Awọn ọmọ Nàìjíríà fẹ́ràn láti gba adigunjalè mọ́ra ju àwa "transgender" táa ń múra bí obìnrin lọ - Jay Boogie

Jay Boogie

Oríṣun àwòrán, Jay_Boogie/Instagram

Ọmọ orílẹ̀èdè Naijiria kan to maa n mura bi obinrin amọ to ni adamọ ọkùnrin lara, Jay Boogie ti orúkọ abisọ rẹ gangan n jẹ Daniel Nsikan ti di ilumọọka bayii lori ayelujara latari awọn aworan ara rẹ to n fi si ori ayelujara.

Ó ti fẹ́rẹ to eniyan egberun lọ́nà igba to n tẹ leè loju opo Instagram rẹ, koda o le ki eeyan to mọ pe orúkọ abisọ rẹ gangan ni Daniel, eyi jẹ orúkọ ti ọpọ obi ni Naijiria maa n sọ ọmọ wọn ọkùnrin.

Nigeria jẹ ọkan lara awọn orílẹ̀èdè agbaye to kọ ẹyin si ibadọgba awọn onibalopọ akosakọ tabi abosabo (LGBTQ).

Bii tí àwọn orílẹ̀èdè ilẹ̀ Afirika mii, oju awọn LGBTQ n ri mabo ni ti idẹyẹsi ati iwa ipa ni awọn ilu to gbe àṣà lárugẹ bii Naijiria.

Ni ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn ni ile igbimọ aṣofin orílẹ̀èdè Ghana fi gbogbo ọwọ gbaruku ti àtúnṣe abadofin kan to ni ṣe pẹlu awọn onibalopọ ẹ̀yà kan naa yii del eyi to dabaa ẹ̀wọ̀n ọdun mẹta fun ẹnikẹni to ba pe ara rẹ ni LGBTQ+.

Bakan naa, ninu oṣù karun ọdun 2023 ni Ààrẹ orílẹ̀èdè Uganda, Yoweri Museveni fọwọ́ si iwe kan ti awọn onwoye ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ ọkan lara ofin to le ju to lodi si iwa awọn ó ibalopọ ẹda kan naa (LGBTQ) lagbaye.

Ofin ti wọn pàṣẹ idajọ iku fún ẹni ti gule gule rẹ ba pọ ju nipa ibalopọ ẹda kan naa. Ibalopọ yii ti jẹ eyi to lodi si ofin ni o le ni ọgbọn orílẹ̀èdè ni Áfíríkà.

Amọ ṣá, Jay Boogie ti pe ara rẹ ni ọkùnrin to n mura bi obinrin o si jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ́ LGBTQ díẹ̀ to ti jade sita lati sọ̀rọ̀ nípa ẹni ti wọn jẹ gangan nipa ti ibalopọ.

Ninu ifọrọwanilẹ́nuwo to ṣe pẹlu BBC Pidgin, o ni oun n gbe igbe aye òótọ́ eyi si ni idi ti oun fi n gbe gẹgẹ bi ọkùnrin to n mura bi obinrin nitori idunu oun lo ṣe pataki ju.

Bawo ni igba kekere Jay Boogie ṣe ri?

Jay Boogie

Oríṣun àwòrán, Jay_Boogie/Instagram

"Igba kekere mi ri bákan".

Jay Boogie n sọ̀rọ̀ nipa iṣẹlẹ kan to bá a ninu jẹ nigba kekere rẹ.

O ni olùkọ́ oun da oun ya sọtọ nitoripe oun wọ awọtẹlẹ fi bo aya oun toripe toripe oun ti n dagba.

Jay ni lati igba ti oun ti wa ni kekere ni oun ti mọ wipe obinrin ni oun toripe gbogbo nnkan nipa oun lo jẹ ti obinrin.

O fi ku un pe awọn obi oun gan ati mọlẹbi to fi mọ ọrẹ lo n ti oun lẹyin.

Ko si ofin to da abo bo ẹtọ awọn LGBTQ ni Naijiria to si jẹ pe itapa si ofin ni bẹẹ si lo ni ijiya labẹ ofin.

Nitori ofin to wa nilẹ, Jay Boogie sọ pe o ni awọn ibi kọọkan ti oun ko le lọ - “ibi kibi ti mo ba n lọ, mo maa n rii pe abo mi daju.”

“Iṣẹ́ abẹ ti mo ṣe”

Jay Boogie

Oríṣun àwòrán, Jay_Boogie/Instagram

Gbajugbaja yii ni ọpọlọpọ eeyan to n tẹle e lori ayelujara to si n mu inu wọn dun pẹlu oniruuru aworan ara rẹ.

O sọ fun ileeṣẹ BBC pe oun ti ṣe iṣẹ abẹ lati ni ọyan amọ oun ko tii ṣe ohunkohun si ara oun.

O fi kun un pe oun nigbagbọ pe oun yoo ṣe igbeyawo lọjọ kan ti oun yoo si fi inu ṣe oyun lẹyin ti oun ba pari gbogbo iṣẹ abẹ atunto ara oun.

Jay Boogie to jẹ gbajugbaja ori ayelujara ni oun ko ni ibanujẹ kankan nipa ara oun bẹẹ si ni oun ko foju kere ara oun.

Ẹwẹ, oju ti awọn ọmọ Naijira ma fi n wo iru akanda to jẹ maa n kọ ọ lominu.

O ni o ya oun lẹnu pe awọn eeyan lee gba awọn ẹlẹwọn to ṣẹ ti ẹwọn de si awujọ, wọn a ri awọn to n digunjale, kowo ilu jẹ, ajinigbe ati apaniyan, wọn ko ni ṣe ikọlu si wọn.

“Amọ ti wọn ba ti ri ẹni to ni ẹya ara to yatọ si ohun ti wọn n fi pe e lara, yoo maa gun wọn garagara lati ṣe ikọlu si wa.”

Ki ni ofin Naijiria sọ nipa LGBTQ?

Jay Boogie

Oríṣun àwòrán, Jay_Boogie/Instagram

Jay Boogie sọ pe ọpọlọpọ igbagbọ odi lo wa nipa awọn eeyan bii ti oun.

O ṣalaye pe ọpọlọpọ eniyan lo maa n gbe ẹni ti o n mura bi obirin sira wọn pẹlu onibalopọ akọsakọ tabi abosabo.

“Ni temi, mi o ki n ṣe onibalopọ akọsakọ, abi ẹya ara ẹda meji ni mi tori iru awọn nnkan ti mo ni, bẹẹ si ni mo ṣe ri ara mi.”

Ni ọjọ keje oṣu kinni ọdun 2014 ni aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ, Goodluck Jonathan buwọlu ofin to tako ibalopọ ẹda kan naa to si sọ ọ di ofin.

Ofin naa lodi si ki onibalopọ ẹda kan naa jọ maa gbe papọ to si tun fofin de ibaṣepọ wọn nita gbangba.

Ofin SSMPA yii dajọ ijiya ẹwọn ọdun mẹwa fun ẹnikẹni to ba n kopa ninu ẹgbẹ tabi akojọpọ awọn onibalopọ ẹda kan naa tabi ṣe atilẹyin fun wọn.

Ijiya fun eyi wa laarin ọdun mẹwaa si mẹrinla lọgba ẹwọn.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Instagram