnu naira ni yoo wa fun owo ti ijọba yoo ma a na ni atigbadegba, to fi mọ owo oṣu awọn oṣiṣẹ.
  • Owo to wa fun iṣẹ akanṣe din miliọnu mẹwa ninu tiriliọnu mẹwa.
  • Tiriliọnu mẹjọ ati ọrinlelugbadinmẹwa biliọnu Naira ni Naijiria yoo fi san gbese.
Ile aṣofin apapọ orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, WIKIPEDIA

Wo awọn ileeṣẹ ijọba ti yoo na owo to po julọ ni 2024

  • Ileeṣẹ feto abo ni yoo na owo to pọ ju - tiriliọnu kan ati ọọdunrun biliọnu Naira fun lati ma a gbọ bukaata igba gbogbo, ti wọn os i na 339.2bn Naira fun iṣẹ akanṣe
  • Ileeṣẹ to n moju to ọrọ awọn ọlọpaa yoo na owo to le diẹ ni 869.1bn Naira fun bukaata atidegbadegba, ti wọn yoo si na 100bn Naira o le diẹ fun iṣẹ akanṣe.
  • Eto ẹkọ ni yoo gba 857.1bn Naira fun bukaata atidegbadegba, ti 417.5bn Naira yoo si jẹ yiya sọtọ fun iṣe akanṣe.
  • Ileeṣẹ feto ilera ati iranlọwo awujọ ni yoo na 667.5bn Naira fun bukaata atidegbadegba, leyi to yatọ si 417.5bn Naira to wa fun iṣe akanṣe.
  • Ẹka eto ọgbin ni yoo gba 857.1bn Naira, pẹlu 110bn Naira fun akanṣe iṣẹ
  • Ileeṣẹ to n moju to akanṣe iṣẹ ni yoo na 4.3tr Naira, ti yoo si tun lo892.4bn Naira fun iṣẹ akanṣẹ.
  • Ileeṣẹ feto ẹnawo yoo gba 463bn Naira fun iṣẹ akanṣe pẹlu awọn owo miran.
  • Ileeṣẹ fọrọ abẹle ni owo ti wọn le ni 362.6bn Naira , ti ileeṣẹ to n moju to ọrọ awọn ọdọ yoo si na owo to le diẹ ni 201.5bn Naira.
  • Ofiisi oludamọran fun aarẹ lori eto abo yoo na owo to din diẹ ni 199.8bn Naira Naira; ọfiisi akọwe ijọba orilẹede yoo na 100.2bn Naira; ti ileeṣẹ aarẹ yoo si na 97.9bn Naira ati awọn owo miran.