Transgender: Ilé ìwòsàn wọ gàù torí kò sọ ewu tó wà nídìí ìyípadà ìṣẹ̀dá kan sí òmíràn

Yoruba ni abamọ nii gbẹyin ọrọ, gbogbo oloogun agbaye si pe jọ, wọn ko ri ẹbọ abamọ se.
Bẹẹ lọrọ ri fun obinrin kan, Keira Bell, ọmọ ilẹ gẹẹsi, ẹni ọdun mẹtalelogun bayii, to sọ ara rẹ di ọkunrin, latigba to ti wa lọmọ ọdun mẹrindinlogun.
Bell, ẹni to ti n ko oogun jẹ lati ọmọ ọdun mẹrinla ko lee di ọkunrin, sọ fun BBC pe awọn dokita ko salaye fun oun nipa ewu to wa ninu igbesẹ ti oun fẹ gbe naa, tori ti oun ba mọ nipa rẹ daada ni, oun ko ba ti gbe igbesẹ ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kaduna tún gbàlejò ìkọlù àwọn agbébọn, àádọ́ta èèyàn míì rọ̀run ọ̀sán gangan
- Obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ ẹrú ní Oman tó bá fẹ́ òmìnira, yóò bá ọ̀gá rẹ̀ ṣùn - obìnrin méjì tó ti oko ẹrú dé
- Ọ́lọ́pàá bá aṣọ, bàtà àti fóónù ọkùnrin tó dàwátì nílé Pásítọ̀ etí òkun l‘Eko
- Ẹ fi ọkàn balẹ̀ lórí àrùn Coronavirus, à ń ṣa ìpa wa láti dènà ìtànkálẹ̀ rẹ̀ - Buhari
- Ẹ́ fún ọmọ Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́ tó yè kooro dípò kẹ rán Boko Haram tó ronúpìwàdà lọ kàwé lókè òkun - Serap
Ọbinrin naa, ni ọjọ ori oun kere lasiko ti oun n gbe igbesẹ naa, ti oun ko si mọ ọtun yatọ si osi, tun fikun pe, to ba si jẹ pe oun ri ẹni si oun leti ni, abamọ ko ba ti gbẹyin ọrọ fun oun.

Bell, ẹni to ti gbe ile iwosan to ba se iyipada naa lọ sile ẹjọ salaye pe, lati ọmọ ọdun mẹrindinlogun ti oun ti n lo awọn oogun to yẹ, ni oun ti ni ọyan bii obinrin, bakan naa ni ohun oun ti dabi ti obinrin.
O ti wa kede bayii pe oun ko fẹ di ọkunrin mọ, oun si fẹ pada si ipo ti oun wa tẹlẹ, lati akoko yii lọ, ọbinrin ni ki wọn maa pe oun, tori oun ti dawọ lilo oogun to n sọ oun di obinrin duro.
Awọn agbẹjọro ti wa salaye pe ẹni ti ko baa tii pe ẹni ọdun mejidinlogun si wa ni ọmọde, ti ko si mọ ohun to yẹ, bẹẹ ni ko yẹ ki wọn lanfaani si eto iyipada lati isẹda kan si omiran

Ajọ Tavistock ati Portman NHS to se agbatẹru bi Bell se yipada si ọkunrin salaye pe awọn kuku sọrase lori ọrọ ọmọde naa, tawọn si fi pẹlẹputu beere awọn ibeere to yẹ lọwọ ọmọkunrin naa, ko to di pe awọn gunle igbesẹ to yẹ lati sọ di obinrin.
Nigba to salaye ohun to sun ohun de idi iyipada naa, Bell di ẹbi ọrọ ọhun ru awujọ ti ko gba oun ni aaye lati mura bo se wu oun, ki oun si lee lo asọ ati bata ọkunrin laisi jẹ pe wọn yoo maa pe wo oun.













