Ọwọ́ ikọ̀ Ológun tẹ ọmọ Ghana kan tó ń kó ẹ̀kún ọkọ̀ nǹkan ìjagun lọ sí Anambra nípínlẹ̀ Ogun

Awọn nnkan ijagun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ikọ ologun 192 Battalion ti fi panpẹ Ọba mu afurasi ara orílẹ̀èdè Ghana kan to n gbe ọkọ kan to kun fun nnkan ijagun lọ si Ìpínlẹ̀ Anambra ni ọjọ Abameta, ọjọ kẹ́ẹdogun oṣù keje ọdun 2023.

Ikọ ologun naa ti wọn tara ṣaṣa lati gbe igbesẹ ọlọgbọn ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si ni ṣe ayẹwo awọn ọkọ to n kọja loju pópó da ọkọ ara ilẹ̀ okere naa duro ni opopona Ajilete-Owode ni ijọba ìbílẹ̀ Yewa, Ìpínlẹ̀ Ogun.

Ibẹ ni wọn ti ri ẹrù nnkan ijagun ti wọn ko sinu ọkọ kan to ni nọ́mbà ENU 697 XY, eyi to kun fun ẹẹdẹgbẹrin o le ogun ọta ibọn "Red Star Cartridges ònísọrí méjìlá, to tun wa ni ọta ibọn meedogbon ninu Pali kọọkan.

Gbogbo rẹ wa jẹ ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún ọta ibọn ati Pali igba ó lé àádọ́ta ọta ibọn to ti rẹdu tòun naa ni paaki mẹwa mẹwa ninu ti gbogbo rẹ jẹ ẹgbẹrun meji àbọ̀ onísọ̀rí kan náà.

Ninu atẹjade ti Ileeṣẹ ologun Naijiria fi sita eyi ti agbẹnusọ wọn, Onyema Nwachukwu fọwọ́ si ṣàlàyé pé afurasi naa ti orúkọ rẹ ń jẹ Ọgbẹni Eric Seworvor jẹ ọmọ orílẹ̀èdè Ghana bẹẹ si ni dẹrẹba to n wa ọkọ naa ni Lukman Sani.

Wọn ti ko awọn mejeji si àtìmọ́lé bayii ti wọn si n ṣeranwọ fun iwadii to n lọ lọwọ.

Ki lo wa ninu ọkọ naa?

Lara ohun to jẹ jade nibi iwadii ti wọn ti kọ́kọ́ ṣe fihan pe lati orílẹ̀èdè Mali ni wọn ti ko awọn nnkan ijagun to wa ninu ọkọ ti wọn ṣe bii pe o wa lofo wa ti wọn si gbe e gba ibode Idiroko ti awọn afurasi ọ̀daràn yii ti gba oniruuru ibudo ayẹwo awọn ologun kọja titi wọn fi wa lojuna wọn lọ si Onitsha ni Anambra.

Ọpẹlọpẹ pe awọn ikọ fijilante ri èyí, ti wọn si ni ohun lo ba erongba wọn jẹ pẹlu awọn irinṣẹ to leè pa awọn aráàlú lara ti wọn ko.

Ileeṣẹ ologun Naijiria wa rọ awọn araalu lati tesiwaju ninu riran awọn ologun àtàwọn oṣiṣẹ alaabo míì lọwọ pẹlu iroyin tootọ gẹgẹ bi wọn ṣe n gbogun ti ipenija abo kaakiri Naijiria.

Ọga agba awọn ọmọ ogun oriilẹ, Ọgagun Taoreed Lagbaja naa ti gboriyin fún àwọn ikọ ologun fun ifarajin wọn o si rọ wọn pe ki wọn ma kaarẹ bi pa ọwọ pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ alaabo mii lati pèsè ayika to wa ni aabo pipeye fun gbogbo ọmọ Nàìjíríà ati fun idagbasoke ilu jakejado Naijiria.