Bí ọwọ́ ṣe tẹ ẹni ọdún 32 tó fún ìyá rẹ̀ lọ́run pa nípinlẹ̀ Ogun níyì

Oríṣun àwòrán, Nigerian Police Force
Ileeṣẹ ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Ogun ni awọn ti fi panpẹ ofin mu arakunrin kan to maa n mu ogun oloro, Samson Sikiru ti wọn ni o fun iya to bi i lọrun pa ni agbegbe Ijebu Ode, Ìpínlẹ̀ Ogun.
Agbẹnusọ Ileeṣẹ Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ Ogun, Omotola Odutola lo fi aridaju iroyin yii lede.
Wọn ni o ti pẹ díẹ̀ ti afurasi naa ti wa lábẹ́ akoso oogun oloro to maa n gbe lu ara to si jẹ pe iya rẹ lo maa n tọju rẹ, àmọ́ ọmọ yii naa lo wa pada pa iya rẹ ni agbegbe Itanran ni Ijebu Ode.
Iroyin sọ pe aburo afurasi naa ọkùnrin to jẹ ọlọdẹ adugbo nigba to n bọ lati ibi iṣẹ alẹ rẹ lo kígbe sáwọn ara adugbo nigba to ri ara iya rẹ to wa nilẹ ti ko si èémí kankan ninu rẹ mọ.
Iru eeyan wo ni Samson jẹ?
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ́, Samson ko si nílé fun iye ọdun melo kan, sugbọn wọn ni o pada wale lati wa ba wọn ṣe ọdun ileya to kọja yii pẹlu iya rẹ ni nnkan bi ọ̀sẹ̀ meji sẹ́yìn.
Ile iṣẹ iroyin Channels TV ni ọwọ Ọlọpaa tẹ Samson lẹyin ti awọn ara adugbo rii pe oun lo wa nidi iku iya rẹ ti wọn si fa a le Ọlọpaa lọwọ.
Nigba to n fi aridaju iṣẹlẹ naa han, agbẹnusọ Ileeṣẹ Ọlọpaa Ìpínlẹ̀ naa, Omotola sọ pe afurasi ọhun tun jẹ alaarẹ to n gba itọju to ni ṣe pẹlu ọpọlọ.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ Ọlọpaa ṣe sọ, lẹẹkọọkan, awọn mọ̀lẹ́bí rẹ maa n so o mọ́lẹ̀ tori ko ma baa ṣe ara rẹ tabi ẹlòmíràn léṣe.
"O ti wa lọdọ iya rẹ to lọ bẹ wo lasiko ọdun Sallah bo tilẹ̀ jẹ pe wọn mọ ohun to lee ṣe, sugbọn wọn n tọju rẹ ni ìwọ̀n bi iya rẹ ṣe mọ.
"Ko tii wa ye ẹnikẹ́ni boya iya rẹ ṣe ohunkohun to mu u binu amọ iwadii ti n lọ to si ti fihan pe ṣáájú lọjọ yii kan naa, wọn de e mọ́lẹ̀ ninu ile, afi to dede tu ara rẹ silẹ to si bo iya rẹ mọ́lẹ̀ to fun un lọrun."
Ki ni ọlọpaa ri nigba ti wọn de ile wọn?
Iroyin taa gbọ́ ni oku arabinrin naa wa lori bẹẹdi nigba ti awọn Ọlọpaa. SP Murphy ati DPO de sugbọn nigba ti wọn wo o daadaa wọn ri apa wipe wọn fipa mu eeyan layika rẹ.
Wọn ri oju Ọgbẹ lẹsẹ ọtun rẹ, eyi to fihan pe ọwọ ipa wa ninu iku rẹ.
"Samson Sikiru ṣi wa ni àtìmọ́lé Ọlọpaa lọwọlọwọ amọ ko tii si ohun pupọ ti wọn ri gba silẹ lẹ́nu rẹ nitoripe ko tii sọ ọrọ kankan to mu ọgbọn wa si awọn ibeere ti wọn bere lọwọ rẹ", agbẹnusọ Ọlọpaa sọ bẹẹ.















