Ilé aṣòfin àgbà l’Abuja képe àwọn olórí ológun, DSS àti ọ̀gá ọlọ́pàá lórí ìṣekúpani Plateau

Oríṣun àwòrán, JONATHAN BENJOE/FACEBOOK
Ile aṣofin agba niluu Abuja ti ranṣẹ pe awọn olori ileeṣẹ ologun Naijria, olori ajọ DSS ati ọga ọlọpaa ni Naijiria lori iṣẹlẹ isẹkupani to waye ni ipinlẹ Plateau.
O kere tan eeyan marunlelogoje lawọn janduku agbebọn ṣekupa ni bii abule mẹtalelogun ni ijọba ibilẹ Bokko ati Barkin Ladi ni ibẹrẹ ọsẹ yii.
Iṣẹlẹ ọhun ninu eyi ti ọpọ ẹmi ati dukia ti ṣofo ni a gbọ pe o waye lati ọjọ Abamẹta ọsẹ to lọ to fi di ọjọ Aje ọsẹ yii.
Ile aṣofin sọ nibi ijokoo rẹ lọjẹ Abamẹta wi pe ile iṣẹ ẹṣẹ eleto abo Naijiria lo kuna pẹlu bi awọn janduku ọhun ti ṣiṣẹ laabi wọn ti ẹnikankan ko si le dawọn lọwọ ko.
Awọn aṣofin fẹ ki awọn olori ileeṣẹ ologun atawọn ẹsọ eleto abo wa sọ tẹnu wọn ki awọn le mọ igbesẹ mii ti awọn maa gbe.
Sẹnẹtọ Abdul Ningi to n ṣoju ipinlẹ Bauchi ni iru iṣẹlẹ naa tun yatọ pe ko ṣẹlẹ ri.
Sẹnẹtọ Ningi ni lẹyin ipade oun pẹlu gomina Plateau, oun le sọ pe awọn janduku agbebọn yii ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn eeyanto wa lagbege awọn abule ti wọn ti ṣiṣẹ laabi wọn.
O ni awọn ẹṣọ eleto abo kuna pẹlu bi awọn janduku agbebọn to le ni ọdunrun un fi ṣọṣẹ ti wọn ko si ri ẹnikẹni dawọn lọwọ kọ.
Ẹwẹ, gomina ipinlẹ Plateau tẹlẹ, Simon Lalong ti sọ pe nkan to buru jai ni bi iṣekupani ṣe tun waye pẹlu gbogbo awọn oriṣiriiṣi ẹṣọ eleto abo nipinlẹ naa.















